A. Oni 8:1-17
A. Oni 8:1-17 Bibeli Mimọ (YBCV)
AWỌN ọkunrin Efraimu si wi fun u pe, Kili eyiti iwọ ṣe si wa bayi, ti iwọ kò fi pè wa, nigbati iwọ nlọ bá awọn ara Midiani jà? Nwọn si bá a sọ̀ gidigidi. On si wi fun wọn pe, Kini mo ha ṣe nisisiyi ti a le fiwe ti nyin? Ẽṣẹ́ àjara Efraimu kò ha san jù ikore-àjara Abieseri lọ? Ọlọrun sá ti fi awọn ọmọ-alade Midiani lé nyin lọwọ, Orebu ati Seebu: kini mo si le ṣe bi nyin? Nigbana ni inu wọn tutù si i, nigbati o ti wi eyinì. Gideoni si dé odò Jordani, o si rekọja, on ati ọdunrun ọkunrin ti o wà lọdọ rẹ̀, o di ãrẹ, ṣugbọn nwọn nlepa sibẹ̀. On si wi fun awọn ọkunrin Sukkotu pe, Emi bẹ̀ nyin, ẹ fi ìṣu-àkara melokan fun awọn enia wọnyi ti ntọ̀ mi lẹhin: nitoriti o di ãrẹ fun wọn, emi si nlepa Seba ati Salmunna, awọn ọba Midiani. Awọn ọmọ-alade Sukkotu si wi pe, ọwọ́ rẹ ha ti ítẹ Seba on Salmunna na, ti awa o fi fun awọn ogun rẹ li onjẹ? Gideoni si wipe, Nitorina nigbati OLUWA ba fi Seba ati Salmunna lé mi lọwọ, nigbana li emi o fi ẹgún ijù, ati oṣuṣu yà ẹran ara nyin. On si gòke lati ibẹ̀ lọ si Penueli, o si sọ fun wọn bẹ̃ gẹgẹ: awọn ọkunrin Penueli si da a lohùn gẹgẹ bi awọn ara Sukkotu si ti da a lohùn. On si wi fun awọn ọkunrin Penueli pẹlu pe, Nigbati mo ba pada dé li alafia, emi o wó ile-ẹṣọ́ yi lulẹ̀. Njẹ Seba ati Salmunna wà ni Karkori, ogun wọn si wà pẹlu wọn, o to ìwọn ẹdẹgbajọ ọkunrin, iye awọn ti o kù ninu gbogbo ogun awọn ọmọ ìha ìla-õrùn: nitoripe ẹgba ọgọta ọkunrin ti o lo idà ti ṣubu. Gideoni si gbà ọ̀na awọn ti ngbé inú agọ́ ni ìha ìla-õrùn Noba ati Jogbeha gòke lọ, o si kọlù ogun na; nitoriti ogun na ti sọranù. Seba ati Salmunna si sá; on si lepa wọn; o si mù awọn ọba Midiani mejeji na, Seba ati Salmunna, o si damu gbogbo ogun na. Gideoni ọmọ Joaṣi si pada lẹhin ogun na, ni ibi ati gòke Heresi. O si mú ọmọkunrin kan ninu awọn ọkunrin Sukkotu, o si bère lọwọ rẹ̀: on si ṣe apẹrẹ awọn ọmọ-alade Sukkotu fun u, ati awọn àgba ti o wà nibẹ̀, mẹtadilọgọrin ọkunrin. On si tọ̀ awọn ọkunrin Sukkotu na wá, o si wi fun wọn pe, Wò Seba ati Salmunna, nitori awọn ẹniti ẹnyin fi gàn mi pe, Ọwọ́ rẹ ha ti tẹ Seba ati Salmunna na, ti awa o fi fun awọn ọkunrin rẹ ti ãrẹ mu li onjẹ? On si mú awọn àgbagba ilu na, ati ẹgún ijù ati oṣuṣu, o si fi kọ́ awọn ọkunrin Sukkotu li ọgbọ́n. On si wó ile-ẹṣọ́ Penueli, o si pa awọn ọkunrin ilu na.

