Jer 1:5-9
Jer 1:5-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ki emi ki o to dá ọ ni inu, emi ti mọ̀ ọ, ki iwọ ki o si to ti inu jade wá li emi ti sọ ọ di mimọ́, emi si yà ọ sọtọ lati jẹ́ woli fun awọn orilẹ-ède. Emi si wipe, Oluwa Ọlọrun! sa wò o, emi kò mọ̀ ọ̀rọ isọ nitori ọmọde li emi. Ṣugbọn Oluwa wi fun mi pe, má wipe, ọmọde li emi: ṣugbọn iwọ o lọ sọdọ ẹnikẹni ti emi o ran ọ si, ati ohunkohun ti emi o paṣẹ fun ọ ni iwọ o sọ. Má bẹ̀ru niwaju wọn nitori emi wà pẹlu rẹ lati gbà ọ: li Oluwa wi. Oluwa si nà ọwọ rẹ̀, o fi bà ẹnu mi; Oluwa si wi fun mi pe, sa wò o, emi fi ọ̀rọ mi si ọ li ẹnu.
Jer 1:5-9 Yoruba Bible (YCE)
“Kí n tó dá ọ sinu ìyá rẹ ni mo ti mọ̀ ọ́, kí wọ́n sì tó bí ọ ni mo ti yà ọ́ sọ́tọ̀, mo yàn ọ́ ní wolii fún àwọn orílẹ̀-èdè.” Mo bá dáhùn pé, “Háà! OLUWA Ọlọrun! Wò ó! N kò mọ ọ̀rọ̀ sọ, nítorí pé ọmọde ni mí.” Ṣugbọn OLUWA dá mi lóhùn, ó ní, “Má pe ara rẹ ní ọmọde, nítorí pé gbogbo ẹni tí mo bá rán ọ sí ni o gbọdọ̀ tọ̀ lọ. Gbogbo ohun tí mo bá pa láṣẹ fún ọ ni o gbọdọ̀ sọ. Má bẹ̀rù wọn, nítorí mo wà pẹlu rẹ, n óo sì gbà ọ́.” OLUWA bá na ọwọ́, ó fi kàn mí lẹ́nu, ó sì wí fún mi pé, “Wò ó, mo ti fi ọ̀rọ̀ mi sí ọ lẹ́nu.
Jer 1:5-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Kí ó tó di pé mo dá ọ láti inú ni mo ti mọ̀ ọ́n, kí ó sì tó di pé a bí ọ ni mo ti yà ọ́ sọ́tọ̀. Mo yàn ọ́ gẹ́gẹ́ bí wòlíì fún àwọn orílẹ̀-èdè. Mo sọ pé, “Háà! OLúWA Olódùmarè, ọmọdé ni mí, èmi kò mọ bí a ṣe é sọ̀rọ̀.” OLúWA sọ fún mi pé, “Má ṣe sọ pé, ‘Ọmọdé lásán ni mí.’ O gbọdọ̀ ní láti lọ sí ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tí mo rán ọ sí, kí o sì sọ ohun tí mo pàṣẹ fún ọ.” OLúWA sì wí pé má ṣe bẹ̀rù wọn, nítorí tí èmi wà pẹ̀lú rẹ èmi ó sì gbà ọ́. OLúWA sì na ọwọ́ rẹ̀, ó sì fi kàn mí lẹ́nu, ó sì wí fún mi pé nísinsin yìí mo ti fi ọ̀rọ̀ mi sí inú ẹnu rẹ