A. Oni 9:22-57

A. Oni 9:22-57 Bibeli Mimọ (YBCV)

Abimeleki sí ṣe olori awọn ọmọ Israeli li ọdún mẹta. Ọlọrun si rán ẹmi buburu sãrin Abimeleki ati awọn ọkunrin Ṣekemu; awọn ọkunrin Ṣekemu si fi arekereke bá Abimeleki lò: Ki ìwa-ìka ti a ti hù si awọn ãdọrin ọmọ Jerubbaali ki o le wá, ati ẹ̀jẹ wọn sori Abimeleki arakunrin wọn, ẹniti o pa wọn; ati sori awọn ọkunrin Ṣekemu, awọn ẹniti o ràn a lọwọ lati pa awọn arakunrin rẹ̀. Awọn ọkunrin Ṣekemu si yàn awọn enia ti o ba dè e lori òke, gbogbo awọn ti nkọja lọdọ wọn ni nwọn si njà a li ole: nwọn si sọ fun Abimeleki. Gaali ọmọ Ebedi si wá ti on ti awọn arakunrin rẹ̀, nwọn si kọja lọ si Ṣekemu: awọn ọkunrin Ṣekemu si gbẹkẹ wọn le e. Nwọn si jade lọ si oko, nwọn si ká eso-àjara wọn, nwọn si fọ́n eso na, nwọn si nṣe ariya, nwọn si lọ si ile oriṣa wọn, nwọn si jẹ, nwọn si mu, nwọn si fi Abimeleki ré. Gaali ọmọ Ebedi si wipe, Tani Abimeleki? ta si ni Ṣekemu, ti awa o fi ma sìn i? Ṣe ọmọ Jerubbaali ni iṣe? ati Sebulu ijoye rẹ̀? ẹ mã sìn awọn ọkunrin Hamoru baba Ṣekemu: ṣugbọn nitori kili awa o ha ṣe ma sìn on? Awọn enia wọnyi iba wà ni ikawọ mi! nigbana ni emi iba ṣí Abimeleki ni ipò. On si wi fun Abimeleki pe, Gbá ogun kún ogun rẹ, ki o si jade. Nigbati Sebulu alaṣẹ ilu na si gbọ́ ọ̀rọ Gaali ọmọ Ebedi, o binu gidigidi. On si rán awọn onṣẹ ìkọkọ si Abimeleki, wipe, Kiyesi i, Gaali ọmọ Ebedi ati awọn arakunrin rẹ̀ wá si Ṣekemu; si kiyesi i, nwọn rú ilú na sokè si ọ. Njẹ nitorina, dide li oru, iwọ ati awọn enia ti o wà pẹlu rẹ, ki ẹnyin ki o si ba sinu oko: Yio si ṣe, li owurọ̀, lojukanna bi õrùn ba si ti là, ki iwọ ki o dide ni kùtukutu owurọ̀, ki iwọ ki o si kọlù ilu na: si kiyesi i, nigbati on ati awọn enia ti mbẹ lọdọ rẹ̀ ba jade tọ̀ ọ, nigbana ni ki iwọ ki o ṣe si wọn bi iwọ ba ti ri pe o yẹ. Abimeleki si dide, ati gbogbo awọn enia ti o wà lọdọ rẹ̀ li oru, nwọn si ba ni ipa mẹrin leti Ṣekemu. Gaali ọmọ Ebedi si jade, o si duro li ẹnu-ọ̀na ibode ilu na: Abimeleki si dide, ati awọn enia ti o wà lọdọ rẹ̀, kuro ni ibùba. Nigbati Gaali si ri awọn enia na, o wi fun Sebulu pe, Wò o, awọn enia nti ori òke sọkalẹ wa. Sebulu si wi fun u pe, Ojiji òke wọnni ni iwọ ri bi ẹnipe enia. Gaali si tun wipe, Wò o, awọn enia nti òke sọkalẹ li agbedemeji ilẹ wá, ẹgbẹ kan si nti ọ̀na igi-oaku Meonenimu wá. Nigbana ni Sebulu wi fun u pe, Nibo li ẹnu rẹ wà nisisiyi, ti iwọ fi wipe, Tani Abimeleki, ti awa o fi ma sìn i? awọn enia ti iwọ ti gàn kọ́ ni iwọnyi? jọwọ jade lọ, nisisiyi, ki o si bà wọn