A. Oni 7:1-25
A. Oni 7:1-25 Bibeli Mimọ (YBCV)
NIGBANA ni Jerubbaali, ti iṣe Gideoni, ati gbogbo awọn enia ti o wà pẹlu rẹ̀, dide ni kùtukutu, nwọn si dó lẹba orisun Harodu: ibudó Midiani si wà ni ìha ariwa wọn, nibi òke More, li afonifoji. OLUWA si wi fun Gideoni pe, Awọn enia ti o wà lọdọ rẹ pọ̀ju fun mi lati fi awọn Midiani lé wọn lọwọ, ki Israeli ki o má ba gbé ara wọn ga si mi, pe, Ọwọ́ mi li o gbà mi là. Njẹ nitorina, lọ kede li etí awọn enia na, wipe, Ẹnikẹni ti o ba nfòya ti ẹ̀ru ba si mbà, ki o pada lati òke Gileadi ki o si lọ. Ẹgbã mọkanla si pada ninu awọn enia na; awọn ti o kù si jẹ́ ẹgba marun. OLUWA si wi fun Gideoni pe, Awọn enia na pọ̀ju sibẹ̀; mú wọn sọkalẹ wá si odò, nibẹ̀ li emi o gbé dan wọn wò fun ọ: yio si ṣe, ẹniti mo ba wi fun ọ pe, Eyi ni yio bá ọ lọ, on na ni yio bá ọ lọ; ẹnikẹni ti mo ba si wi fun ọ pe, Eyi ki yio bá ọ lọ, on na ni ki yio si bá ọ lọ. Bẹ̃li o mú awọn enia na wá si odò: OLUWA si wi fun Gideoni pe, Olukuluku ẹniti o ba fi ahọn rẹ̀ lá omi, bi ajá ti ma lá omi, on na ni ki iwọ ki o fi si apakan fun ara rẹ̀; bẹ̃ si li olukuluku ẹniti o kunlẹ li ẽkun rẹ̀ lati mu omi. Iye awọn ẹniti o lá omi, ti nwọn fi ọwọ́ wọn si ẹnu wọn, jẹ́ ọdunrun ọkunrin: ṣugbọn gbogbo awọn enia iyokù kunlẹ li ẽkun wọn lati mu omi. OLUWA si wi fun Gideoni pe, Nipaṣe ọdunrun ọkunrin wọnyi ti o lá omi li emi o gbà nyin, emi o si fi awọn Midiani lé ọ lọwọ: jẹ ki gbogbo awọn iyokù lọ olukuluku si ipò rẹ̀. Awọn enia na si mu onjẹ ati ipè li ọwọ́ wọn: on si rán gbogbo Israeli lọ, olukuluku sinu agọ́ rẹ̀, o si da ọdunrun ọkunrin nì duro: ibudó Midiani si wà nisalẹ rẹ̀ li afonifoji. O si ṣe li oru na, ni OLUWA wi fun u pe, Dide, sọkalẹ lọ si ibudó; nitoriti mo ti fi i lé ọ lọwọ. Ṣugbọn bi iwọ ba mbẹ̀ru lati sọkalẹ lọ, ki iwọ ati Pura iranṣẹ rẹ sọkalẹ lọ si ibudo: Iwọ o si gbọ́ ohun ti nwọn nwi; lẹhin eyi ni ọwọ́ rẹ yio lí agbara lati sọkalẹ lọ si ibudó. Nigbana ni ti on ti Pura iranṣẹ rẹ̀ sọkalẹ lọ si ìha opin awọn ti o hamora, ti o wà ni ibudó. Awọn Midiani ati awọn Amaleki, ati gbogbo awọn ọmọ ìha ìla-õrùn tò lọ titi li afonifoji gẹgẹ bi eṣú li ọ̀pọlọpọ; ibakasiẹ wọn kò si ní iye, bi iyanrin ti mbẹ leti okun li ọ̀pọlọpọ. Nigbati Gideoni si dé, kiyesi i, ọkunrin kan nrọ́ alá fun ẹnikeji rẹ̀, o si wipe, Kiyesi i, emi lá alá kan, si wò o, àkara ọkà-barle kan ṣubu si ibudó Midiani, o si bọ́ sinu agọ́ kan, o si kọlù u tobẹ̃ ti o fi ṣubu, o si doju rẹ̀ de, agọ́ na si ṣubu. Ekeji rẹ̀ si da a lohùn, wipe, Eyiyi ki iṣe ohun miran bikoṣe idà