Jer 23:5-8
Jer 23:5-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Sa wò o, ọjọ mbọ, li Oluwa wi, ti emi o gbe Ẹka ododo soke fun Dafidi, yio si jẹ Ọba, yio si ṣe rere, yio si ṣe idajọ ati ododo ni ilẹ na. Li ọjọ rẹ̀ ni a o gba Juda là, Israeli yio si ma gbe li ailewu, ati eyi li orukọ ti a o ma pè e: OLUWA ODODO WA. Nitorina, sa wò o, ọjọ mbọ̀, li Oluwa wi, ti nwọn kì yio tun wipe, Oluwa mbẹ, ti o mu awọn ọmọ Israeli jade kuro ni ilẹ Egipti: Ṣugbọn pe, Oluwa mbẹ, ti o mu iru-ọmọ ile Israeli wá, ti o si tọ́ wọn lati ilu ariwa wá, ati lati ilu wọnni nibi ti mo ti lé wọn si, nwọn o si gbe inu ilẹ wọn.
Jer 23:5-8 Yoruba Bible (YCE)
“Wò ó! Àkókò kan ń bọ̀, tí n óo gbé Ẹ̀ka olódodo kan dìde ninu ìdílé Dafidi. Yóo jọba, yóo hùwà ọlọ́gbọ́n, yóo sì ṣe ẹ̀tọ́ ati òdodo ní ilẹ̀ náà. Juda yóo rí ìgbàlà ní ìgbà tirẹ̀, Israẹli yóo sì wà láìléwu. Orúkọ tí a óo máa pè é ni ‘OLUWA ni òdodo wa.’ “Nítorí náà àkókò kan ń bọ̀, tí wọn kò ní máa búra ní orúkọ OLUWA tí ó kó àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti mọ́, ṣugbọn tí wọn yóo máa wí pé, ‘Ní orúkọ OLUWA tí ó kó àwọn ọmọ ilé Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ àríwá, ati gbogbo ilẹ̀ tí wọn kó wọn lẹ́rú lọ, tí ó sì mú wọn pada sí ilẹ̀ wọn.’ Wọn óo wá máa gbé orí ilẹ̀ wọn nígbà náà. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
Jer 23:5-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ọjọ́ ń bọ̀,” ni OLúWA wí, “tí Èmi yóò gbé ẹ̀ka òdodo dìde fún Dafidi, ọba tí yóò lo ìjọba pẹ̀lú ọgbọ́n tí yóò sì ṣe òdodo àti ohun tí ó yẹ lórí ilẹ̀ náà. Ní ọjọ́ rẹ̀ ni a ó gba Juda là, Israẹli yóò sì máa gbé ní aláìléwu Èyí ni orúkọ tí a ó fi máa pè é: OLúWA Òdodo wa. Nítorí náà, ọjọ́ ń bọ̀,” ni OLúWA wí, “tí ènìyàn kì yóò tún wí pé, ‘Dájúdájú OLúWA wà láààyè tí ó mú àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti.’ Ṣùgbọ́n wọn yóò máa wí pé, ‘Dájúdájú OLúWA ń bẹ tí ó mú irú-ọmọ ilé Israẹli wá láti ilẹ̀ àríwá àti láti àwọn ilẹ̀ ibi tí mo tí lé wọn lọ,’ wọn ó sì gbé inú ilẹ̀ wọn.”