jà. Gaali si jade niwaju awọn ọkunrin Ṣekemu, o si bá Abimeleki jà. Abimeleki si lé e, on si sá niwaju rẹ̀, ọ̀pọlọpọ ninu nwọn ti o gbọgbẹ si ṣubu, titi dé ẹnu-ọ̀na ibode. Abimeleki si joko ni Aruma: Sebulu si tì Gaali ati awọn arakunrin rẹ̀ jade, ki nwọn ki o má ṣe joko ni Ṣekemu. O si ṣe ni ijọ keji, ti awọn enia si jade lọ sinu oko; nwọn si sọ fun Abimeleki. On si mu awọn enia, o si pín wọn si ipa mẹta, o si ba ninu oko: o si wò, si kiyesi i, awọn enia nti ilu jade wá; on si dide si wọn, o si kọlù wọn. Abimeleki, ati ẹgbẹ́ ti o wà lọdọ rẹ̀ sure siwaju, nwọn si duro li ẹnu-ọ̀na ibode ilu na: ẹgbẹ meji si sure si gbogbo awọn enia na ti o wà ninu oko, nwọn si kọlù wọn. Abimeleki si bá ilu na jà ni gbogbo ọjọ́ na; on si kó ilu na, o si pa awọn enia ti o wà ninu rẹ̀, o si wó ilu na palẹ, o si fọn iyọ̀ si i. Nigbati gbogbo awọn ọkunrin ile-ẹṣọ́ Ṣekemu gbọ́, nwọn si wọ̀ inu ile-ẹṣọ́ oriṣa Eliberiti lọ. A si sọ fun Abimeleki pe, gbogbo awọn ọkunrin ile-ẹṣọ́ Ṣekemu kó ara wọn jọ pọ̀. Abimeleki si gùn ori òke Salmoni lọ, on ati gbogbo enia ti o wà pẹlu rẹ̀; Abimeleki si mu ãke kan li ọwọ́ rẹ̀, o si ke ẹka kan kuro lara igi, o si mú u, o si gbé e lé èjika rẹ̀, o si wi fun awọn enia ti o wà lọdọ rẹ̀ pe, Ohun ti ẹnyin ri ti emi ṣe, ẹ yára, ki ẹ si ṣe bi emi ti ṣe. Gbogbo awọn enia na pẹlu, olukuluku si ke ẹka tirẹ̀, nwọn si ntọ̀ Abimeleki lẹhin, nwọn si fi wọn sinu ile-ẹṣọ́ na, nwọn si tinabọ ile na mọ́ wọn lori, tobẹ̃ ti gbogbo awọn ọkunrin ile-ẹṣọ́ Ṣekemu fi kú pẹlu, ìwọn ẹgbẹrun enia, ọkunrin ati obinrin. Nigbana ni Abimeleki lọ si Tebesi, o si dótì Tebesi, o si kó o. Ṣugbọn ile-ẹṣọ́ ti o lagbara wà ninu ilu na, nibẹ̀ ni gbogbo awọn ọkunrin ati awọn obinrin, ati gbogbo awọn ẹniti o wà ni ilu na gbé sá si, nwọn si fara wọn mọ́ ibẹ̀; nwọn si gòke ile-ẹṣọ́ na lọ. Abimeleki si wá si ibi ile-ẹṣọ́ na, o si bá a jà, o si sunmọ ẹnu-ọ̀na ile-ẹṣọ na lati fi iná si i. Obinrin kan si sọ ọlọ lù Abimeleki li ori, o si fọ́ ọ li agbári. Nigbana li o pè ọmọkunrin ti nrù ihamọra rẹ̀ kánkan, o si wi fun u pe, Fà idà rẹ yọ, ki o si pa mi, ki awọn enia ki o má ba wi nipa ti emi pe, Obinrin li o pa a. Ọmọkunrin rẹ̀ si gún u, bẹ̃li o si kú. Nigbati awọn ọkunrin Israeli si ri pe, Abimeleki kú, nwọn si lọ olukuluku si ipò rẹ̀. Bayi li Ọlọrun san ìwa buburu Abimeleki, ti o ti hù si baba rẹ̀, niti pe, o pa ãdọrin awọn arakunrin rẹ̀: Ati gbogbo ìwa buburu awọn ọkunrin Ṣekemu li Ọlọrun si múpada sori wọn: egún Jotamu ọmọ Jerubbaali si ṣẹ sori wọn.