Gideoni ọmọ Joaṣi, ọkunrin kan ni Israeli: nitoripe Ọlọrun ti fi Midiani ati gbogbo ibudo lé e lọwọ. O si ṣe, nigbati Gideoni gbọ́ rirọ́ alá na, ati itumọ̀ rẹ̀, o tẹriba; o si pada si ibudó Israeli, o si wipe, Ẹ dide; nitoriti OLUWA ti fi ogun Midiani lé nyin lọwọ. On si pín ọdunrun ọkunrin na si ẹgbẹ mẹta, o si fi ipè lé olukuluku wọn lọwọ, pẹlu ìṣa ofo, òtufu si wà ninu awọn ìṣa na. On si wi fun wọn pe, Ẹ wò mi, ki ẹnyin ki o si ṣe bẹ̃ gẹgẹ: si kiyesi i, nigbati mo ba dé opin ibudó na, yio si ṣe bi emi ba ti ṣe, bẹ̃ni ki ẹnyin ki o ṣe. Nigbati mo ba fun ìpe, emi ati gbogbo awọn ti mbẹ lọdọ mi, nigbana ni ki ẹnyin pẹlu ki o fun ìpe yiká gbogbo ibudó na, ki ẹnyin ki o si wi pe, Fun OLUWA, ati fun Gideoni. Bẹ̃ni Gideoni, ati ọgọrun ọkunrin ti mbẹ lọdọ rẹ̀, wá si opin ibudó, ni ibẹ̀rẹ iṣọ́ ãrin, nigbati nwọn ṣẹṣẹ yàn iṣọ́ sode: nwọn fun ipè, nwọn si fọ́ ìṣa ti o wà li ọwọ́ wọn. Ẹgbẹ mẹtẹta na si fun ipè wọn, nwọn si fọ́ ìṣa wọn, nwọn si mú awọn òtufu li ọwọ́ òsi wọn, ati ipè li ọwọ́ ọtún lati fun: nwọn si kigbe li ohùn rara pe, Idà OLUWA, ati ti Gideoni. Olukuluku ọkunrin si duro ni ipò rẹ̀ yi ibudó na ká: gbogbo ogun na si sure, nwọn si kigbe, nwọn si sá. Awọn ọkunrin na fun ọdunrun ipè, OLUWA si yí idà olukuluku si ẹnikeji rẹ̀, ati si gbogbo ogun na: ogun na si sá titi dé Beti-ṣita ni ìha Serera, dé àgbegbe Abeli-mehola, leti Tabati. Awọn ọkunrin Israeli si kó ara wọn jọ lati Naftali, ati lati Aṣeri ati lati gbogbo Manasse wá, nwọn si lepa awọn Midiani. Gideoni si rán onṣẹ lọ si gbogbo òke Efraimu, wipe, Ẹ sọkalẹ wá pade awọn Midiani, ki ẹ si tète gbà omi wọnni dé Beti-bara ani Jordani. Nigbana ni gbogbo awọn ọkunrin Efraimu kó ara wọn jọ, nwọn si gbà omi wọnni, titi dé Beti-bara ani Jordani. Nwọn si mú meji ninu awọn ọmọ-alade Midiani, Orebu ati Seebu; Orebu ni nwọn si pa lori apata Orebu, ati Seebu ni nwọn si pa ni ibi-ifọnti Seebu, nwọn si lepa awọn ara Midiani, nwọn si mú ori Orebu ati Seebu wá fi fun Gideoni li apa keji odò Jordani.
A. Oni 7:1-25 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí ó yá, Gideoni, tí àdàpè rẹ̀ ń jẹ́ Jerubaali, ati àwọn eniyan tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀ gbéra ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ kan, wọ́n lọ pàgọ́ sí ẹ̀gbẹ́ odò Harodu. Àgọ́ ti àwọn ará Midiani wà ní apá ìhà àríwá wọn ní àfonífojì lẹ́bàá òkè More. OLUWA wí fún Gideoni pé, “Àwọn tí wọ́n wà pẹlu rẹ ti pọ̀jù fún mi, láti fi àwọn ará ilẹ̀ Midiani lé lọ́wọ́, kí àwọn ọmọ Israẹli má baà gbéraga