A. Oni 7:1-8

A. Oni 7:1-8 Bibeli Mimọ (YBCV)

NIGBANA ni Jerubbaali, ti iṣe Gideoni, ati gbogbo awọn enia ti o wà pẹlu rẹ̀, dide ni kùtukutu, nwọn si dó lẹba orisun Harodu: ibudó Midiani si wà ni ìha ariwa wọn, nibi òke More, li afonifoji. OLUWA si wi fun Gideoni pe, Awọn enia ti o wà lọdọ rẹ pọ̀ju fun mi lati fi awọn Midiani lé wọn lọwọ, ki Israeli ki o má ba gbé ara wọn ga si mi, pe, Ọwọ́ mi li o gbà mi là. Njẹ nitorina, lọ kede li etí awọn enia na, wipe, Ẹnikẹni ti o ba nfòya ti ẹ̀ru ba si mbà, ki o pada lati òke Gileadi ki o si lọ. Ẹgbã mọkanla si pada ninu awọn enia na; awọn ti o kù si jẹ́ ẹgba marun. OLUWA si wi fun Gideoni pe, Awọn enia na pọ̀ju sibẹ̀; mú wọn sọkalẹ wá si odò, nibẹ̀ li emi o gbé dan wọn wò fun ọ: yio si ṣe, ẹniti mo ba wi fun ọ pe, Eyi ni yio bá ọ lọ, on na ni yio bá ọ lọ; ẹnikẹni ti mo ba si wi fun ọ pe, Eyi ki yio bá ọ lọ, on na ni ki yio si bá ọ lọ. Bẹ̃li o mú awọn enia na wá si odò: OLUWA si wi fun Gideoni pe, Olukuluku ẹniti o ba fi ahọn rẹ̀ lá omi, bi ajá ti ma lá omi, on na ni ki iwọ ki o fi si apakan fun ara rẹ̀; bẹ̃ si li olukuluku ẹniti o kunlẹ li ẽkun rẹ̀ lati mu omi. Iye awọn ẹniti o lá omi, ti nwọn fi ọwọ́ wọn si ẹnu wọn, jẹ́ ọdunrun ọkunrin: ṣugbọn gbogbo awọn enia iyokù kunlẹ li ẽkun wọn lati mu omi. OLUWA si wi fun Gideoni pe, Nipaṣe ọdunrun ọkunrin wọnyi ti o lá omi li emi o gbà nyin, emi o si fi awọn Midiani lé ọ lọwọ: jẹ ki gbogbo awọn iyokù lọ olukuluku si ipò rẹ̀. Awọn enia na si mu onjẹ ati ipè li ọwọ́ wọn: on si rán gbogbo Israeli lọ, olukuluku sinu agọ́ rẹ̀, o si da ọdunrun ọkunrin nì duro: ibudó Midiani si wà nisalẹ rẹ̀ li afonifoji.

A. Oni 7:1-8 Yoruba Bible (YCE)

Nígbà tí ó yá, Gideoni, tí àdàpè rẹ̀ ń jẹ́ Jerubaali, ati àwọn eniyan tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀ gbéra ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ kan, wọ́n lọ pàgọ́ sí ẹ̀gbẹ́ odò Harodu. Àgọ́ ti àwọn ará Midiani wà ní apá ìhà àríwá wọn ní àfonífojì lẹ́bàá òkè More. OLUWA wí fún Gideoni pé, “Àwọn tí wọ́n wà pẹlu rẹ ti pọ̀jù fún mi, láti fi àwọn ará ilẹ̀ Midiani lé lọ́wọ́, kí àwọn ọmọ Israẹli má baà gbéraga pé agbára wọn ni wọ́n fi ṣẹgun, wọn kò sì ní fi ògo fún mi. Nítorí náà, kéde fún gbogbo wọn pé, kí ẹnikẹ́ni tí ẹ̀rù bá ń bà pada sí ilé.” Gideoni bá dán wọn wò lóòótọ́, ọ̀kẹ́ kan ati ẹgbaa (22,000) ọkunrin ninu wọn sì pada sí ilé. Àwọn tí wọ́n kù jẹ́ ẹgbaarun (10,000). OLUWA tún wí fún Gideoni pé, “Àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù yìí pọ̀jù sibẹsibẹ. Kó wọn lọ sí etí odò, n óo sì bá ọ dán wọn wò níbẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí mo bá wí fún ọ pé yóo lọ, òun ni yóo lọ, ẹnikẹ́ni tí mo bá sì wí fún ọ pé kò ní lọ, kò gbọdọ̀ lọ.” Gideoni bá kó àwọn eniyan náà lọ sí etí odò, OLUWA bá wí fún Gideoni pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ahọ́n lá omi gẹ́gẹ́ bí ajá, yọ ọ́ sọ́tọ̀ sí ẹ̀gbẹ́ kan, bákan náà ni kí o ṣe ẹnikẹ́ni tí ó bá kúnlẹ̀ kí ó tó mu omi. Àwọn tí wọ́n fi ọwọ́ bomi, tí wọ́n sì fi ahọ́n lá a bí ajá jẹ́ ọọdunrun (300), gbogbo àwọn yòókù ni wọ́n kúnlẹ̀ kí wọ́n tó mu omi. OLUWA bá wí fún Gideoni pé, “Àwọn ọọdunrun (300) tí wọ́n fi ahọ́n lá omi ni n óo lò láti gbà yín là, n óo sì fi àwọn ará Midiani lé ọ lọ́wọ́. Jẹ́ kí àwọn yòókù pada sí ilé wọn.” Gideoni bá gba oúnjẹ àwọn eniyan náà ati fèrè ogun wọn lọ́wọ́ wọn, ó sì sọ fún wọn pé kí wọ́n pada sí ilé, ṣugbọn ó dá àwọn ọọdunrun (300) náà dúró. Àgọ́ àwọn ọmọ ogun Midiani wà ní àfonífojì lápá ìsàlẹ̀ ibi tí wọ́n wà.

