A. Oni 6:1-40

A. Oni 6:1-40 Bibeli Mimọ (YBCV)

AWỌN ọmọ Israeli si ṣe buburu loju OLUWA: OLUWA si fi wọn lé Midiani lọwọ li ọdún meje. Ọwọ́ Midiani si le si Israeli: ati nitori Midiani awọn ọmọ Israeli wà ihò wọnni fun ara wọn, ti o wà ninu òke, ati ninu ọgbun, ati ni ibi-agbara wọnni. O si ṣe, bi Israeli ba gbìn irugbìn, awọn Midiani a si gòke wá, ati awọn Amaleki, ati awọn ọmọ ìha ìla-õrùn; nwọn a si gòke tọ̀ wọn wá; Nwọn a si dótì wọn, nwọn a si run eso ilẹ na, titi iwọ o fi dé Gasa, nwọn ki isi fi onjẹ silẹ ni Israeli, tabi agutan, tabi akọ-malu, tabi kẹtẹkẹtẹ. Nitoriti nwọn gòke wá ti awọn ti ohunọ̀sin wọn ati agọ́ wọn, nwọn si wá bi eṣú li ọ̀pọlọpọ; awọn ati awọn ibakasiẹ wọn jẹ́ ainiye: nwọn si wọ̀ inu ilẹ na lati jẹ ẹ run. Oju si pọ́n Israeli gidigidi nitori awọn Midiani; awọn ọmọ Israeli si kigbepè OLUWA. O si ṣe, nigbati awọn ọmọ Israeli kigbepè OLUWA nitori awọn Midiani, OLUWA si rán wolĩ kan si awọn ọmọ Israeli: ẹniti o wi fun wọn pe, Bayi li OLUWA, Ọlọrun Israeli wi, Emi mú nyin gòke ti Egipti wá, mo si mú nyin jade kuro li oko-ẹrú; Emi si gbà nyin li ọwọ́ awọn ara Egipti, ati li ọwọ́ gbogbo awọn ti npọ́n nyin loju, mo si lé wọn kuro niwaju nyin, mo si fi ilẹ wọn fun nyin; Mo si wi fun nyin pe, Emi li OLUWA Ọlọrun nyin; ẹ máṣe bẹ̀ru oriṣa awọn Amori, ilẹ ẹniti ẹnyin ngbé: ṣugbọn ẹnyin kò gbà ohùn mi gbọ́. Angeli OLUWA kan si wá, o si joko labẹ igi-oaku kan ti o wà ni Ofra, ti iṣe ti Joaṣi ọmọ Abieseri: Gideoni ọmọ rẹ̀ si npakà nibi ifọnti, lati fi i pamọ́ kuro loju awọn Midiani. Angeli OLUWA na si farahàn a, o si wi fun u pe, OLUWA wà pẹlu rẹ, iwọ ọkunrin alagbara. Gideoni si wi fun u pe, Yẽ oluwa mi, ibaṣepe OLUWA wà pẹlu wa, njẹ ẽṣe ti gbogbo eyi fi bá wa? nibo ni gbogbo iṣẹ-iyanu rẹ̀ ti awọn baba wa ti sọ fun wa gbé wà, wipe, OLUWA kò ha mú wa gòke lati Egipti wá? ṣugbọn nisisiyi OLUWA ti kọ̀ wa silẹ, o si ti fi wa lé Midiani lọwọ. OLUWA si wò o, o si wipe, Lọ ninu agbara rẹ yi, ki iwọ ki ó si gbà Israeli là kuro lọwọ Midiani: Emi kọ ha rán ọ bi? O si wi fun u pe, Yẽ oluwa mi, ọ̀na wo li emi o fi gbà Israeli là? kiyesi i, talakà ni idile mi ni Manasse, emi li o si jẹ́ ẹni ikẹhin ni ile baba mi. OLUWA si wi fun u pe, Nitõtọ emi o wà pẹlu rẹ, iwọ o si kọlù awọn Midiani bi ọkunrin kan. On si wi fun u pe, Bi o ba ṣepe mo ri ore-ọfẹ gbà li oju rẹ, njẹ fi àmi kan hàn mi pe iwọ bá mi sọ̀rọ. Máṣe lọ kuro nihin, emi bẹ̀ ọ, titi emi o fi tọ̀ ọ wá, ti emi o si fi mú ọrẹ mi fun ọ wá, ati ti emi o si fi gbé e kalẹ niwaju rẹ. On si wipe, Emi o duro titi iwọ o si fi pada wá. Gideoni si wọ̀ inu ilé lọ, o si pèse ọmọ ewurẹ kan, ati àkara alaiwu ti iyẹfun òṣuwọn efa kan: ẹran na li o