A. Oni 6:25-27
A. Oni 6:25-27 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si ṣe li oru ọjọ́ kanna, li OLUWA wi fun u pe, Mú akọ-malu baba rẹ, ani akọ-malu keji ọlọdún meje, ki o si wó pẹpẹ Baali ti baba rẹ ní lulẹ ki o si bẹ́ igi-oriṣa ti o wà lẹba rẹ̀ lulẹ: Ki o si mọ pẹpẹ kan fun OLUWA Ọlọrun rẹ lori ibi agbara yi, bi o ti yẹ, ki o si mú akọ-malu keji, ki o si fi igi-oriṣa ti iwọ bẹ́ lulẹ ru ẹbọ sisun. Nigbana ni Gideoni mú ọkunrin mẹwa ninu awọn iranṣẹ rẹ̀, o si ṣe bi OLUWA ti sọ fun u: o si ṣe, nitoripe o bẹ̀ru ile baba rẹ̀ ati awọn ọkunrin ilu na, tobẹ̃ ti kò fi le ṣe e li ọsán, ti o si fi ṣe e li oru.
A. Oni 6:25-27 Yoruba Bible (YCE)
Ní òru ọjọ́ náà, OLUWA sọ fún Gideoni pé, “Mú akọ mààlúù baba rẹ ati akọ mààlúù mìíràn tí ó jẹ́ ọlọ́dún meje, wó pẹpẹ oriṣa Baali baba rẹ lulẹ̀, kí o sì gé ère oriṣa Aṣera tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Kí o wá tẹ́ pẹpẹ kan fún èmi OLUWA Ọlọrun rẹ lórí òkítì ibi gegele náà. To àwọn òkúta rẹ̀ lérí ara wọn dáradára, lẹ́yìn náà mú akọ mààlúù keji kí o sì fi rú ẹbọ sísun. Igi ère oriṣa Aṣera tí o bá gé lulẹ̀ ni kí o fi ṣe igi ẹbọ sísun náà.” Gideoni mú mẹ́wàá ninu àwọn iranṣẹ rẹ̀, ó sì ṣe bí OLUWA ti ní kí ó ṣe, ṣugbọn kò lè ṣe é lọ́sàn-án, nítorí ẹ̀rù àwọn ará ilé ati àwọn ará ìlú rẹ̀ ń bà á, nítorí náà lóru ni ó ṣe é.
A. Oni 6:25-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní òru ọjọ́ náà OLúWA wí fún un pé, mú akọ màlúù baba rẹ, àní akọ màlúù kejì ọlọ́dún méje. Wó pẹpẹ Baali baba rẹ lulẹ̀, kí o sì bẹ́ igi ère òrìṣà Aṣerah tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ lulẹ̀. Lẹ́yìn èyí kí o wá mọ pẹpẹ èyí tí ó yẹ fún OLúWA Ọlọ́run rẹ lórí òkè yìí. Kí o sì mú akọ màlúù kejì, kí o sì mú igi ère òrìṣà Aṣerah tí ìwọ bẹ́ lulẹ̀ rú ẹbọ sísun sí OLúWA. Gideoni mú mẹ́wàá nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì ṣe bí OLúWA ti pàṣẹ fún un ṣùgbọ́n, nítorí ó bẹ̀rù àwọn ará ilé baba rẹ̀ àti àwọn ènìyàn ìlú náà kò ṣe é ní ọ̀sán, òru ni ó ṣe.