A. Oni 6:1-7

A. Oni 6:1-7 Yoruba Bible (YCE)

Àwọn ọmọ Israẹli tún ṣe nǹkan tí ó burú lójú OLUWA, OLUWA sì fi wọ́n lé àwọn ará Midiani lọ́wọ́ fún ọdún meje. Àwọn ará Midiani lágbára ju àwọn ọmọ Israẹli lọ tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn ọmọ Israẹli fi ṣe ibi tí wọn ń sápamọ́ sí lórí àwọn òkè, ninu ihò àpáta, ati ibi ààbò mìíràn ninu òkè. Nítorí pé, nígbàkúùgbà tí àwọn ọmọ Israẹli bá gbin ohun ọ̀gbìn wọn, àwọn ará Midiani ati àwọn ará Amaleki ati àwọn kan láti inú aṣálẹ̀ tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn, a máa kó ara wọn jọ, wọn a lọ ṣígun bá àwọn ọmọ Israẹli. Wọn a gbógun tì wọ́n, wọn a sì ba gbogbo ohun ọ̀gbìn ilẹ̀ náà jẹ́ títí dé agbègbè Gasa. Wọn kì í fi oúnjẹ kankan sílẹ̀ rárá ní ilẹ̀ Israẹli, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í fi aguntan tabi mààlúù tabi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kankan sílẹ̀. Nítorí pé, nígbà tí wọ́n bá ń bọ̀, tilé-tilé ni wọ́n wá. Wọn á kó àwọn àgọ́ wọn ati àwọn ẹran ọ̀sìn wọn lọ́wọ́, wọn á sì bo àwọn ọmọ Israẹli bí eṣú. Àwọn ati ràkúnmí wọn kò níye, nítorí náà nígbà tí wọ́n bá dé, wọn á jẹ gbogbo ilẹ̀ náà ní àjẹrun. Àwọn ọmọ Israẹli di ẹni ilẹ̀ patapata, nítorí àwọn ará Midiani. Nítorí náà, wọ́n ké pe OLUWA fún ìrànlọ́wọ́. Nígbà tí wọ́n ké pe OLUWA, nítorí ìyọnu àwọn ará Midiani

A. Oni 6:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Àwọn ọmọ Israẹli sì túnṣe ohun tí ó burú ní ojú OLúWA, Ó sì fi wọ́n lé àwọn ará Midiani lọ́wọ́ fún ọdún méje. Agbára àwọn ará Midiani sì pọ̀ púpọ̀ lórí àwọn Israẹli, wọ́n sì hùwà ipá sí wọn, nítorí ìdí èyí, àwọn Israẹli sálọ sí àwọn orí òkè, wọ́n sì kọ́ àgọ́ fún ara wọn nínú ihò àpáta, àti nínú ọ̀gbun àti ní ibi agbára nínú àpáta. Ní ìgbàkúgbà tí àwọn ọmọ Israẹli bá ti gbin ọ̀gbìn wọn, àwọn ará Midiani, àwọn ará Amaleki àti àwọn ará ìlà-oòrùn mìíràn yóò wá láti bá wọn jà. Wọn yóò tẹ̀dó sí orí ilẹ̀ náà, wọn a sì bá irúgbìn wọ̀nyí jẹ́ títí dé Gasa, wọn kì í sì í fi ohun alààyè kankan sílẹ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli, kì bá à ṣe àgùntàn, màlúù tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Wọn a máa wá pẹ̀lú ohun ọ̀sìn wọn àti àwọn àgọ́ wọn, wọn a sì dàbí eṣú nítorí i púpọ̀ wọn. Ènìyàn kò sì lè ka iye àwọn ènìyàn náà bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìbákasẹ, wọ́n pọ̀ dé bi pé wọn kò ṣe é kà ní iye, wọn a bo ilẹ̀ náà wọn a sì jẹ ẹ́ run. Àwọn ará Midiani sì pọ́n àwọn ọmọ Israẹli lójú, wọ́n sọ wọ́n di òtòṣì àti aláìní, fún ìdí èyí wọ́n ké pe OLúWA nínú àdúrà fún ìrànlọ́wọ́. Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli ké pe OLúWA nítorí àwọn ará Midiani.