A. Oni 9:22-57 Yoruba Bible (YCE)

Abimeleki jọba lórí Israẹli fún ọdún mẹta. Ọlọrun rán ẹ̀mí burúkú sí ààrin Abimeleki ati àwọn ara ìlú Ṣekemu. Àwọn ará ìlú Ṣekemu sì dìtẹ̀ mọ́ Abimeleki. Kí ẹ̀san pípa tí Abimeleki pa àwọn aadọrin ọmọ baba rẹ̀ ati ẹ̀jẹ̀ wọn lè wá sórí Abimeleki, ati àwọn ará ìlú Ṣekemu tí wọ́n kì í láyà láti pa wọ́n. Àwọn ará ìlú Ṣekemu bá rán àwọn kan ninu wọn, wọ́n lọ ba ní ibùba ní orí òkè de Abimeleki. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí dá gbogbo àwọn tí wọn ń kọjá lọ́nà; ni ìròyìn bá kan Abimeleki. Gaali ọmọ Ebedi ati àwọn arakunrin rẹ̀ kó lọ sí Ṣekemu, àwọn ará ìlú Ṣekemu sì gbẹ́kẹ̀lé e. Àwọn ará ìlú Ṣekemu lọ sinu oko wọn, wọ́n ká èso àjàrà, wọ́n fi pọn ọtí fún wọn. Wọ́n jọ ń ṣe àríyá, wọ́n jọ lọ sí ilé oriṣa wọn, wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fi Abimeleki ṣe ẹlẹ́yà. Gaali ọmọ Ebedi bá bèèrè pé, “Ta tilẹ̀ ni Abimeleki? Báwo sì ni àwa ará ìlú Ṣekemu ṣe jẹ́ sí i, tí a fi níláti máa sìn ín? Ṣebí àwọn ọmọ Hamori, baba Ṣekemu, ni Gideoni ati Sebulu, iranṣẹ rẹ̀ máa ń sìn? Kí ló dé tí àwa fi níláti máa sin Abimeleki? Ìbá ṣe pé ìkáwọ́ mi ni àwọn eniyan yìí wà, ǹ bá yọ Abimeleki kúrò lórí oyè. Ǹ bá sọ fún Abimeleki pé kí ó lọ wá kún àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kí ó jáde wá bá mi jà.” Nígbà tí Sebulu, olórí ìlú náà gbọ́ ohun tí Gaali, ọmọ Ebedi wí, inú bí i gidigidi. Ó ranṣẹ sí Abimeleki ní Aruma, ó ní, “Gaali, ọmọ Ebedi, ati àwọn arakunrin rẹ̀ ti dé sí Ṣekemu, wọn kò sì ní gbà fún ọ kí o wọ ibí mọ́. Nítorí náà, tí ó bá di òru, kí ìwọ ati àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu rẹ lọ ba níbùba. Bí ilẹ̀ bá ti mọ́, tí oòrùn sì bẹ̀rẹ̀ sí yọ, gbéra, kí o sì gbógun ti ìlú náà. Nígbà tí Gaali ati àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ bá sì jáde sí ọ, mú wọn dáradára, kí o sì ṣe ẹ̀tọ́ fún wọn.” Abimeleki ati àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ bá gbéra ní òru, wọ́n lọ ba níbùba lẹ́gbẹ̀ẹ́ Ṣekemu, ní ìsọ̀rí mẹrin. Gaali ọmọ Ebedi bá jáde, ó dúró ní ẹnu ọ̀nà bodè ìlú náà, Abimeleki ati àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ sì jáde níbi tí wọ́n ba sí. Nígbà tí Gaali rí