pé agbára wọn ni wọ́n fi ṣẹgun, wọn kò sì ní fi ògo fún mi. Nítorí náà, kéde fún gbogbo wọn pé, kí ẹnikẹ́ni tí ẹ̀rù bá ń bà pada sí ilé.” Gideoni bá dán wọn wò lóòótọ́, ọ̀kẹ́ kan ati ẹgbaa (22,000) ọkunrin ninu wọn sì pada sí ilé. Àwọn tí wọ́n kù jẹ́ ẹgbaarun (10,000). OLUWA tún wí fún Gideoni pé, “Àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù yìí pọ̀jù sibẹsibẹ. Kó wọn lọ sí etí odò, n óo sì bá ọ dán wọn wò níbẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí mo bá wí fún ọ pé yóo lọ, òun ni yóo lọ, ẹnikẹ́ni tí mo bá sì wí fún ọ pé kò ní lọ, kò gbọdọ̀ lọ.” Gideoni bá kó àwọn eniyan náà lọ sí etí odò, OLUWA bá wí fún Gideoni pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ahọ́n lá omi gẹ́gẹ́ bí ajá, yọ ọ́ sọ́tọ̀ sí ẹ̀gbẹ́ kan, bákan náà ni kí o ṣe ẹnikẹ́ni tí ó bá kúnlẹ̀ kí ó tó mu omi. Àwọn tí wọ́n fi ọwọ́ bomi, tí wọ́n sì fi ahọ́n lá a bí ajá jẹ́ ọọdunrun (300), gbogbo àwọn yòókù ni wọ́n kúnlẹ̀ kí wọ́n tó mu omi. OLUWA bá wí fún Gideoni pé, “Àwọn ọọdunrun (300) tí wọ́n fi ahọ́n lá omi ni n óo lò láti gbà yín là, n óo sì fi àwọn ará Midiani lé ọ lọ́wọ́. Jẹ́ kí àwọn yòókù pada sí ilé wọn.” Gideoni bá gba oúnjẹ àwọn eniyan náà ati fèrè ogun wọn lọ́wọ́ wọn, ó sì sọ fún wọn pé kí wọ́n pada sí ilé, ṣugbọn ó dá àwọn ọọdunrun (300) náà dúró. Àgọ́ àwọn ọmọ ogun Midiani wà ní àfonífojì lápá ìsàlẹ̀ ibi tí wọ́n wà. OLUWA sọ fún un ní òru ọjọ́ kan náà pé, “Gbéra, lọ gbógun ti àgọ́ náà, nítorí pé mo ti fi lé ọ lọ́wọ́. Ṣugbọn bí ẹ̀rù bá ń bà ọ láti lọ, mú Pura iranṣẹ rẹ, kí ẹ jọ lọ sí ibi àgọ́ náà. O óo gbọ́ ohun tí wọ́n ń sọ, lẹ́yìn náà, o óo ní agbára láti lè gbógun ti àgọ́ náà.” Gideoni bà mú Pura, iranṣẹ rẹ̀, wọ́n jọ lọ sí ìpẹ̀kun ibi tí àwọn tí wọ́n di ihamọra ogun ninu àgọ́ wọn wà. Àwọn ará ilẹ̀ Midiani ati ti Amaleki ati àwọn ará ilẹ̀ tí ó wà ní ìlà oòrùn pọ̀ nílẹ̀ lọ bí eṣú àwọn ràkúnmí wọn kò níye, wọ́n pọ̀ bí iyanrìn etí òkun. Nígbà tí Gideoni dé ibẹ̀, ó gbọ́ tí ẹnìkan ń rọ́ àlá tí ó lá fún ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kan pé, “Mo lá àlá kan, mo rí i tí àkàrà ọkà baali kan ré bọ́ sinu ibùdó àwọn ará Midiani. Bí ó ti bọ́ lu àgọ́ náà, ó wó o lulẹ̀, ó sì dojú rẹ̀ délẹ̀, àgọ́ náà sì tẹ́ sílẹ̀ pẹrẹsẹ.” Ẹnìkejì rẹ̀ dá a lóhùn, ó ní, “Èyí kì í ṣe ohun mìíràn, bíkòṣe idà Gideoni, ọmọ Joaṣi, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Israẹli. Ọlọrun ti fi Midiani ati gbogbo ọmọ ogun rẹ̀ lé e lọ́wọ́.” Nígbà tí Gideoni gbọ́ bí ó ti rọ́ àlá yìí, ati ìtumọ̀ rẹ̀, ó yin OLUWA. Ó pada sí ibùdó