fi sinu agbọ̀n, omi rẹ̀ li o si fi sinu ìkoko, o si gbé e jade tọ̀ ọ wá labẹ igi-oaku na, o si gbé e siwaju rẹ̀. Angeli Ọlọrun na si wi fun u pe, Mú ẹran na, ati àkara alaiwu na, ki o si fi wọn lé ori okuta yi, ki o si dà omi ẹran na silẹ. On si ṣe bẹ̃. Nigbana ni angeli OLUWA nà ọpá ti o wà li ọwọ rẹ̀, o si fi ori rẹ̀ kàn ẹran na ati àkara alaiwu na; iná si là lati inu okuta na jade, o si jó ẹran na, ati àkara alaiwu; angeli OLUWA na si lọ kuro niwaju rẹ̀. Gideoni si ri pe angeli OLUWA ni; Gideoni si wipe, Mo gbé, OLUWA Ọlọrun! nitoriti emi ri angeli OLUWA li ojukoju. OLUWA si wi fun u pe, Alafia fun ọ; má ṣe bẹ̀ru: iwọ́ ki yio kú. Nigbana ni Gideoni mọ pẹpẹ kan nibẹ̀ fun OLUWA, o si pè orukọ rẹ̀ ni Jehofa-ṣalomu: o wà ni Ofra ti awọn Abiesri sibẹ̀ titi di oni. O si ṣe li oru ọjọ́ kanna, li OLUWA wi fun u pe, Mú akọ-malu baba rẹ, ani akọ-malu keji ọlọdún meje, ki o si wó pẹpẹ Baali ti baba rẹ ní lulẹ ki o si bẹ́ igi-oriṣa ti o wà lẹba rẹ̀ lulẹ: Ki o si mọ pẹpẹ kan fun OLUWA Ọlọrun rẹ lori ibi agbara yi, bi o ti yẹ, ki o si mú akọ-malu keji, ki o si fi igi-oriṣa ti iwọ bẹ́ lulẹ ru ẹbọ sisun. Nigbana ni Gideoni mú ọkunrin mẹwa ninu awọn iranṣẹ rẹ̀, o si ṣe bi OLUWA ti sọ fun u: o si ṣe, nitoripe o bẹ̀ru ile baba rẹ̀ ati awọn ọkunrin ilu na, tobẹ̃ ti kò fi le ṣe e li ọsán, ti o si fi ṣe e li oru. Nigbati awọn ọkunrin ilu na si dide ni kùtukutu, si wò o, a ti wó pẹpẹ Baali lulẹ, a si bẹ́ igi-oriṣa lulẹ ti o wà lẹba rẹ̀, a si ti pa akọ-malu keji rubọ lori pẹpẹ ti a mọ. Nwọn si sọ fun ara wọn pe, Tali o ṣe nkan yi? Nigbati nwọn tọ̀sẹ̀, ti nwọn si bère, nwọn si wipe, Gideoni ọmọ Joaṣi li o ṣe nkan yi. Nigbana li awọn ọkunrin ilu na wi fun Joaṣi pe, Mú ọmọ rẹ jade wá ki o le kú: nitoripe o wó pẹpẹ Baali lulẹ, ati nitoriti o bẹ́ igi-oriṣa ti o wà lẹba rẹ̀ lulẹ. Joaṣi si wi fun gbogbo awọn ti o duro tì i pe, Ẹnyin o gbèja Baali bi? tabi ẹnyin o gbà a là bi? ẹniti o ba ngbèja rẹ̀, ẹ jẹ ki a lù oluwarẹ̀ pa ni kùtukutu owurọ yi: bi on ba ṣe ọlọrun, ẹ jẹ ki o gbèja ara rẹ̀, nitoriti ẹnikan wó pẹpẹ rẹ̀ lulẹ. Nitorina li ọjọ́ na, o pè orukọ rẹ̀ ni Jerubbaali, wipe, Jẹ ki Baali ki o bá a jà, nitoriti o wó pẹpẹ rẹ̀ lulẹ. Nigbana ni gbogbo awọn Midiani ati awọn Amaleki, ati awọn ọmọ ìha ìla-õrùn kó ara wọn jọ pọ̀; nwọn rekọja, nwọn si dó li afonifoji Jesreeli. Ṣugbọn ẹmi OLUWA bà lé Gideoni, on si fun ipè; Abieseri si kójọ sẹhin rẹ̀. On si rán onṣẹ si gbogbo Manasse; awọn si kójọ sẹhin rẹ̀ pẹlu: o si rán onṣẹ si Aṣeri, ati si Sebuluni, ati si Naftali; nwọn si gòke wá lati pade wọn. Gideoni si wi fun Ọlọrun pe, Bi iwọ o ba ti ọwọ́ mi gbà Israeli là, bi iwọ ti wi, Kiyesi i, emi o fi irun agutan le ilẹ-pakà; bi