wọn, ó sọ fún Sebulu pé, “Wò ó, àwọn eniyan kan ń sọ̀kalẹ̀ bọ̀ láti orí òkè.” Sebulu dá a lóhùn pé, “Òjìji òkè ni ò ń wò tí o ṣebí eniyan ni.” Gaali tún dáhùn, ó ní, “Tún wò ó, àwọn eniyan kan ń bọ̀ láti agbede meji ilẹ̀ náà, àwọn kan sì ń bọ̀ láti apá ibi igi Oaku àwọn tíí máa ń wo iṣẹ́.” Ṣugbọn Sebulu dá a lóhùn, pé, “Gbogbo ẹnu tí ò ń fọ́n pin, tabi kò pin? Ṣebí ìwọ ni o wí pé, ‘Kí ni Abimeleki jẹ́ tí a fi ń sìn ín.’ Àwọn tí ò ń gàn ni wọ́n dé yìí, yára jáde kí o lọ gbógun tì wọ́n.” Gaali bá kó àwọn ọkunrin Ṣekemu lẹ́yìn, wọ́n lọ gbógun ti Abimeleki. Abimeleki lé Gaali, Gaali sì sá fún un, ọpọlọpọ eniyan fara gbọgbẹ́ títí dé ẹnu ibodè ìlú. Abimeleki tún lọ ń gbé Aruma. Sebulu bá lé Gaali ati àwọn arakunrin rẹ̀ jáde kúrò ní ìlú, kò sì jẹ́ kí wọ́n gbé Ṣekemu mọ́. Nígbà tí ó di ọjọ́ keji, Abimeleki gbọ́ pé àwọn ará Ṣekemu ń jáde lọ sinu pápá. Ó kó àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀, ó pín wọn sí ìsọ̀rí mẹta, wọ́n sì ba níbùba ninu pápá. Bí ó ti rí i pé àwọn eniyan náà ń jáde bọ̀ láti inú ìlú, ó gbógun tì wọ́n, ó sì pa wọ́n. Abimeleki ati àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀ sáré, wọ́n lọ gba ẹnu ọ̀nà bodè ìlú. Àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun meji yòókù sáré sí gbogbo àwọn tí wọ́n wà ninu pápá, wọ́n pa wọ́n. Abimeleki gbógun ti ìlú náà ní gbogbo ọjọ́ náà, ó gbà á, ó sì pa àwọn eniyan inú rẹ̀; ó wó gbogbo ìlú náà palẹ̀, ó sì da iyọ̀ sí i. Nígbà tí gbogbo àwọn tí wọ́n ń gbé ilé ìṣọ́ tí ó wà ní Ṣekemu gbọ́, wọ́n sá lọ sí ibi ààbò tí ó wà ní ilé Eli-beriti. Wọ́n sọ fún Abimeleki pé gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní ilé ìṣọ́ tí ó wà ní Ṣekemu ti kó ara wọn jọ sí ibìkan. Abimeleki bá lọ sí òkè Salimoni, òun ati gbogbo àwọn tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀. Ó mú àáké kan lọ́wọ́, ó fi gé ẹrù igi kan jọ, ó gbé e lé èjìká, ó sì sọ fún àwọn tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ pé, “Ẹ yára ṣe bí ẹ ti rí mi tí mo ṣe.” Olukuluku wọn náà bá gé ẹrù igi kọ̀ọ̀kan, wọ́n tẹ̀lé Abimeleki. Wọ́n to ẹrù igi wọn jọ sí ara ibi ààbò náà, wọn sọ iná sí i. Gbogbo àwọn tí wọ́n wà ninu ilé ìṣọ́ Ṣekemu sì kú