Israẹli, ó ní, “Ẹ dìde, nítorí OLUWA ti fi àwọn ọmọ ogun Midiani le yín lọ́wọ́.” Ó pín àwọn ọọdunrun (300) náà sí ọ̀nà mẹta, ó fi fèrè ogun ati ìkòkò òfìfo tí wọn fi ògùṣọ̀ sí ninu lé ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn lọ́wọ́. Ó wí fún wọn pé, “Ẹ máa wò mí, kí ẹ sì máa ṣe bí mo bá ti ń ṣe. Nígbà tí mo bá dé ìkangun àgọ́ náà, ẹ ṣe bí mo bá ti ṣe. Nígbà tí èmi ati àwọn tí wọ́n wà lọ́dọ̀ mi bá fọn fèrè, ẹ̀yin náà ẹ fọn fèrè tiyín ní gbogbo àyíká àgọ́ náà, ẹ óo sì pariwo pé, ‘Fún OLUWA, ati fún Gideoni.’ ” Gideoni ati ọgọrun-un eniyan tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ bá lọ sí ìkangun àgọ́ náà ní òru, nígbà tí àwọn olùṣọ́ mìíràn ṣẹ̀ṣẹ̀ gba ipò àwọn tí wọ́n wà níbẹ̀ tẹ́lẹ̀. Wọ́n fọn fèrè, wọ́n sì fọ́ àwọn ìkòkò tí ó wà lọ́wọ́ wọn mọ́lẹ̀. Àwọn ẹgbẹ́ mẹtẹẹta fọn fèrè wọn, wọ́n sì fọ́ ìkòkò tì ó wà lọ́wọ́ wọn. Wọ́n fi iná ògùṣọ̀ wọn sí ọwọ́ òsì, wọ́n sì fi fèrè tí wọn ń fọn sí ọwọ́ ọ̀tún, wọ́n bá pariwo pé, “Idà kan fún OLUWA ati fún Gideoni.” Olukuluku wọn dúró sí ààyè wọn yípo àgọ́ náà, gbogbo àwọn ọmọ ogun Midiani bá bẹ̀rẹ̀ sí sá káàkiri, wọ́n ń kígbe, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ. Nígbà tí àwọn ọmọ ogun Gideoni fọn ọọdunrun (300) fèrè wọn, Ọlọrun mú kí àwọn ọmọ ogun ọ̀tá wọn dojú ìjà kọ ara wọn, gbogbo wọn bá bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ sí apá Serera. Wọ́n sá títí dé Beti Ṣita, ati títí dé ààlà Abeli Mehola, lẹ́bàá Tabati. Àwọn ọmọ ogun Israẹli pe àwọn ọkunrin Israẹli jáde láti inú ẹ̀yà Nafutali, ati ti Aṣeri ati ti Manase, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí lé àwọn ará Midiani lọ. Gideoni rán àwọn oníṣẹ́ jákèjádò agbègbè olókè Efuraimu, ó ní, “Ẹ máa bọ̀ wá bá àwọn ará Midiani jagun, kí ẹ sì gba ojú odò lọ́wọ́ wọn títí dé Bẹtibara ati odò Jọdani.” Wọ́n pe gbogbo àwọn ọkunrin Efuraimu jáde, wọ́n sì gba gbogbo odò títí dé Bẹtibara ati odò Jọdani pẹlu. Wọ́n mú Orebu ati Seebu, àwọn ọmọ ọba Midiani mejeeji, wọ́n pa Orebu sí ibi òkúta Orebu, wọ́n sì pa Seebu níbi ìfúntí Seebu, bí wọ́n ti ń lé àwọn ará Midiani lọ. Wọ́n gé orí Orebu ati ti Seebu, wọ́n sì gbé wọn wá sí ọ̀dọ̀ Gideoni ní òdìkejì odò Jọdani.