o ba ṣepe ìri sẹ̀ sara kìki irun nikan, ti gbogbo ilẹ si gbẹ, nigbana li emi o mọ̀ pe iwọ o ti ọwọ́ mi gbà Israeli là, gẹgẹ bi iwọ ti wi. Bẹ̃li o si ri: nitoriti on dide ni kùtukutu ijọ́ keji, o si fọ́n irun agutan na, o si fọ́n ìri na kuro lara rẹ̀, ọpọ́n kan si kún fun omi. Gideoni si wi fun Ọlọrun pe, Má ṣe jẹ ki ibinu rẹ ki o rú si mi, emi o sọ̀rọ lẹ̃kanṣoṣo yi: emi bẹ̀ ọ, jẹ ki emi ki o fi irun na ṣe idanwò lẹ̃kan yi; jẹ ki irun agutan nikan ki o gbẹ, ṣugbọn ki ìri ki o wà lori gbogbo ilẹ. Ọlọrun si ṣe bẹ̃ li oru na: nitoriti irun agutan na gbẹ, ìri si wà lori gbogbo ilẹ na.

A. Oni 6:1-40 Yoruba Bible (YCE)

Àwọn ọmọ Israẹli tún ṣe nǹkan tí ó burú lójú OLUWA, OLUWA sì fi wọ́n lé àwọn ará Midiani lọ́wọ́ fún ọdún meje. Àwọn ará Midiani lágbára ju àwọn ọmọ Israẹli lọ tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn ọmọ Israẹli fi ṣe ibi tí wọn ń sápamọ́ sí lórí àwọn òkè, ninu ihò àpáta, ati ibi ààbò mìíràn ninu òkè. Nítorí pé, nígbàkúùgbà tí àwọn ọmọ Israẹli bá gbin ohun ọ̀gbìn wọn, àwọn ará Midiani ati àwọn ará Amaleki ati àwọn kan láti inú aṣálẹ̀ tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn, a máa kó ara wọn jọ, wọn a lọ ṣígun bá àwọn ọmọ Israẹli. Wọn a gbógun tì wọ́n, wọn a sì ba gbogbo ohun ọ̀gbìn ilẹ̀ náà jẹ́ títí dé agbègbè Gasa. Wọn kì í fi oúnjẹ kankan sílẹ̀ rárá ní ilẹ̀ Israẹli, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í fi aguntan tabi mààlúù tabi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kankan sílẹ̀. Nítorí pé, nígbà tí wọ́n bá ń bọ̀, tilé-tilé ni wọ́n wá. Wọn á kó àwọn àgọ́ wọn ati àwọn ẹran ọ̀sìn wọn lọ́wọ́, wọn á sì bo àwọn ọmọ Israẹli bí eṣú. Àwọn ati ràkúnmí wọn kò níye, nítorí náà nígbà tí wọ́n bá dé, wọn á jẹ gbogbo ilẹ̀ náà ní àjẹrun. Àwọn ọmọ Israẹli di ẹni ilẹ̀ patapata, nítorí àwọn ará Midiani. Nítorí náà, wọ́n ké pe OLUWA fún ìrànlọ́wọ́. Nígbà tí wọ́n ké pe OLUWA, nítorí ìyọnu àwọn ará Midiani, OLUWA rán wolii kan sí wọn. Wolii náà bá sọ fún wọn pé, “OLUWA, Ọlọrun Israẹli ní, ‘Mo ko yín wá láti ilẹ̀ Ijipti, mo ko yín kúrò ní oko ẹrú. Mo gbà yín lọ́wọ́ àwọn ará Ijipti, ati gbogbo àwọn tí wọn ń ni yín lára. Mo lé wọn jáde fún yín, mo sì fi ilẹ̀ wọn fun yín. Mo kìlọ̀ fún yín pé, èmi ni OLUWA Ọlọrun yín, ati pé ẹ kò gbọdọ̀ bọ oriṣa àwọn ará Amori tí ẹ̀ ń gbé ilẹ̀ wọn, ṣugbọn ẹ kò gbọ́ tèmi.’ ” Angẹli OLUWA kan wá, ó jókòó lábẹ́ igi Oaku tí ó wà ní Ofira, igi Oaku yìí jẹ́ ti Joaṣi, ará Abieseri. Bí Gideoni ọmọ Joaṣi, ti ń pa ọkà ní ibi tí wọ́n ti ń pọn ọtí, tí ó ń fi í pamọ́ fún àwọn ará Midiani, ni angẹli OLUWA náà yọ sí i, ó sì wí fún un pé, “OLUWA wà pẹlu rẹ, ìwọ akikanju ati alágbára ọkunrin.” Gideoni dá a lóhùn, ó ní “Jọ̀wọ́, oluwa mi, bí OLUWA bá wà pẹlu wa, kí ló dé tí gbogbo nǹkan wọnyi fi ń ṣẹlẹ̀ sí wa? Níbo sì ni gbogbo àwọn iṣẹ́ ìyanu OLUWA wà, tí àwọn baba wa máa ń sọ fún wa nípa rẹ̀, pé, ‘Ṣebí OLUWA ni ó kó wa jáde láti ilẹ̀ Ijipti?’ Ṣugbọn nisinsinyii OLUWA ti kọ̀ wá sílẹ̀, ó sì ti fi wá lé àwọn ará Midiani lọ́wọ́.” Ṣugbọn OLUWA yipada sí i, ó sì dá a lóhùn pé, “Lọ pẹlu agbára rẹ yìí, kí o sì gba Israẹli kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Midiani, ṣebí èmi ni mo rán ọ.” Gideoni dáhùn, ó ní, “Sọ fún mi OLUWA, báwo ni mo ṣe lè gba Israẹli sílẹ̀? Ìran mi ni ó rẹ̀yìn jùlọ ninu ẹ̀yà Manase, èmi ni mo sì kéré jù ní ìdílé wa.” OLUWA dá a lóhùn, ó ní, “N óo wà pẹlu rẹ, o óo sì run àwọn ará Midiani bí ẹni pé, ẹyọ ẹnìkan péré ni wọ́n.” Gideoni tún dáhùn, ó ní, “Bí inú rẹ bá yọ́ sí mi, fi àmì kan hàn mí pé ìwọ OLUWA ni ò ń bá mi sọ̀rọ̀. Jọ̀wọ́, má kúrò níhìn-ín títí tí n óo fi mú ẹ̀bùn mi dé, tí n óo sì gbé e kalẹ̀ níwájú rẹ.” Angẹli náà dá Gideoni lóhùn, ó ní, “N óo dúró títí tí o óo fi pada dé.” Gideoni bá wọlé lọ, ó tọ́jú ọmọ ewúrẹ́ kan, ó sì fi ìyẹ̀fun ìwọ̀n efa kan ṣe burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu. Ó kó ẹran tí ó sè sinu agbọ̀n kan, ó da omi ọbẹ̀ rẹ̀ sinu ìkòkò kan, ó gbé e tọ Angẹli OLUWA náà lọ ní abẹ́ igi Oaku, ó sì gbé wọn kalẹ̀ níwájú rẹ̀. Angẹli Ọlọrun náà wí fún un pé, “Da ẹran náà ati burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu náà sí orí àpáta yìí, kí o sì da omi ọbẹ̀ náà lé gbogbo rẹ̀ lórí.” Gideoni sì ṣe bẹ́ẹ̀. Angẹli OLUWA náà bá na ọ̀pá tí ó wà ní ọwọ́ rẹ̀, ó sì fi ṣóńṣó orí rẹ̀ kan ẹran ati burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu náà; iná bá ṣẹ́ lára àpáta, ó sì jó ẹran ati burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu náà. Angẹli OLUWA náà bá rá mọ́ ọn lójú. Nígbà náà ni Gideoni tó mọ̀ pé angẹli OLUWA ni, ó bá dáhùn pé, “Yéè! OLUWA Ọlọrun, mo gbé! Nítorí pé mo ti rí angẹli OLUWA lojukooju.” Ṣugbọn OLUWA dá a lóhùn pé, “Alaafia ni, má bẹ̀rù, o kò ní kú.” Gideoni bá tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀ fún OLUWA, ó pe orúkọ rẹ̀ ní “OLUWA ni Alaafia.” Pẹpẹ náà wà ní Ofira ti ìdílé Abieseri títí di òní olónìí. Ní òru ọjọ́ náà, OLUWA sọ fún Gideoni pé, “Mú akọ mààlúù baba rẹ ati akọ mààlúù mìíràn tí ó jẹ́ ọlọ́dún meje, wó pẹpẹ oriṣa Baali baba rẹ lulẹ̀, kí o sì gé ère oriṣa Aṣera tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Kí o wá tẹ́ pẹpẹ kan fún èmi OLUWA Ọlọrun rẹ lórí òkítì ibi gegele náà. To àwọn òkúta rẹ̀ lérí ara wọn dáradára, lẹ́yìn náà mú akọ mààlúù keji kí o sì fi rú ẹbọ sísun. Igi ère oriṣa Aṣera tí o bá gé lulẹ̀ ni kí o fi ṣe igi ẹbọ sísun náà.” Gideoni