patapata. Wọ́n tó ẹgbẹrun (1,000) eniyan, atọkunrin, atobinrin. Abimeleki tún lọ sí Tebesi, ó gbógun tì í, ó sì gbà á. Ṣugbọn ilé ìṣọ́ kan tí ó lágbára wà ninu ìlú náà, gbogbo àwọn ará ìlú sá lọ sinu rẹ̀, atọkunrin, atobinrin. Wọ́n ti ara wọn mọ́ inú rẹ̀, wọ́n sì gun òkè ilé ìṣọ́ náà lọ. Nígbà tí Abimeleki dé ibi ilé ìṣọ́ náà, ó gbógun tì í. Ó súnmọ́ ẹnu ọ̀nà ilé ìṣọ́ náà láti dáná sun ún. Obinrin kan bá gbé ọmọ ọlọ kan, ó sọ ọ́ sílẹ̀, ọmọ ọlọ yìí bá Abimeleki lórí, ó sì fọ́ agbárí rẹ̀. Ó yára pe ọdọmọkunrin tí ń ru ihamọra rẹ̀, ó wí fún un pé, “Fa idà rẹ yọ, kí o pa mí, kí àwọn eniyan má baà máa wí pé, ‘Obinrin kan ni ó pa á.’ ” Ọdọmọkunrin yìí bá gún un ní idà, ó sì kú. Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli rí i pé Abimeleki ti kú, olukuluku gba ilé rẹ̀ lọ. Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun ṣe gbẹ̀san lára Abimeleki fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ baba rẹ̀, nítorí pé, ó pa aadọrin àwọn arakunrin rẹ̀. Ọlọrun sì mú kí gbogbo ìwà ibi àwọn ará Ṣekemu pada sórí wọn. Èpè tí Jotamu ọmọ Gideoni ṣẹ́ sì ṣẹ mọ́ wọn lára.

A. Oni 9:22-57 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Lẹ́yìn tí Abimeleki ti ṣe àkóso Israẹli fún ọdún mẹ́ta, Ọlọ́run rán ẹ̀mí búburú sáàárín Abimeleki àti àwọn ará Ṣekemu, àwọn ẹni tí ó hu ìwà ọ̀tẹ̀. Ọlọ́run ṣe èyí láti gbẹ̀san àwọn ìwà búburú, àti ìtàjẹ̀ sílẹ̀ àwọn àádọ́rin (70) ọmọ Jerubbaali lára Abimeleki arákùnrin wọn àti lára àwọn ènìyàn Ṣekemu, ẹni tí ó ràn án lọ́wọ́ láti pa àwọn arákùnrin rẹ̀. Nítorí ìkórìíra tí wọ́n ni sí àwọn olórí, ni Ṣekemu dẹ àwọn ènìyàn sí àwọn orí òkè láti máa dá àwọn ènìyàn tó ń kọjá lọ́nà, kí wọn sì máa jà wọ́n lólè, àwọn kan ló sọ èyí fún Abimeleki. Gaali ọmọ Ebedi àti àwọn arákùnrin rẹ̀ wá sí Ṣekemu, àwọn ará Ṣekemu sì gbẹ́kẹ̀lé wọn, wọ́n sì fi inú tán wọn. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n jáde lọ sí oko, wọ́n sì ṣa èso àjàrà wọn jọ, wọ́n fún èso àjàrà náà, wọ́n sì ṣe àjọ̀dún nínú ilé òrìṣà wọn. Nígbà tí wọ́n ń jẹ tí wọ́n ń mu wọ́n fi Abimeleki ré. Gaali ọmọ Ebedi dáhùn pé, “Ta ni Abimeleki tàbí ta ni Ṣekemu tí àwa ó fi sìn ín? Ọmọ Jerubbaali kọ́ ní ṣe tàbí Sebulu kọ́ ní igbákejì rẹ̀? Ẹ má sin àwọn ará Hamori baba àwọn ará Ṣekemu, Èéṣe tí a ó fi sin Abimeleki? Bí àwọn ènìyàn yìí bá wà ní abẹ́ ìṣàkóso mi ni! Ẹ̀yin ó bọ́ àjàgà rẹ̀ kúrò ní ọrùn yín (Èmi yóò yọ Abimeleki kúrò). Èmi yóò wí fún Abimeleki pé, ‘Kó gbogbo àwọn ogun rẹ jáde láti jà.’ ” Nígbà tí Sebulu, alákòóso ìlú náà gbọ́ ohun tí Gaali ọmọ Ebedi sọ, inú bí i gidigidi. Ó ránṣẹ́ sí Abimeleki pé, “Gaali ọmọ Ebedi àti àwọn arákùnrin rẹ̀ wá láti máa gbé ní Ṣekemu ṣùgbọ́n, wọ́n ń rú àwọn ènìyàn sókè láti ṣọ̀tẹ̀ sí ọ. Wá ní òru kí ìwọ àti àwọn ogun rẹ sápamọ́ dè wọ́n nínú igbó. Ní òwúrọ̀ kùtùkùtù bí oòrùn ti ń yọ ìwọ yóò wọ inú ìlú náà lọ láti bá a jà. Yóò sì ṣe nígbà tí Gaali àti àwọn ogun rẹ̀ tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ bá jáde sí ọ láti bá ọ jà, ìwọ yóò ṣe ohunkóhun tí o bá fẹ́ sí wọn.” Abimeleki àti gbogbo àwọn ogun rẹ̀ sì jáde ní òru, wọ́n sì sápamọ́ sí ọ̀nà mẹ́rin yí Ṣekemu ká. Gaali ọmọ Ebedi jáde síta, ó sì dúró ní ẹnu-ọ̀nà ibodè ìlú náà ní àkókò tí Abimeleki àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ jáde kúrò níbi tí wọn sápamọ́ sí. Nígbà tí Gaali rí àwọn ènìyàn náà, ó sọ fún Sebulu pé, “Wò ó, àwọn ènìyàn ń ti orí òkè sọ̀kalẹ̀ wá!” Sebulu sì wí fún un pé, “Òjìji òkè wọ̀n-ọn-nì ni ìwọ rí bi ẹni pé ènìyàn.” Gaali ké ó ní, “Wòkè, àwọn ènìyàn ń tọ̀ wá bọ̀ láti agbede-méjì ilẹ̀ wá àti ẹ̀gbẹ́ kan sì ń ti ọ̀nà igi óákù Meonenimu wá.” Nígbà náà ni Sebulu dá a lóhùn pé, “Níbo ni ẹnu tí ó ń ṣe ni wà báyìí. Ṣe bí o wí pé, ‘Ta ni Abimeleki tí àwa ó fi máa sìn ín?’ Àwọn ẹni tí ó gàn án kọ́ nìyí? Jáde lọ kí o sì bá wọn jà!” Gaali sì síwájú àwọn ogun ará Ṣekemu lọ kọjú Abimeleki láti bá wọn jagun. Abimeleki sì lé e, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ-ogun ṣubú wọ́n sì gbọgbẹ́ bí wọ́n ṣe ń sálọ, títí dé ẹnu-ọ̀nà ibùdó ìlú náà. Abimeleki dúró sí Aruma, nígbà tí Sebulu lé Gaali àti àwọn arákùnrin rẹ̀ kúrò ni Ṣekemu, kò sì jẹ́ kí wọ́n gbé Ṣekemu mọ́. Ní ọjọ́ kejì àwọn ará Ṣekemu sì jà lọ́ sí oko, ẹnìkan ló ṣe òfófó rẹ̀ fún Abimeleki. Ó kó àwọn ènìyàn rẹ̀, ó pín wọn sí ẹgbẹ́ mẹ́ta ó sì sápamọ́ sí inú oko. Nígbà tí ó sì rí tí àwọn ènìyàn náà ń jáde kúrò nínú ìlú, ó dìde ó gbóguntì