A. Oni 7:1-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní òwúrọ̀ kùtùkùtù Jerubbaali (èyí ni Gideoni) pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ-ogun tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ kó ogun jọ lẹ́bàá a orísun Harodi. Àwọn ogun Midiani sì wà ní apá àríwá tí wọ́n ní àfonífojì tí ó wà ní ẹ̀bá òkè More. OLúWA wí fún Gideoni pé, “Àwọn ọmọ-ogun tí o kójọ sọ́dọ̀ ti pọ̀jù fún mi láti fi àwọn ogun Midiani lé wọn lọ́wọ́, kí Israẹli má ba à gbé ara rẹ̀ ga sí mi wí pé agbára òun ni ó gbà á là, sì kéde sí àwọn ènìyàn nísinsin yìí pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń gbọ̀n, tí ó sì ń bẹ̀rù lè padà sẹ́yìn, kí ó sì kúrò lórí òkè Gileadi.’ ” Báyìí ni Gideoni ṣe ya àwọn ènìyàn náà. Ẹgbẹ̀rúnméjìlélógún ọkùnrin sì padà sẹ́yìn àwọn ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá sì dúró. OLúWA sì tún sọ fún Gideoni pé, “Àwọn ènìyàn yìí sì tún pọ̀jù. Kó wọn lọ sí ibi tí omi wà, èmi yóò sì yọ̀rọ̀ wọn níbẹ̀ fún ọ. Bí mo bá wí pé eléyìí yóò bá ọ lọ yóò lọ, ṣùgbọ́n tí mo bá sọ pé, ‘Eléyìí kò ní bá ọ lọ,’ òun kò gbọdọ̀ lọ.” Gideoni sì kó àwọn ọkùnrin náà lọ sí ibi ìsun omi. Níbẹ̀ ni OLúWA ti wí fún un pé, “Kí ó pín àwọn ènìyàn náà sí ọ̀nà méjì. Ya àwọn tí ó fi ahọ́n wọn lá omi bí ajá kúrò lára àwọn tí ó kúnlẹ̀ láti mu omi pẹ̀lú ọwọ́ wọn.” Ọ̀ọ́dúnrún (300) ọkùnrin ni ó lá omi pẹ̀lú ahọ́n wọn. Gbogbo àwọn ìyókù ni ó kúnlẹ̀ láti mu mi. OLúWA wí fún Gideoni pé, “Àwọn ọ̀ọ́dúnrún (300) ọkùnrin tí ó lá omi ni èmi yóò lò láti gbà yín là àti láti fi ogun Midiani lé yín lọ́wọ́. Jẹ́ kí àwọn tókù padà sí ilé wọn.” Báyìí ni Gideoni ṣe dá àwọn Israẹli tí ó kù padà sí àgọ́ wọn, ṣùgbọ́n ó dá àwọn ọ̀ọ́dúnrún ọkùnrin náà dúró. Àwọn wọ̀nyí sì gba gbogbo ohun èlò àti fèrè àwọn tí ó ti padà. Ibùdó ogun àwọn Midiani wà ní àfonífojì ní ìsàlẹ̀. Ibi tí ó wà. Ní òru ọjọ́ náà OLúWA sọ fún Gideoni pé, “Dìde, dojú ogun kọ ibùdó ogun àwọn ará Midiani nítorí èmi yóò fi lé ọ lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n bí ẹ̀rù àti kọlù wọ́n bá ń bà ọ́, yọ́ wọ ibùdó wọn lọ kí o mú Pura ìránṣẹ́ rẹ lọ́wọ́ kí o sì fi ara balẹ̀ gbọ́ ohun tí wọ́n ń sọ nínú ibùdó náà. Lẹ́yìn èyí ọkàn rẹ̀ yóò le láti kọlù ibùdó náà.” Báyìí ni òun àti Pura ìránṣẹ́ rẹ̀ wọ ẹnu-ọ̀nà ibùdó yìí. Àwọn ará Midiani, àwọn ará Amaleki àti gbogbo ènìyàn ìlà-oòrùn tó lọ ní àfonífojì bí eṣú ni wọ́n rí nítorí púpọ̀ wọn. Àwọn ìbákasẹ wọn kò sì lóǹkà, wọ́n sì pọ̀ bí yanrìn inú Òkun. Gideoni dé sí àsìkò tí ọkùnrin kan bẹ̀rẹ̀ sí í rọ́ àlá tí ó lá sí ọ̀kan nínú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Ó ní, “Mo lá àlá kan, nínú àlá náà mo rí àkàrà kan tó ṣe róbótó tí a fi barle ṣe ń yí wọ inú ibùdó àwọn ará Midiani, ó sì kọlu àgọ́ pẹ̀lú agbára ńlá dé bi wí pé àgọ́ náà dojúdé, ó sì ṣubú.” Ọ̀rẹ́ rẹ̀ dá a lóhùn pé, “Èyí kò le túmọ̀ sí ohun mìíràn ju idà Gideoni ọmọ Joaṣi ará Israẹli