Jer 10:12-13
Jer 10:12-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
On ti da aiye nipa agbara rẹ̀, on ti pinnu araiye nipa ọgbọ́n rẹ̀, o si nà awọn ọrun nipa oye rẹ̀. Nigbati o ba sán ãrá, ọ̀pọlọpọ omi ni mbẹ loju-ọrun, o si jẹ ki kũku rú soke lati opin aiye; o da mànamana fun òjo, o si mu ẹfũfu jade lati inu iṣura rẹ̀ wá.
Jer 10:12-13 Yoruba Bible (YCE)
Òun ni ó fi agbára rẹ̀ dá ayé, tí ó fi ọgbọ́n fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀, tí ó sì fi òye rẹ̀ ta ojú ọ̀run bí aṣọ. Bí ó bá fọhùn, omi á máa rọ́kẹ̀kẹ̀ lójú ọ̀run, ó mú kí ìkùukùu gbéra láti òpin ayé, òun ni ó dá mànàmáná fún òjò, tí ó sì mú afẹ́fẹ́ wá láti ilé ìṣúra rẹ̀.
Jer 10:12-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọlọ́run dá ayé pẹ̀lú agbára rẹ̀, ó dá àgbáyé pẹ̀lú ọgbọ́n rẹ̀, ó mú kí ọ̀run kí ó fẹ̀ síta nípa òye rẹ̀. Nígbà tí ó bá sán àrá, àwọn omi lọ́run a sì pariwo, ó mú kí ìkùùkuu ru sókè láti òpin ayé: ó rán mọ̀nàmọ́ná pẹ̀lú òjò, ó sì ń mú afẹ́fẹ́ wá láti ilé ìṣúra rẹ̀.