Jer 1:9-10
Jer 1:9-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
Oluwa si nà ọwọ rẹ̀, o fi bà ẹnu mi; Oluwa si wi fun mi pe, sa wò o, emi fi ọ̀rọ mi si ọ li ẹnu. Wò o, li oni yi ni mo fi ọ ṣe olori awọn orilẹ-ède, ati olori ijọba wọnni, lati fàtu, ati lati fà lulẹ; lati parun, ati lati wó lulẹ; lati kọ́, ati lati gbìn.
Jer 1:9-10 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA bá na ọwọ́, ó fi kàn mí lẹ́nu, ó sì wí fún mi pé, “Wò ó, mo ti fi ọ̀rọ̀ mi sí ọ lẹ́nu. Mo ti fi ọ́ ṣe orí fún àwọn orílẹ̀-èdè ati ìjọba lónìí, láti fà wọ́n tu ati láti bì wọ́n lulẹ̀, láti pa wọ́n run ati láti bì wọ́n ṣubú, láti tún wọn kọ́ ati láti gbé wọn ró.”
Jer 1:9-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA sì na ọwọ́ rẹ̀, ó sì fi kàn mí lẹ́nu, ó sì wí fún mi pé nísinsin yìí mo ti fi ọ̀rọ̀ mi sí inú ẹnu rẹ Wò ó, mo yàn ọ́ lórí àwọn orílẹ̀-èdè àti ìjọba gbogbo láti fàtu, láti wó lulẹ̀, láti bàjẹ́, láti jágbà, láti máa kọ́, àti láti máa gbìn.