A. Oni 7:9-15

A. Oni 7:9-15 Yoruba Bible (YCE)

OLUWA sọ fún un ní òru ọjọ́ kan náà pé, “Gbéra, lọ gbógun ti àgọ́ náà, nítorí pé mo ti fi lé ọ lọ́wọ́. Ṣugbọn bí ẹ̀rù bá ń bà ọ láti lọ, mú Pura iranṣẹ rẹ, kí ẹ jọ lọ sí ibi àgọ́ náà. O óo gbọ́ ohun tí wọ́n ń sọ, lẹ́yìn náà, o óo ní agbára láti lè gbógun ti àgọ́ náà.” Gideoni bà mú Pura, iranṣẹ rẹ̀, wọ́n jọ lọ sí ìpẹ̀kun ibi tí àwọn tí wọ́n di ihamọra ogun ninu àgọ́ wọn wà. Àwọn ará ilẹ̀ Midiani ati ti Amaleki ati àwọn ará ilẹ̀ tí ó wà ní ìlà oòrùn pọ̀ nílẹ̀ lọ bí eṣú àwọn ràkúnmí wọn kò níye, wọ́n pọ̀ bí iyanrìn etí òkun. Nígbà tí Gideoni dé ibẹ̀, ó gbọ́ tí ẹnìkan ń rọ́ àlá tí ó lá fún ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kan pé, “Mo lá àlá kan, mo rí i tí àkàrà ọkà baali kan ré bọ́ sinu ibùdó àwọn ará Midiani. Bí ó ti bọ́ lu àgọ́ náà, ó wó o lulẹ̀, ó sì dojú rẹ̀ délẹ̀, àgọ́ náà sì tẹ́ sílẹ̀ pẹrẹsẹ.” Ẹnìkejì rẹ̀ dá a lóhùn, ó ní, “Èyí kì í ṣe ohun mìíràn, bíkòṣe idà Gideoni, ọmọ Joaṣi, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Israẹli. Ọlọrun ti fi Midiani ati gbogbo ọmọ ogun rẹ̀ lé e lọ́wọ́.” Nígbà tí Gideoni gbọ́ bí ó ti rọ́ àlá yìí, ati ìtumọ̀ rẹ̀, ó yin OLUWA. Ó pada sí ibùdó Israẹli, ó ní, “Ẹ dìde, nítorí OLUWA ti fi àwọn ọmọ ogun Midiani le yín lọ́wọ́.”

A. Oni 7:9-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ní òru ọjọ́ náà OLúWA sọ fún Gideoni pé, “Dìde, dojú ogun kọ ibùdó ogun àwọn ará Midiani nítorí èmi yóò fi lé ọ lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n bí ẹ̀rù àti kọlù wọ́n bá ń bà ọ́, yọ́ wọ ibùdó wọn lọ kí o mú Pura ìránṣẹ́ rẹ lọ́wọ́ kí o sì fi ara balẹ̀ gbọ́ ohun tí wọ́n ń sọ nínú ibùdó náà. Lẹ́yìn èyí ọkàn rẹ̀ yóò le láti kọlù ibùdó náà.” Báyìí ni òun àti Pura ìránṣẹ́ rẹ̀ wọ ẹnu-ọ̀nà ibùdó yìí. Àwọn ará Midiani, àwọn ará Amaleki àti gbogbo ènìyàn ìlà-oòrùn tó lọ ní àfonífojì bí eṣú ni wọ́n rí nítorí púpọ̀ wọn. Àwọn ìbákasẹ wọn kò sì lóǹkà, wọ́n sì pọ̀ bí yanrìn inú Òkun. Gideoni dé sí àsìkò tí ọkùnrin kan bẹ̀rẹ̀ sí í rọ́ àlá tí ó lá sí ọ̀kan nínú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Ó ní, “Mo lá àlá kan, nínú àlá náà mo rí àkàrà kan tó ṣe róbótó tí a fi barle ṣe ń yí wọ inú ibùdó àwọn ará Midiani, ó sì kọlu àgọ́ pẹ̀lú agbára ńlá dé bi wí pé àgọ́ náà dojúdé, ó sì ṣubú.” Ọ̀rẹ́ rẹ̀ dá a lóhùn pé, “Èyí kò le túmọ̀ sí ohun mìíràn ju idà Gideoni ọmọ Joaṣi ará Israẹli lọ: Ọlọ́run ti fi àwọn ará Midiani àti gbogbo ogun ibùdó lé e lọ́wọ́.” Nígbà tí Gideoni gbọ́ àlá náà àti ìtumọ̀ rẹ̀, ó wólẹ̀ sin Ọlọ́run: lẹ́yìn náà ni ó padà sí ibùdó àwọn ọmọ Israẹli ó sì pè wọ́n pé, “Ẹ dìde! Nítorí pé Ọlọ́run yóò lò yín láti ṣẹ́gun gbogbo ogun Midiani.”