A. Oni 8:1-17 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn ará Efuraimu bèèrè lọ́wọ́ Gideoni pé, “Irú kí ni o ṣe yìí, tí o kò pè wá, nígbà tí o lọ gbógun ti àwọn ara Midiani?” Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ sí i pẹlu ibinu. Ó dá wọn lóhùn, ó ní, “Kí ni mo ṣe lẹ́gbẹ̀ẹ́ èyí tí ẹ̀yin ṣe? Ohun tí ẹ̀yin ará Efuraimu ṣe, tí ẹ rò pé ohun kékeré ni yìí, ó ju gbogbo ohun tí àwọn ará Abieseri ṣe, tí ẹ kà kún nǹkan bàbàrà lọ. Ẹ̀yin ni Ọlọrun fi Orebu ati Seebu, àwọn ọmọ ọba Midiani mejeeji lé lọ́wọ́. Kí ni ohun tí mo ṣe lẹ́gbẹ̀ẹ́ èyí tí ẹ̀yin ṣe?” Nígbà tí wọ́n gbọ́ bí ó ṣe dá wọn lóhùn, inú wọ́n yọ́. Gideoni bá lọ sí odò Jọdani, ó sì kọjá odò náà sí òdìkejì rẹ̀, òun ati àwọn ọọdunrun (300) ọkunrin tí wọ́n tẹ̀lé e. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti rẹ̀ wọ́n, sibẹsibẹ wọ́n ń lé àwọn ará Midiani lọ. Ó bẹ àwọn ará Sukotu, ó ní, “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ fún àwọn tí wọ́n tẹ̀lé mi ní oúnjẹ, nítorí pé ó ti rẹ̀ wọ́n, ati pé à ń lé Seba ati Salimuna, àwọn ọba Midiani mejeeji lọ ni.” Àwọn ìjòyè Sukotu dá a lóhùn, wọ́n ní, “Ṣé ọwọ́ rẹ ti tẹ Seba ati Salimuna ni, tí a óo fi fún ìwọ ati àwọn ọmọ ogun rẹ ní oúnjẹ?” Gideoni dá wọn lóhùn pé, “Kò burú, nígbà tí OLUWA bá fi Seba ati Salimuna lé mi lọ́wọ́, ẹ̀gún ọ̀gàn aṣálẹ̀ ati òṣùṣú ni n óo fi ya ẹran ara yín.” Ó kúrò níbẹ̀ lọ sí Penueli, ó sọ ohun kan náà fún wọn, ṣugbọn irú èsì tí àwọn ará Sukotu fún un ni àwọn ará Penueli náà fún un. Ó sọ fún àwọn ará Penueli pé, “Nígbà tí mo bá pada dé ní alaafia n óo wó ilé ìṣọ́ yìí.” Seba ati Salimuna wà ní ìlú Karikori pẹlu àwọn ọmọ ogun wọn yòókù, gbogbo àwọn ọmọ ogun ìlà oòrùn tí wọ́n ṣẹ́kù kò ju nǹkan bí ẹẹdẹgbaajọ (15,000) lọ, nítorí pé àwọn tí wọ́n ti kú ninu àwọn ọmọ ogun wọn tí wọ́n ń lo idà tó ọ̀kẹ́ mẹfa (120,000). Ọ̀nà èrò tí ó wà ní ìlà oòrùn Noba ati Jogibeha ni Gideoni gbà lọ, ó lọ jálu àwọn ọmọ ogun náà láì rò tẹ́lẹ̀. Seba ati Salimuna bá bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ, ṣugbọn Gideoni lé àwọn ọba Midiani mejeeji yìí títí tí ó fi mú wọn. Jìnnìjìnnì bá dàbo gbogbo àwọn ọmọ ogun wọn. Ọ̀nà àtigun òkè Heresi ni Gideoni gbà nígbà tí ó ń ti ojú ogun pada bọ̀. Ọwọ́ rẹ̀ tẹ ọdọmọkunrin ará Sukotu kan, ó sì bèèrè orúkọ àwọn olórí ati àwọn àgbààgbà ìlú Sukotu lọ́wọ́ rẹ̀. Ọdọmọkunrin yìí sì kọ orúkọ wọn sílẹ̀, wọ́n jẹ́ ọkunrin mẹtadinlọgọrin. Ó bá wá sọ́dọ̀ àwọn ọkunrin Sukotu, ó ní, “Ẹ wo Seba ati Salimuna, àwọn ẹni tí ẹ tìtorí wọn pẹ̀gàn mi pé ọwọ́ mi kò tíì tẹ̀ wọ́n, tí ẹ kò sì fún àwọn ọmọ ogun mi tí àárẹ̀ mú ní oúnjẹ. Seba ati Salimuna náà nìyí o.” Ó kó gbogbo àwọn àgbààgbà ìlú náà, ó sì mú ẹ̀gún ọ̀gàn ati òṣùṣú, ó fi kọ́ wọn lọ́gbọ́n. Lẹ́yìn náà ó lọ sí Penueli, ó wó ilé ìṣọ́ wọn, ó sì pa àwọn ọkunrin ìlú náà.
