Jer 1:1-19

Jer 1:1-19 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ọ̀RỌ Jeremiah, ọmọ Hilkiah, ọkan ninu awọn alufa ti o wà ni Anatoti, ni ilẹ Benjamini. Ẹniti ọ̀rọ Oluwa tọ̀ wá ni igba ọjọ Josiah, ọmọ Amoni, ọba Juda, li ọdun kẹtala ijọba rẹ̀. O si tọ̀ ọ wá pẹlu ni igba ọjọ Jehoiakimu, ọmọ Josiah, ọba Juda, titi de opin ọdun kọkanla Sedekiah, ọmọ Josiah, ọba Juda, ani de igba ti a kó Jerusalemu lọ ni igbekun li oṣu karun. Nigbana ni ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá wipe: Ki emi ki o to dá ọ ni inu, emi ti mọ̀ ọ, ki iwọ ki o si to ti inu jade wá li emi ti sọ ọ di mimọ́, emi si yà ọ sọtọ lati jẹ́ woli fun awọn orilẹ-ède. Emi si wipe, Oluwa Ọlọrun! sa wò o, emi kò mọ̀ ọ̀rọ isọ nitori ọmọde li emi. Ṣugbọn Oluwa wi fun mi pe, má wipe, ọmọde li emi: ṣugbọn iwọ o lọ sọdọ ẹnikẹni ti emi o ran ọ si, ati ohunkohun ti emi o paṣẹ fun ọ ni iwọ o sọ. Má bẹ̀ru niwaju wọn nitori emi wà pẹlu rẹ lati gbà ọ: li Oluwa wi. Oluwa si nà ọwọ rẹ̀, o fi bà ẹnu mi; Oluwa si wi fun mi pe, sa wò o, emi fi ọ̀rọ mi si ọ li ẹnu. Wò o, li oni yi ni mo fi ọ ṣe olori awọn orilẹ-ède, ati olori ijọba wọnni, lati fàtu, ati lati fà lulẹ; lati parun, ati lati wó lulẹ; lati kọ́, ati lati gbìn. Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá wipe, Jeremiah, kini iwọ ri? emi si wipe, mo ri ọpa igi almondi. Oluwa si wi fun mi pe, iwọ riran rere, nitori ti emi o kiye si ọ̀rọ mi lati mu u ṣẹ. Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá lẹ̃keji pe, kini iwọ ri? emi si wipe, mo ri ìkoko ori iná, oju rẹ̀ si ni lati iha ariwa wá. Nigbana ni Oluwa sọ fun mi pe, ibi yio tú jade lati ariwa wá, sori gbogbo awọn ti ngbe inu ilẹ. Sa wò o, Emi o pè gbogbo idile awọn ijọba ariwa, li Oluwa wi, nwọn o si wá: olukuluku wọn o si tẹ́ itẹ rẹ̀ li ẹnu-bode Jerusalemu, ati lori gbogbo odi rẹ̀ yikakiri, ati lori gbogbo ilu Juda. Emi o si sọ̀rọ idajọ mi si wọn nitori gbogbo buburu wọn; ti nwọn ti kọ̀ mi silẹ, ti nwọn ti sun turari fun ọlọrun miran, ti nwọn si tẹriba fun iṣẹ ọwọ wọn. Ṣugbọn iwọ di ẹ̀gbẹ́ rẹ li amure, ki o si dide, ki o si wi fun wọn gbogbo ohun ti emi o pa laṣẹ fun ọ, má fòya niwaju wọn, ki emi ki o má ba mu ọ dãmu niwaju wọn. Sa wò o, loni ni mo fi ọ ṣe ilu-odi, ati ọwọ̀n irin, ati odi idẹ fun gbogbo ilẹ; fun awọn ọba Juda, awọn ijoye rẹ̀, awọn alufa, ati enia ilẹ na. Ṣugbọn nwọn o ba ọ jà, nwọn kì o si le bori rẹ; nitori emi wà pẹlu rẹ, li Oluwa wi, lati gbà ọ.