A. Oni 7:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ní òwúrọ̀ kùtùkùtù Jerubbaali (èyí ni Gideoni) pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ-ogun tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ kó ogun jọ lẹ́bàá a orísun Harodi. Àwọn ogun Midiani sì wà ní apá àríwá tí wọ́n ní àfonífojì tí ó wà ní ẹ̀bá òkè More. OLúWA wí fún Gideoni pé, “Àwọn ọmọ-ogun tí o kójọ sọ́dọ̀ ti pọ̀jù fún mi láti fi àwọn ogun Midiani lé wọn lọ́wọ́, kí Israẹli má ba à gbé ara rẹ̀ ga sí mi wí pé agbára òun ni ó gbà á là, sì kéde sí àwọn ènìyàn nísinsin yìí pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń gbọ̀n, tí ó sì ń bẹ̀rù lè padà sẹ́yìn, kí ó sì kúrò lórí òkè Gileadi.’ ” Báyìí ni Gideoni ṣe ya àwọn ènìyàn náà. Ẹgbẹ̀rúnméjìlélógún ọkùnrin sì padà sẹ́yìn àwọn ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá sì dúró. OLúWA sì tún sọ fún Gideoni pé, “Àwọn ènìyàn yìí sì tún pọ̀jù. Kó wọn lọ sí ibi tí omi wà, èmi yóò sì yọ̀rọ̀ wọn níbẹ̀ fún ọ. Bí mo bá wí pé eléyìí yóò bá ọ lọ yóò lọ, ṣùgbọ́n tí mo bá sọ pé, ‘Eléyìí kò ní bá ọ lọ,’ òun kò gbọdọ̀ lọ.” Gideoni sì kó àwọn ọkùnrin náà lọ sí ibi ìsun omi. Níbẹ̀ ni OLúWA ti wí fún un pé, “Kí ó pín àwọn ènìyàn náà sí ọ̀nà méjì. Ya àwọn tí ó fi ahọ́n wọn lá omi bí ajá kúrò lára àwọn tí ó kúnlẹ̀ láti mu omi pẹ̀lú ọwọ́ wọn.” Ọ̀ọ́dúnrún (300) ọkùnrin ni ó lá omi pẹ̀lú ahọ́n wọn. Gbogbo àwọn ìyókù ni ó kúnlẹ̀ láti mu mi. OLúWA wí fún Gideoni pé, “Àwọn ọ̀ọ́dúnrún (300) ọkùnrin tí ó lá omi ni èmi yóò lò láti gbà yín là àti láti fi ogun Midiani lé yín lọ́wọ́. Jẹ́ kí àwọn tókù padà sí ilé wọn.” Báyìí ni Gideoni ṣe dá àwọn Israẹli tí ó kù padà sí àgọ́ wọn, ṣùgbọ́n ó dá àwọn ọ̀ọ́dúnrún ọkùnrin náà dúró. Àwọn wọ̀nyí sì gba gbogbo ohun èlò àti fèrè àwọn tí ó ti padà. Ibùdó ogun àwọn Midiani wà ní àfonífojì ní ìsàlẹ̀. Ibi tí ó wà.