mú mẹ́wàá ninu àwọn iranṣẹ rẹ̀, ó sì ṣe bí OLUWA ti ní kí ó ṣe, ṣugbọn kò lè ṣe é lọ́sàn-án, nítorí ẹ̀rù àwọn ará ilé ati àwọn ará ìlú rẹ̀ ń bà á, nítorí náà lóru ni ó ṣe é. Nígbà tí àwọn ará ìlú náà jí ní òwúrọ̀ kutukutu, wọ́n rí i pé, wọ́n ti wó pẹpẹ oriṣa Baali lulẹ̀, wọ́n sì ti gé ère oriṣa Aṣera tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ati pé wọ́n ti fi mààlúù keji rúbọ lórí pẹpẹ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́. Wọ́n bá ń bi ara wọn léèrè pé, “Ta ló dán irú èyí wò?” Lẹ́yìn ìgbà tí wọn ti wádìí, wọ́n ní, “Gideoni ọmọ Joaṣi ni ó ṣe é.” Àwọn ará ìlú náà bá wí fún Joaṣi pé, “Mú ọmọ rẹ jáde kí á pa á, nítorí pé ó ti wó pẹpẹ oriṣa Baali, ó sì ti gé ère oriṣa Aṣera tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀.” Ṣugbọn Joaṣi dá àwọn tí wọ́n dìde sí Gideoni lóhùn, ó ní, “Ṣé ẹ fẹ́ gbèjà oriṣa Baali ni, àbí ẹ fẹ́ dáàbò bò ó? Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbèjà rẹ̀, pípa ni a óo pa á kí ilẹ̀ tó mọ́. Bí ó bá jẹ́ pé ọlọrun ni Baali nítòótọ́, kí ó gbèjà ara rẹ̀, nítorí pẹpẹ rẹ̀ tí wọ́n wó lulẹ̀.” Nítorí náà, láti ọjọ́ náà lọ ni wọ́n ti ń pe Gideoni ní Jerubaali, ìtumọ̀ rẹ̀ ni pé, “Ẹ jẹ́ kí Baali bá a jà fúnra rẹ̀,” nítorí pé ó wó pẹpẹ rẹ̀ lulẹ̀. Nígbà náà ni gbogbo àwọn ará ilẹ̀ Midiani ati àwọn ará ilẹ̀ Amaleki ati àwọn ará ilẹ̀ tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn kó ara wọn jọ, wọ́n la odò Jọdani kọjá, wọ́n sì pàgọ́ wọn sí àfonífojì Jesireeli. Ṣugbọn Ẹ̀mí Ọlọrun bà lé Gideoni, Gideoni bá fọn fèrè ogun, àwọn ọmọ Abieseri bá pe ara wọn jáde wọ́n bá tẹ̀lé e. Ó ranṣẹ jákèjádò ilẹ̀ Manase, wọ́n pe ara wọn jáde, wọ́n sì tẹ̀lé e. Ó tún ranṣẹ bákan náà sí ẹ̀yà Aṣeri, ẹ̀yà Sebuluni, ati ẹ̀yà Nafutali, àwọn náà sì lọ pàdé rẹ̀. Gideoni wí fún Ọlọrun pé, “Bí ó bá jẹ́ pé èmi ni o fẹ́ lò láti gba Israẹli kalẹ̀, gẹ́gẹ́ bí o ti wí, n óo fi irun aguntan lélẹ̀ ní ibi ìpakà, bí ìrì bà sẹ̀ sórí irun yìí nìkan, tí gbogbo ilẹ̀ tí ó yí i ká bá gbẹ, nígbà náà ni n óo gbà pé nítòótọ́, èmi ni o fẹ́ lò láti gba Israẹli kalẹ̀, gẹ́gẹ́ bí o ti wí.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀. Nígbà tí ó jí ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, tí ó sì fún irun aguntan náà, ìrì tí ó fún ní ara rẹ̀ kún abọ́ kan. Gideoni tún wí fún Ọlọrun pé, “Jọ̀wọ́, má jẹ́ kí inú bí ọ sí mi, ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo yìí ni ó kù tí mo fẹ́ sọ̀rọ̀; jọ̀wọ́ jẹ́ kí n tún dán kinní kan wò pẹlu irun aguntan yìí lẹ́ẹ̀kan sí i, jẹ́ kí gbogbo irun yìí gbẹ ṣugbọn kí ìrì sẹ̀ sí gbogbo ilẹ̀, kí ó sì tutù.” Ọlọrun tún ṣe bẹ́ẹ̀ ní alẹ́ ọjọ́ náà, nítorí pé, orí irun yìí nìkan ṣoṣo ni ó gbẹ, ìrì sì sẹ̀ sí gbogbo ilẹ̀.