Jer 1:1-19 Yoruba Bible (YCE)

Ọ̀rọ̀ Jeremaya, ọmọ Hilikaya, ọ̀kan ninu àwọn alufaa tí ó wà ní Anatoti, ní ilẹ̀ Bẹnjamini nìyí. Nígbà ayé Josaya, ọmọ Amoni, ọba Juda, ní ọdún kẹtala tí Josaya gun orí oyè ni OLUWA bá Jeremaya sọ̀rọ̀. Ó sì tún gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA ní ìgbà ayé Jehoiakimu, ọmọ Josaya, ọba Juda títí di òpin ọdún kọkanla tí Sedekaya ọmọ Josaya jọba ní ilẹ̀ Juda, títí tí ogun fi kó Jerusalẹmu ní oṣù karun-un ọdún náà. OLUWA sọ fún mi pé, “Kí n tó dá ọ sinu ìyá rẹ ni mo ti mọ̀ ọ́, kí wọ́n sì tó bí ọ ni mo ti yà ọ́ sọ́tọ̀, mo yàn ọ́ ní wolii fún àwọn orílẹ̀-èdè.” Mo bá dáhùn pé, “Háà! OLUWA Ọlọrun! Wò ó! N kò mọ ọ̀rọ̀ sọ, nítorí pé ọmọde ni mí.” Ṣugbọn OLUWA dá mi lóhùn, ó ní, “Má pe ara rẹ ní ọmọde, nítorí pé gbogbo ẹni tí mo bá rán ọ sí ni o gbọdọ̀ tọ̀ lọ. Gbogbo ohun tí mo bá pa láṣẹ fún ọ ni o gbọdọ̀ sọ. Má bẹ̀rù wọn, nítorí mo wà pẹlu rẹ, n óo sì gbà ọ́.” OLUWA bá na ọwọ́, ó fi kàn mí lẹ́nu, ó sì wí fún mi pé, “Wò ó, mo ti fi ọ̀rọ̀ mi sí ọ lẹ́nu. Mo ti fi ọ́ ṣe orí fún àwọn orílẹ̀-èdè ati ìjọba lónìí, láti fà wọ́n tu ati láti bì wọ́n lulẹ̀, láti pa wọ́n run ati láti bì wọ́n ṣubú, láti tún wọn kọ́ ati láti gbé wọn ró.” OLUWA bi mí pé, “Jeremaya, kí ni o rí yìí?” Mo dáhùn, pé, “Ọ̀pá igi Alimọndi ni.” OLUWA bá wí fún mi pé, “Òtítọ́ ni ohun tí o rí, nítorí mò ń sọ ọ̀rọ̀ tí mo sọ, n óo sì mú un ṣẹ.” OLUWA tún bi mí lẹẹkeji, ó ní, “Kí ni o rí?” Mo bá dáhùn pé, “Mo rí ìkòkò kan tí ó ń hó lórí iná, ó tẹ̀ láti ìhà àríwá sí ìhà gúsù.” OLUWA bá sọ fún mi pé, “Láti ìhà àríwá ni ibi yóo ti dé bá gbogbo àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ náà. Nítorí pé mò ń pe gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó wà ní ìjọba àríwá, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀, àwọn ọba wọn yóo sì tẹ́ ìtẹ́ wọn kalẹ̀ ní ẹnubodè Jerusalẹmu, ati yíká odi gbogbo ìlú Juda. N óo dá wọn lẹ́jọ́ nítorí gbogbo ibi tí wọ́n ti ṣe, tí wọ́n kọ̀ mí sílẹ̀, tí wọn ń sun turari fún àwọn oriṣa, tí wọ́n sì ń bọ ohun tí wọ́n fi ọwọ́ ara wọn ṣe. Ṣugbọn, ìwọ dìde, di àmùrè rẹ, kí o sì sọ gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún ọ fún wọn. Má jẹ́ kí ẹ̀rù wọn ó bà ọ́, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, n óo dẹ́rù bà ọ́ níwájú wọn. Wò ó, mo ti sọ ọ́ di ìlú tí a mọ odi yíká lónìí, o di òpó irin ati ògiri tí a fi bàbà mọ fún gbogbo ilẹ̀ yìí, ati fún àwọn ọba ilẹ̀ Juda, àwọn ìjòyè, ati àwọn alufaa rẹ̀, ati àwọn eniyan ilẹ̀ náà. Wọn yóo gbógun tì ọ́, ṣugbọn wọn kò ní ṣẹgun rẹ. Nítorí pé mo wà pẹlu rẹ láti gbà ọ́ kalẹ̀. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Jer 1:1-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Èyí ni ọ̀rọ̀ Jeremiah ọmọ Hilkiah ọ̀kan nínú àwọn àlùfáà ní Anatoti ní agbègbè ilẹ̀ Benjamini. Ọ̀rọ̀ OLúWA sì tọ̀ ọ́ wá ní ọdún kẹtàlá ní àkókò ìjọba Josiah ọmọ Amoni ọba Juda, Àti títí dé àsìkò Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda, títí dé oṣù karùn-ún ọdún kọkànlá Sedekiah ọmọ Josiah ọba Juda, nígbà tí àwọn ará Jerusalẹmu lọ sí ìgbèkùn. Ọ̀rọ̀ OLúWA sì tọ̀ mí wá, wí pé, Kí ó tó di pé mo dá ọ láti inú ni mo ti mọ̀ ọ́n, kí ó sì tó di pé a bí ọ ni mo ti yà ọ́ sọ́tọ̀. Mo yàn ọ́ gẹ́gẹ́ bí wòlíì fún àwọn orílẹ̀-èdè. Mo sọ pé, “Háà! OLúWA Olódùmarè, ọmọdé ni mí, èmi kò mọ bí a ṣe é sọ̀rọ̀.” OLúWA sọ fún mi pé, “Má ṣe sọ pé, ‘Ọmọdé lásán ni mí.’ O gbọdọ̀ ní láti lọ sí ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tí mo rán ọ sí, kí o sì sọ ohun tí mo pàṣẹ fún ọ.” OLúWA sì wí pé má ṣe bẹ̀rù wọn, nítorí tí èmi wà pẹ̀lú rẹ èmi ó sì gbà ọ́. OLúWA sì na ọwọ́ rẹ̀, ó sì fi kàn mí lẹ́nu, ó sì wí fún mi pé nísinsin yìí mo ti fi ọ̀rọ̀ mi sí inú ẹnu rẹ Wò ó, mo yàn ọ́ lórí àwọn orílẹ̀-èdè àti ìjọba gbogbo láti fàtu, láti wó lulẹ̀, láti bàjẹ́, láti jágbà, láti máa kọ́, àti láti máa gbìn. Ọ̀rọ̀ OLúWA sì tọ mí wá wí pé: “Kí ni o rí Jeremiah?” Mo sì dáhùn wí pé “Mo rí ẹ̀ka igi almondi.” OLúWA sì wí fún mi pé, “Ó ti rí i bí ó ṣe yẹ, nítorí pé mo ti ń ṣọ láti rí i pé ọ̀rọ̀ mi wá sí ìmúṣẹ.” Ọ̀rọ̀ OLúWA sì tún tọ̀ mi wá ní ẹ̀ẹ̀kejì pé, “Kí ni o rí?” Mo sì dáhùn pé mo rí ìkòkò gbígbóná, tí ó ń ru láti apá àríwá. OLúWA, sì wí fún mi pé, “Láti apá àríwá ni a ó ti mu ìdààmú wá sórí gbogbo àwọn tí ó ń gbé ní ilẹ̀ náà. Mo sì ti ṣetán láti pe gbogbo àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè àríwá níjà,” ni OLúWA wí. Àwọn ọba wọn yóò wá gbé ìtẹ́ wọn ró ní ojú ọ̀nà àbáwọlé Jerusalẹmu. Wọn ó sì dìde sí gbogbo àyíká wọn àti sí gbogbo àwọn ìlú Juda. Èmi yóò sì kéde ìdájọ́ mi lórí àwọn ènìyàn mi nítorí ìwà búburú wọn nípa kíkọ̀ mí sílẹ̀, nípa rírúbọ sí ọlọ́run mìíràn àti sínsin àwọn ohun tí wọ́n fi ọwọ́ wọn ṣe. “Wà ní ìmúrasílẹ̀! Dìde dúró kí o sì sọ fún wọn ohunkóhun tí mo bá pàṣẹ fún wọn. Má ṣe jẹ́ kí wọ́n dẹ́rùbà ọ́, èmi yóò sì sọ ọ́ di ẹ̀rù níwájú wọn. Ní òní èmi ti sọ ọ́ di ìlú alágbára, òpó irin àti odi idẹ sí àwọn ọba Juda, àwọn ìjòyè rẹ̀, sí àwọn àlùfáà àti àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà. Wọn yóò dojú ìjà kọ ọ́, wọn kì yóò borí rẹ, nítorí wí pé èmi wà pẹ̀lú rẹ, èmi yóò sì gbà ọ́,” ni OLúWA wí.