Jer 17:5-9
Jer 17:5-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bayi li Oluwa wi: Egbe ni fun ẹniti o gbẹkẹle enia, ti o fi ẹlẹran ara ṣe apá rẹ̀, ẹniti ọkàn rẹ̀ si ṣi kuro lọdọ Oluwa! Nitoripe yio dabi alaini ni aginju, ti kò si ri pe rere mbọ̀: ṣugbọn yio gbe ibi iyangbẹ ilẹ wọnni ni aginju, ilẹ iyọ̀ ti a kì igbe inu rẹ̀. Ibukun ni fun ẹniti o gbẹkẹle Oluwa, ti o si fi Oluwa ṣe igbẹkẹle rẹ̀! Yio si dabi igi ti a gbìn lẹba omi, ti o nà gbòngbo rẹ̀ lẹba odò, ti kì yio bẹ̀ru bi õru ba de, ṣugbọn ewe rẹ̀ yio tutu, kì yio si ni ijaya ni ọdun ọ̀dá, bẹ̃ni kì yio dẹkun lati ma so eso. Ọkàn enia kún fun ẹ̀tan jù ohun gbogbo lọ, o si buru jayi! tani o le mọ̀ ọ?
Jer 17:5-9 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA ní, “Ègún ni fún ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé eniyan, tí ó fi ẹlẹ́ran ara ṣe agbára rẹ̀; tí ọkàn rẹ̀ yipada kúrò lọ́dọ̀ èmi OLUWA. Ó dàbí igbó ṣúúrú ninu aṣálẹ̀, nǹkan rere kan kò lè ṣẹlẹ̀ sí i. Ninu ilẹ̀ gbígbẹ, ninu aṣálẹ̀ ni ó wà, ninu ilẹ̀ iyọ̀ tí ẹnikẹ́ni kò lè gbé. “Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, tí ó fi OLUWA ṣe àgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀. Yóo dàbí igi tí a gbìn sí ipa odò, tí ó ta gbòǹgbò kan ẹ̀bá odò. Ẹ̀rù kò ní bà á nígbà tí ẹ̀ẹ̀rùn bá dé, nítorí pé ewé rẹ̀ yóo máa tutù minimini. Kò ní páyà lákòókò ọ̀gbẹlẹ̀, nígbà gbogbo ni yóo sì máa so. “Ọkàn eniyan kún fún ẹ̀tàn ju ohun gbogbo lọ, ìwà ìbàjẹ́ sì kún inú rẹ̀; ta ni ó lè mọ èrò ọkàn eniyan?
Jer 17:5-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Báyìí ni OLúWA wí: “Ègbé ni fún àwọn tí ó fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn sínú ènìyàn, tí ó fi agbára rẹ̀ sínú ẹran-ara, àti tí ọkàn rẹ̀ kò sí lọ́dọ̀ OLúWA Yóò dàbí igbó tí ó wà ní ilẹ̀ aláìlọ́ràá, kò ní rí ìre, nígbà tí ó bá dé, yóò máa gbé ní ibi ìyàngbẹ ilẹ̀ aginjù, ní ilẹ̀ iyọ̀ tí ẹnikẹ́ni kò gbé. “Ṣùgbọ́n ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé OLúWA, tí ó sì fi OLúWA ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀. Yóò dàbí igi tí a gbìn sí ipadò tí ó ta gbòǹgbò rẹ̀ ká etí odò kò sí ìbẹ̀rù fún un nígbà ooru, gbogbo ìgbà ni èwe rẹ̀ máa ń tutù kò sí ìjayà fún un ní ọdún ọ̀dá bẹ́ẹ̀ ni kò ní dẹ́kun láti máa so èso.” Ọkàn ènìyàn kún fún ẹ̀tàn ju ohun gbogbo lọ, ó kọjá ohun tí a lè wòsàn, ta ni èyí lè yé?