wọ́n. Abimeleki àti àwọn ọmọ-ogun tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ sáré síwájú, wọ́n gba ẹnu ibodè ìlú náà, wọ́n sì dúró níbẹ̀. Àwọn ẹgbẹ́ méjì tókù sì sáré sí àwọn tó wà ní oko wọ́n sì gbóguntì wọ́n. Ní gbogbo ọjọ́ náà ni Abimeleki fi bá àwọn ará ìlú náà jà, ó sì ṣẹ́gun wọn, ó sì pa àwọn ènìyàn ìlú náà ó wó ìlú náà palẹ̀ pátápátá ó sì fọ́n iyọ̀ sí i. Àwọn ènìyàn ilé ìṣọ́ Ṣekemu gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀, wọ́n sálọ fún ààbò sí inú ilé ìṣọ́ òrìṣà El-Beriti. Nígbà tí wọ́n sọ fún Abimeleki pé gbogbo àwọn ènìyàn ilé ìṣọ́ Ṣekemu kó ara wọn jọ pọ̀. Abimeleki àti gbogbo àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ gun òkè Salmoni lọ. Ó gé àwọn ẹ̀ka díẹ̀ pẹ̀lú àáké, ó gbé àwọn ẹ̀ka wọ̀nyí sí èjìká rẹ̀. Ó sọ fún àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ pé, “Ẹ ṣe ohun tí ẹ rí tí mo ń ṣe yìí ní kíákíá.” Báyìí gbogbo àwọn ọkùnrin tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ gé àwọn ẹ̀ka igi wọn tẹ̀lé Abimeleki. Wọ́n kó wọn ti ilé ìṣọ́ agbára níbi tí àwọn ènìyàn sápamọ́ sí wọ́n sì fi iná sí i, tóbẹ́ẹ̀ tí gbogbo àwọn ọkùnrin ilé ìṣọ́ Ṣekemu fi kú pẹ̀lú. Gbogbo àwọn ènìyàn náà tí ó tó ẹgbẹ̀rún ènìyàn lọ́kùnrin àti lóbìnrin sì kú. Abimeleki tún lọ sí Tebesi, ó yí ìlú náà ká pẹ̀lú àwọn ọmọ-ogun, ó sì ṣẹ́gun rẹ̀. Ilé ìṣọ́ kan tí ó ní agbára sì wà nínú ìlú náà. Gbogbo àwọn ènìyàn ìlú náà ọkùnrin àti obìnrin sá sínú ilé ìṣọ́ náà. Wọ́n ti ara wọn mọ́ ibẹ̀ wọ́n sì sálọ sí inú àjà ilé ìṣọ́ náà. Abimeleki lọ sí ìsàlẹ̀ ilé ìṣọ́ náà, ó sì ń bá a jà. Ṣùgbọ́n bí ó ti súnmọ́ ẹnu-ọ̀nà ilé ìṣọ́ náà láti dáná sun ún, obìnrin kan sọ ọmọ ọlọ lu Abimeleki lórí, ó sì fọ́ ọ ní agbárí. Ní ojú kan náà ni ó pe ẹni tí ó ru àpáta rẹ̀ pé, “Yára yọ idà rẹ kí o sì pa mí, kí wọn má ba à sọ pé, ‘Obìnrin ni ó pa á.’ ” Ọ̀dọ́mọkùnrin náà sì fi ọ̀kọ̀ gún un, ó sì kú. Nígbà tí àwọn ará Israẹli rí i pé Abimeleki kú, olúkúlùkù wọn padà sí ilé rẹ̀. Báyìí ni Ọlọ́run san ẹ̀san ìwà búburú ti Abimeleki hù sí baba rẹ̀ ní ti pípa tí ó pa, àwọn àádọ́rin (70) arákùnrin rẹ̀. Ọlọ́run jẹ́ kí ìwà búburú àwọn ará Ṣekemu pẹ̀lú padà sí orí wọn. Ègún Jotamu ọmọ Jerubbaali pàápàá wá sí orí wọn.