lọ: Ọlọ́run ti fi àwọn ará Midiani àti gbogbo ogun ibùdó lé e lọ́wọ́.” Nígbà tí Gideoni gbọ́ àlá náà àti ìtumọ̀ rẹ̀, ó wólẹ̀ sin Ọlọ́run: lẹ́yìn náà ni ó padà sí ibùdó àwọn ọmọ Israẹli ó sì pè wọ́n pé, “Ẹ dìde! Nítorí pé Ọlọ́run yóò lò yín láti ṣẹ́gun gbogbo ogun Midiani.” Nígbà tí ó ti pín àwọn ọ̀ọ́dúnrún ọkùnrin wọ̀n-ọn-nì sí ọ̀nà mẹ́ta, ó fi fèrè, pẹ̀lú àwọn òfìfo ìkòkò lé ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn lọ́wọ́, iná sì wà nínú àwọn ìkòkò náà. Ó sọ fún wọn pé, “Ẹ máa wò mí, kí ẹ sì máa ṣe ohun tí mo bá ṣe. Nígbà tí mo bá dé igun ibùdó wọn ẹ ṣe ohun tí mo bá ṣe. Nígbà tí èmi àti àwọn ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú mi bá fun fèrè wa, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin náà ni gbogbo igun ibùdó tí ẹ̀ bá wà kí ẹ fun àwọn fèrè yín kí ẹ sì hó pé, ‘Fún Ọlọ́run àti fún Gideoni.’ ” Gideoni àti àwọn ọgọ́rùn-ún ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ dé òpin ibùdó àwọn ará Midiani ní nǹkan bí agogo méjìlá padà. Wọ́n fun fèrè wọn, wọ́n sì tún fọ́ àwọn ìkòkò tí ó wà ní ọwọ́ mọ́lẹ̀. Àwọn ẹgbẹ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta fun fèrè wọn, wọ́n tún fọ́ àwọn ìkòkò wọn mọ́lẹ̀. Wọ́n mú àwọn fìtílà iná wọn ní ọwọ́ òsì wọn àti fèrè tí wọ́n ń fun ní ọwọ́ ọ̀tún wọn. Wọ́n pariwo hé è pé, “Idà kan fún OLúWA àti fún Gideoni!” Nígbà tí ọkùnrin kọ̀ọ̀kan dúró ní ipò rẹ̀ yí ibùdó àwọn Midiani ká, gbogbo àwọn ọmọ-ogun Midiani ń sá káàkiri, wọ́n ń pariwo bí wọ́n ṣe ń sálọ. Nígbà tí àwọn ọ̀ọ́dúnrún (300) ọkùnrin wọ̀n-ọn-nì fun fèrè wọn, OLúWA sì yí ojú idà ọkùnrin kọ̀ọ̀kan padà sí ẹnìkejì rẹ̀ àti sí gbogbo ogun wọn. Àwọn ọmọ-ogun sì sá títí dé Beti-Sitta ní ọ̀nà Serera títí lọ dé ìpínlẹ̀ Abeli-Mehola ní ẹ̀bá Tabbati. Gbogbo àwọn ọmọ-ogun Israẹli láti ẹ̀yà Naftali, Aṣeri àti gbogbo Manase ni Gideoni ránṣẹ́ si, wọ́n wá wọ́n sì lé àwọn ará Midiani. Gideoni tún ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn ìlú tí ó wà ní orí òkè Efraimu wí pé, “Ẹ jáde wá bá àwọn ará Midiani jà, kí ẹ tètè gba àwọn omi Jordani títí dé Beti-Bara kí wọ́n tó dé bẹ̀.” Báyìí ni a ṣe pe gbogbo ọkùnrin ológun Efraimu jáde tí wọ́n sì gba gbogbo àwọn à bá wọ odò Jordani títí dé Beti-Bara. Wọ́n mú méjì nínú àwọn olórí àwọn ará Midiani, àwọn náà ni Orebu àti Seebu. Wọ́n pa Horebu nínú àpáta Orebu, wọ́n sì pa Seebu níbi tí àwọn ènìyàn ti mọ̀ fún wáìnì tí a ń pè ní ìfúntí Seebu. Wọ́n lé àwọn ará Midiani, nígbà tí wọ́n gbé orí Orebu àti Seebu tọ Gideoni wá ẹni tí ó wà ní apá kejì Jordani.