A. Oni 6:1-40 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Àwọn ọmọ Israẹli sì túnṣe ohun tí ó burú ní ojú OLúWA, Ó sì fi wọ́n lé àwọn ará Midiani lọ́wọ́ fún ọdún méje. Agbára àwọn ará Midiani sì pọ̀ púpọ̀ lórí àwọn Israẹli, wọ́n sì hùwà ipá sí wọn, nítorí ìdí èyí, àwọn Israẹli sálọ sí àwọn orí òkè, wọ́n sì kọ́ àgọ́ fún ara wọn nínú ihò àpáta, àti nínú ọ̀gbun àti ní ibi agbára nínú àpáta. Ní ìgbàkúgbà tí àwọn ọmọ Israẹli bá ti gbin ọ̀gbìn wọn, àwọn ará Midiani, àwọn ará Amaleki àti àwọn ará ìlà-oòrùn mìíràn yóò wá láti bá wọn jà. Wọn yóò tẹ̀dó sí orí ilẹ̀ náà, wọn a sì bá irúgbìn wọ̀nyí jẹ́ títí dé Gasa, wọn kì í sì í fi ohun alààyè kankan sílẹ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli, kì bá à ṣe àgùntàn, màlúù tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Wọn a máa wá pẹ̀lú ohun ọ̀sìn wọn àti àwọn àgọ́ wọn, wọn a sì dàbí eṣú nítorí i púpọ̀ wọn. Ènìyàn kò sì lè ka iye àwọn ènìyàn náà bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìbákasẹ, wọ́n pọ̀ dé bi pé wọn kò ṣe é kà ní iye, wọn a bo ilẹ̀ náà wọn a sì jẹ ẹ́ run. Àwọn ará Midiani sì pọ́n àwọn ọmọ Israẹli lójú, wọ́n sọ wọ́n di òtòṣì àti aláìní, fún ìdí èyí wọ́n ké pe OLúWA nínú àdúrà fún ìrànlọ́wọ́. Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli ké pe OLúWA nítorí àwọn ará Midiani. OLúWA fi etí sí igbe wọn, ó sì rán wòlíì kan sí wọn, ẹni tí ó wí pé, “Èyí ni ohun tí OLúWA Ọlọ́run Israẹli wí: mo mú yín gòkè ti Ejibiti wá, láti oko ẹrú. Mo gbà yín kúrò nínú agbára Ejibiti àti kúrò ní ọwọ́ gbogbo àwọn aninilára yín. Mo lé wọn kúrò ní iwájú yín, mo sì fi ilẹ̀ wọn fún yín. Mo wí fún un yín pé, èmi ni OLúWA Ọlọ́run yín: ẹ má ṣe sin àwọn òrìṣà àwọn ará Amori, ní ilẹ̀ ẹni tí ẹ̀yin ń gbé. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbọ́rọ̀ sí ohun tí mo sọ.” Ní ọjọ́ kan angẹli OLúWA wá, ó sì jókòó ní abẹ́ igi óákù ofira èyí ti ṣe ti Joaṣi ará Abieseri, níbi tí Gideoni ọmọ rẹ̀ ti ń lu ọkà jéró, níbi ìpọntí wáìnì láti fi pamọ́ kúrò níwájú àwọn ará Midiani. Nígbà tí angẹli OLúWA fi ara han Gideoni, ó wí fún un pé, “OLúWA wà pẹ̀lú rẹ, akọni ológun.” Gideoni dáhùn pé, “Alàgbà, bí OLúWA bá wà pẹ̀lú wa, kí ló dé tí gbogbo ìwọ̀nyí fi ń ṣẹlẹ̀ sí wa? Níbi gbogbo àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ tí àwọn baba wa ròyìn rẹ̀ fún wa nígbà tí wọ́n wí pé, ‘OLúWA kò ha mú wa gòkè láti ilẹ̀ Ejibiti wá?’ Ṣùgbọ́n nísinsin yìí OLúWA ti kọ̀ wá sílẹ̀, ó sì ti fi wá lé àwọn ará Midiani lọ́wọ́.” OLúWA sì yípadà sí i, ó sì wí fún un pé, “Lọ nínú agbára tí o ní yìí, kí o sì gba àwọn ará Israẹli sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Midiani. Èmi ni ó ń rán ọ lọ.” Gideoni sì dáhùn pé, “Yéè olúwa mi, ọ̀nà wo ni èmi yóò fi gba Israẹli là? Ìdílé mi ni ó jẹ́ aláìlera jù ní Manase, àti pé èmi ni ó sì kéré jù ní ìdílé baba mi.” OLúWA sì dáhùn pé, “Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ, ìwọ yóò sì pa gbogbo àwọn ará Midiani láì ku ẹnìkankan.” Gideoni sì dáhùn pé, nísinsin yìí tí mo bá bá ojúrere rẹ pàdé, fún mi ní ààmì pé ìwọ ni ń bá mi sọ̀rọ̀. Jọ̀wọ́ má ṣe kúrò níbí títí èmi yóò fi mú ọrẹ wá fún ọ kí n sì gbé e sí iwájú rẹ. OLúWA sì wí pé, “Èmi yóò dúró títí ìwọ yóò fi dé.” Gideoni sì yára wọ ilé lọ, ó sì pa ọ̀dọ́ ewúrẹ́ kan, wọ́n sì sè é, ó sì mú ìyẹ̀fun efa kan, ó fi ṣe àkàrà aláìwú. Ó gbé ẹran náà sínú agbọ̀n, ṣùgbọ́n ó fi ọbẹ̀ rẹ̀ sínú ìkòkò, ó gbé wọn jáde tọ angẹli náà wá bí ọrẹ lábẹ́ igi óákù. Angẹli Ọlọ́run náà sì wí fún un pé, “Gbé ẹran náà àti àkàrà àìwú náà, sí orí àpáta yìí, kí o sì da omi ọbẹ̀ rẹ̀ sí orí rẹ̀.” Gideoni sì ṣe bẹ́ẹ̀. Angẹli OLúWA sì fi orí ọ̀pá tí ó wà ní ọwọ́ rẹ̀ kan ẹran àti àkàrà àìwú náà. Iná sì jáde láti inú àpáta, ó sì jó ẹran àti àkàrà náà, kò sì rí angẹli náà mọ́. Nígbà tí Gideoni sì ti mọ̀ dájúdájú pé angẹli OLúWA ni, ó ké wí pé, “Háà! OLúWA Olódùmarè! Mo ti rí angẹli OLúWA ní ojúkorojú!” Ṣùgbọ́n OLúWA wí fún un pé, “Àlàáfíà! Má ṣe bẹ̀rù, ìwọ kì yóò kùú.” Báyìí ni Gideoni mọ pẹpẹ kan fún OLúWA níbẹ̀, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní “Àlàáfíà ni OLúWA.” Ó sì wà ní Ofira ti Abieseri títí di òní. Ní òru ọjọ́ náà OLúWA wí fún un pé, mú akọ màlúù baba rẹ, àní akọ màlúù kejì ọlọ́dún méje. Wó pẹpẹ Baali baba rẹ lulẹ̀, kí o sì bẹ́ igi ère òrìṣà Aṣerah tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ lulẹ̀. Lẹ́yìn èyí kí o wá mọ pẹpẹ èyí tí ó yẹ fún OLúWA Ọlọ́run rẹ lórí òkè yìí. Kí o sì mú akọ màlúù kejì, kí o sì mú igi ère òrìṣà Aṣerah tí ìwọ bẹ́ lulẹ̀ rú ẹbọ sísun sí OLúWA. Gideoni mú mẹ́wàá nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì ṣe bí OLúWA ti pàṣẹ fún un ṣùgbọ́n, nítorí ó bẹ̀rù àwọn ará ilé