A. Oni 8:1-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àwọn àgbàgbà ẹ̀yà Efraimu sì bínú gidigidi sí Gideoni wọ́n bi í léèrè pé, kí ló dé tí o fi ṣe irú èyí sí wa? Èéṣe tí ìwọ kò fi pè wá nígbà tí ìwọ kọ́kọ́ jáde lọ láti bá àwọn ará Midiani jagun? Ohùn ìbínú ni wọ́n fi bá a sọ̀rọ̀. Ṣùgbọ́n Gideoni dá wọn lóhùn pé, “Àṣeyọrí wo ni mo ti ṣe tí ó tó fiwé tiyín? Àṣàkù àjàrà Efraimu kò ha dára ju gbogbo ìkórè àjàrà Abieseri lọ bí? Ọlọ́run ti fi Orebu àti Seebu àwọn olórí àwọn ará Midiani lé yín lọ́wọ́. Kí ni ohun tí Mose ṣe tí ó tó fiwé e yín tàbí tí ó tó àṣeyọrí i yín?” Nígbà tí ó wí èyí ríru ìbínú wọn rọlẹ̀. Gideoni àti àwọn ọ̀ọ́dúnrún (300) ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ tẹ̀síwájú láti lépa àwọn ọ̀tá bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti rẹ̀ wọ́n, wọ́n dé Jordani wọ́n sì kọjá sí òdìkejì. Ó wí fún àwọn ọkùnrin Sukkoti pé, “Ẹ fún àwọn ọmọ-ogun mi ní oúnjẹ díẹ̀, nítorí ó ti rẹ̀ wọ́n, èmi sì ń lépa Seba àti Salmunna àwọn ọba Midiani.” Ṣùgbọ́n àwọn ìjòyè Sukkoti fèsì pé ṣé ọwọ́ rẹ ti tẹ Seba àti Salmunna náà ni? Èéṣe tí àwa yóò ṣe fún àwọn ológun rẹ ní oúnjẹ? Gideoni dá wọn lóhùn pé, “Ó dára, nígbà tí OLúWA bá fi Seba àti Salmunna lé mi lọ́wọ́ tán èmi yóò fi ẹ̀gún ijù àti ẹ̀gún òṣùṣú ya ẹran-ara yín.” Láti ibẹ̀, ó lọ sí Penieli ó sì bẹ̀ wọ́n bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ṣùgbọ́n àwọn náà dá a lóhùn bí àwọn ará Sukkoti ti dá a lóhùn. Nígbà náà ni ó sọ fún àwọn ọkùnrin Penieli pé, “Nígbà tí mo bá ṣẹ́gun tí mo sì padà dé ní àlàáfíà, èmi yóò wó ilé ìṣọ́ yìí.” Ní àsìkò náà Seba àti Salmunna wà ní Karkori pẹ̀lú ọmọ-ogun wọn tí ó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15,000) ọkùnrin, àwọn wọ̀nyí ni ó ṣẹ́kù nínú gbogbo ogun àwọn ènìyàn apá ìlà-oòrùn, nítorí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́fà ọkùnrin tí ó fi idà jà ti kú ní ojú ogun. Gideoni gba ọ̀nà tí àwọn darandaran máa ń rìn ní apá ìhà ìlà-oòrùn Noba àti Jogbeha ó sì kọjú ogun sí àwọn ọmọ-ogun náà nítorí wọ́n ti túra sílẹ̀. Seba àti Salmunna, àwọn ọba Midiani méjèèjì sá, ṣùgbọ́n Gideoni lépa wọn ó sì mú wọn, ó run gbogbo ogun wọn. Gideoni ọmọ Joaṣi gba ọ̀nà ìgòkè Heresi padà sẹ́yìn láti ojú ogun. Ó mú ọ̀dọ́mọkùnrin kan ará Sukkoti, ó sì béèrè àwọn ìbéèrè ní ọwọ́ rẹ̀, ọ̀dọ́mọkùnrin náà sì kọ orúkọ àwọn ìjòyè Sukkoti mẹ́tà-dínlọ́gọ́rin fún un tí wọ́n jẹ́ àgbàgbà ìlú náà. Nígbà náà ni Gideoni wá ó sọ fún àwọn ọkùnrin Sukkoti pé, “Seba àti Salmunna nìwọ̀nyí nípa àwọn tí ẹ̀yin fi mí ṣẹ̀fẹ̀ nígbà tí ẹ wí pé, ‘Ṣé ó ti ṣẹ́gun Seba àti Salmunna? Èéṣe tí àwa ó fi fún àwọn ọmọ-ogun rẹ tí ó ti rẹ̀ ní oúnjẹ?’ ” Ó mú àwọn àgbàgbà ìlú náà, ó sì fi kọ́ àwọn Sukkoti lọ́gbọ́n nípa jíjẹ wọ́n ní yà pẹ̀lú àwọn ẹ̀gún ijù àti ẹ̀gún ọ̀gàn. Ó wó ilé ìṣọ́ Penieli, ó sì pa àwọn ọkùnrin ìlú náà.