Jer 11:3-4
Jer 11:3-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ki iwọ ki o si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi; Ifibu ni oluwarẹ̀ ti kò ba gbà ọ̀rọ majẹmu yi gbọ́, Ti mo pa li aṣẹ fun awọn baba nyin, li ọjọ ti mo mu wọn ti ilẹ Egipti jade, lati inu ileru irin wipe, Gbà ohùn mi gbọ́, ki ẹ si ṣe gẹgẹ bi emi ti paṣẹ fun nyin: bẹ̃ni ẹnyin o jẹ enia mi, emi o si jẹ Ọlọrun nyin
Jer 11:3-4 Yoruba Bible (YCE)
Sọ fún wọn pé OLUWA Ọlọrun Israẹli ní, ‘Ẹnikẹ́ni tí kò bá gba ọ̀rọ̀ majẹmu tí mo pa láṣẹ fún àwọn baba ńlá yín, gbé! Majẹmu tí mo bá wọn dá ní ọjọ́ tí mo kó wọn kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, ilẹ̀ tí ó gbóná bí iná tí alágbẹ̀dẹ fi ń yọ́ irin.’ Mo sọ fún wọn nígbà náà, mo ní, ‘Ẹ máa fetí sí ohùn mi, kí ẹ sì máa ṣe gbogbo nǹkan tí mo pa láṣẹ fun yín. Òun ni ẹ óo fi jẹ́ eniyan mi, tí èmi náà óo sì fi jẹ́ Ọlọrun yín.
Jer 11:3-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Sọ fún wọn wí pé èyí ni ohun tí OLúWA Ọlọ́run Israẹli wí: ‘Ègbé ni fún ẹni náà tí kò pa ọ̀rọ̀ májẹ̀mú yìí mọ́. Àwọn májẹ̀mú tí mo pàṣẹ fún àwọn baba ńlá yín, nígbà tí mo mú wọn jáde láti Ejibiti, láti inú iná alágbẹ̀dẹ wá.’ Mo wí pé, ‘Ẹ gbọ́ tèmi, kí ẹ sì ṣe ohun gbogbo tí mo pàṣẹ fún un yín. Ẹ̀yin ó sì jẹ́ ènìyàn mi: Èmi ó sì jẹ́ Ọlọ́run yín