A. Oni 6:11-16
A. Oni 6:11-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
Angeli OLUWA kan si wá, o si joko labẹ igi-oaku kan ti o wà ni Ofra, ti iṣe ti Joaṣi ọmọ Abieseri: Gideoni ọmọ rẹ̀ si npakà nibi ifọnti, lati fi i pamọ́ kuro loju awọn Midiani. Angeli OLUWA na si farahàn a, o si wi fun u pe, OLUWA wà pẹlu rẹ, iwọ ọkunrin alagbara. Gideoni si wi fun u pe, Yẽ oluwa mi, ibaṣepe OLUWA wà pẹlu wa, njẹ ẽṣe ti gbogbo eyi fi bá wa? nibo ni gbogbo iṣẹ-iyanu rẹ̀ ti awọn baba wa ti sọ fun wa gbé wà, wipe, OLUWA kò ha mú wa gòke lati Egipti wá? ṣugbọn nisisiyi OLUWA ti kọ̀ wa silẹ, o si ti fi wa lé Midiani lọwọ. OLUWA si wò o, o si wipe, Lọ ninu agbara rẹ yi, ki iwọ ki ó si gbà Israeli là kuro lọwọ Midiani: Emi kọ ha rán ọ bi? O si wi fun u pe, Yẽ oluwa mi, ọ̀na wo li emi o fi gbà Israeli là? kiyesi i, talakà ni idile mi ni Manasse, emi li o si jẹ́ ẹni ikẹhin ni ile baba mi. OLUWA si wi fun u pe, Nitõtọ emi o wà pẹlu rẹ, iwọ o si kọlù awọn Midiani bi ọkunrin kan.
A. Oni 6:11-16 Yoruba Bible (YCE)
Angẹli OLUWA kan wá, ó jókòó lábẹ́ igi Oaku tí ó wà ní Ofira, igi Oaku yìí jẹ́ ti Joaṣi, ará Abieseri. Bí Gideoni ọmọ Joaṣi, ti ń pa ọkà ní ibi tí wọ́n ti ń pọn ọtí, tí ó ń fi í pamọ́ fún àwọn ará Midiani, ni angẹli OLUWA náà yọ sí i, ó sì wí fún un pé, “OLUWA wà pẹlu rẹ, ìwọ akikanju ati alágbára ọkunrin.” Gideoni dá a lóhùn, ó ní “Jọ̀wọ́, oluwa mi, bí OLUWA bá wà pẹlu wa, kí ló dé tí gbogbo nǹkan wọnyi fi ń ṣẹlẹ̀ sí wa? Níbo sì ni gbogbo àwọn iṣẹ́ ìyanu OLUWA wà, tí àwọn baba wa máa ń sọ fún wa nípa rẹ̀, pé, ‘Ṣebí OLUWA ni ó kó wa jáde láti ilẹ̀ Ijipti?’ Ṣugbọn nisinsinyii OLUWA ti kọ̀ wá sílẹ̀, ó sì ti fi wá lé àwọn ará Midiani lọ́wọ́.” Ṣugbọn OLUWA yipada sí i, ó sì dá a lóhùn pé, “Lọ pẹlu agbára rẹ yìí, kí o sì gba Israẹli kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Midiani, ṣebí èmi ni mo rán ọ.” Gideoni dáhùn, ó ní, “Sọ fún mi OLUWA, báwo ni mo ṣe lè gba Israẹli sílẹ̀? Ìran mi ni ó rẹ̀yìn jùlọ ninu ẹ̀yà Manase, èmi ni mo sì kéré jù ní ìdílé wa.” OLUWA dá a lóhùn, ó ní, “N óo wà pẹlu rẹ, o óo sì run àwọn ará Midiani bí ẹni pé, ẹyọ ẹnìkan péré ni wọ́n.”
A. Oni 6:11-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ọjọ́ kan angẹli OLúWA wá, ó sì jókòó ní abẹ́ igi óákù ofira èyí ti ṣe ti Joaṣi ará Abieseri, níbi tí Gideoni ọmọ rẹ̀ ti ń lu ọkà jéró, níbi ìpọntí wáìnì láti fi pamọ́ kúrò níwájú àwọn ará Midiani. Nígbà tí angẹli OLúWA fi ara han Gideoni, ó wí fún un pé, “OLúWA wà pẹ̀lú rẹ, akọni ológun.” Gideoni dáhùn pé, “Alàgbà, bí OLúWA bá wà pẹ̀lú wa, kí ló dé tí gbogbo ìwọ̀nyí fi ń ṣẹlẹ̀ sí wa? Níbi gbogbo àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ tí àwọn baba wa ròyìn rẹ̀ fún wa nígbà tí wọ́n wí pé, ‘OLúWA kò ha mú wa gòkè láti ilẹ̀ Ejibiti wá?’ Ṣùgbọ́n nísinsin yìí OLúWA ti kọ̀ wá sílẹ̀, ó sì ti fi wá lé àwọn ará Midiani lọ́wọ́.” OLúWA sì yípadà sí i, ó sì wí fún un pé, “Lọ nínú agbára tí o ní yìí, kí o sì gba àwọn ará Israẹli sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Midiani. Èmi ni ó ń rán ọ lọ.” Gideoni sì dáhùn pé, “Yéè olúwa mi, ọ̀nà wo ni èmi yóò fi gba Israẹli là? Ìdílé mi ni ó jẹ́ aláìlera jù ní Manase, àti pé èmi ni ó sì kéré jù ní ìdílé baba mi.” OLúWA sì dáhùn pé, “Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ, ìwọ yóò sì pa gbogbo àwọn ará Midiani láì ku ẹnìkankan.”