baba rẹ̀ àti àwọn ènìyàn ìlú náà kò ṣe é ní ọ̀sán, òru ni ó ṣe. Nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ kejì mọ́, tí àwọn ènìyàn ìlú náà jí, wọ́n rí i pé àti fọ́ pẹpẹ Baali àti pé a ti bẹ́ igi ère òrìṣà Aṣerah tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, a sì ti fi akọ màlúù kejì rú ẹbọ lórí pẹpẹ tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ. Àwọn ènìyàn ìlú náà bi ara wọn wí pé, “Ta ni ó ṣe èyí?” Lẹ́yìn tí wọn fi ara balẹ̀ ṣe ìwádìí, wọ́n gbọ́ wí pé, “Gideoni ọmọ Joaṣi ni ó ṣe é.” Àwọn ọkùnrin ìlú náà sì wí fún Joaṣi wí pé, “Mú ọmọ rẹ jáde wá. Ó ní láti kú nítorí pé ó ti wó pẹpẹ Baali lulẹ̀ ó sì ti ké ère òrìṣà Aṣerah tí ó wà ní ẹ̀bá rẹ̀ lulẹ̀.” Ṣùgbọ́n Joaṣi bi àwọn èrò tí wọ́n fi ìbínú dúró tì í wí pé, “Ẹ̀yin yóò ha gbìjà Baali bí? Ẹ̀yin yóò ha gbà á sílẹ̀ bí? Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbìjà rẹ̀ kíkú ni olúwa rẹ̀ yóò kú ní òwúrọ̀. Bí Baali bá ṣe Ọlọ́run nítòótọ́ yóò jà fún ara rẹ̀ bí ẹnikẹ́ni bá wó pẹpẹ rẹ̀ lulẹ̀.” Fún ìdí èyí ní ọjọ́ náà wọ́n pe Gideoni ní “Jerubbaali” wí pé, “Jẹ́ kí Baali bá a jà,” nítorí pé ó ti wó pẹpẹ Baali. Láìpẹ́ jọjọ, àwọn ogun àwọn Midiani, ti àwọn Amaleki àti ti àwọn ènìyàn ìhà ìlà-oòrùn yòókù kó ara wọn jọ pọ̀ ní ìṣọ̀kan, wọ́n sì kọjá Jordani wọ́n sì tẹ̀dó sí Àfonífojì Jesreeli. Ẹ̀mí OLúWA sì bà lé Gideoni, ó sì fun fèrè ìpè, láti pe àwọn ará Abieseri láti tẹ̀lé òun. Ó rán àwọn oníṣẹ́ la ilẹ̀ Manase já pé kí wọ́n dira ogun, àti sí Aṣeri, Sebuluni àti Naftali gbogbo pẹ̀lú sì lọ láti pàdé wọn. Gideoni wí fún Ọlọ́run pé, “Bí ìwọ yóò bá gba Israẹli là nípasẹ̀ mi bí ìwọ ti ṣe ìlérí— kíyèsi, èmi yóò fi awọ irun àgùntàn lé ilẹ̀ ìpakà ní alẹ́ òní. Bí ìrì bá sẹ̀ sí orí awọ yìí nìkan tí gbogbo ilẹ̀ yòókù sì gbẹ, nígbà náà ni èmi yóò mọ̀ lóòótọ́ pé ìwọ yóò gba Israẹli là nípasẹ̀ mi bí ìwọ ti sọ.” Èyí ni ó sì ṣẹlẹ̀. Nígbà tí Gideoni jí ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ó sì fún irun àgùntàn náà, ọpọ́n omi kan sì kún. Gideoni sì tún wí fún Ọlọ́run pé, “Jọ̀wọ́ má ṣe bínú sí mi, ṣùgbọ́n jẹ́ kí n tún wá ìdánilójú kan sí i, èmi bẹ̀ ọ́ jẹ́ kí n fi awọ irun yìí ṣe ìdánwò kan sí i. Ní àsìkò yìí, jẹ́ kí awọ irun yìí gbẹ kí gbogbo ilẹ̀ sì tutù pẹ̀lú ìrì.” Ní òru náà Ọlọ́run ṣe bẹ́ẹ̀, awọ irun àgùntàn nìkan ni ó gbẹ; gbogbo ilẹ̀ yòókù sì tutù nítorí ìrì.