Jer 1:4-8
Jer 1:4-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbana ni ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá wipe: Ki emi ki o to dá ọ ni inu, emi ti mọ̀ ọ, ki iwọ ki o si to ti inu jade wá li emi ti sọ ọ di mimọ́, emi si yà ọ sọtọ lati jẹ́ woli fun awọn orilẹ-ède. Emi si wipe, Oluwa Ọlọrun! sa wò o, emi kò mọ̀ ọ̀rọ isọ nitori ọmọde li emi. Ṣugbọn Oluwa wi fun mi pe, má wipe, ọmọde li emi: ṣugbọn iwọ o lọ sọdọ ẹnikẹni ti emi o ran ọ si, ati ohunkohun ti emi o paṣẹ fun ọ ni iwọ o sọ. Má bẹ̀ru niwaju wọn nitori emi wà pẹlu rẹ lati gbà ọ: li Oluwa wi.
Jer 1:4-8 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA sọ fún mi pé, “Kí n tó dá ọ sinu ìyá rẹ ni mo ti mọ̀ ọ́, kí wọ́n sì tó bí ọ ni mo ti yà ọ́ sọ́tọ̀, mo yàn ọ́ ní wolii fún àwọn orílẹ̀-èdè.” Mo bá dáhùn pé, “Háà! OLUWA Ọlọrun! Wò ó! N kò mọ ọ̀rọ̀ sọ, nítorí pé ọmọde ni mí.” Ṣugbọn OLUWA dá mi lóhùn, ó ní, “Má pe ara rẹ ní ọmọde, nítorí pé gbogbo ẹni tí mo bá rán ọ sí ni o gbọdọ̀ tọ̀ lọ. Gbogbo ohun tí mo bá pa láṣẹ fún ọ ni o gbọdọ̀ sọ. Má bẹ̀rù wọn, nítorí mo wà pẹlu rẹ, n óo sì gbà ọ́.”
Jer 1:4-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọ̀rọ̀ OLúWA sì tọ̀ mí wá, wí pé, Kí ó tó di pé mo dá ọ láti inú ni mo ti mọ̀ ọ́n, kí ó sì tó di pé a bí ọ ni mo ti yà ọ́ sọ́tọ̀. Mo yàn ọ́ gẹ́gẹ́ bí wòlíì fún àwọn orílẹ̀-èdè. Mo sọ pé, “Háà! OLúWA Olódùmarè, ọmọdé ni mí, èmi kò mọ bí a ṣe é sọ̀rọ̀.” OLúWA sọ fún mi pé, “Má ṣe sọ pé, ‘Ọmọdé lásán ni mí.’ O gbọdọ̀ ní láti lọ sí ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tí mo rán ọ sí, kí o sì sọ ohun tí mo pàṣẹ fún ọ.” OLúWA sì wí pé má ṣe bẹ̀rù wọn, nítorí tí èmi wà pẹ̀lú rẹ èmi ó sì gbà ọ́.