A. Oni 4:4-24
A. Oni 4:4-24 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ati Debora, wolĩ-obinrin, aya Lappidotu, o ṣe idajọ Israeli li akokò na. On si ngbé abẹ igi-ọpẹ Debora li agbedemeji Rama ati Beti-eli ni ilẹ òke Efraimu: awọn ọmọ Israeli a si ma wá sọdọ rẹ̀ fun idajọ. On si ranṣẹ pè Baraki ọmọ Abinoamu lati Kedeṣi-naftali jade wá, o si wi fun u pe, OLUWA, Ọlọrun Israeli kò ha ti paṣẹ pe, Lọ sunmọ òke Tabori, ki o si mú ẹgba marun ọkunrin ninu awọn ọmọ Naftali, ati ninu awọn ọmọ Sebuluni pẹlu rẹ. Emi o si fà Sisera, olori ogun Jabini, pẹlu kẹkẹ́ rẹ̀ ati ogun rẹ̀, sọdọ rẹ si odò Kiṣoni; emi o si fi i lé ọ lọwọ. Baraki si wi fun u pe, Bi iwọ o ba bá mi lọ, njẹ emi o lọ: ṣugbọn bi iwọ ki yio ba bá mi lọ, emi ki yio lọ. On si wipe, Ni lilọ emi o bá ọ lọ: ṣugbọn ọlá ọ̀na ti iwọ nlọ nì ki yio jẹ́ tirẹ; nitoriti OLUWA yio tà Sisera si ọwọ́ obinrin. Debora si dide, o si bá Baraki lọ si Kedeṣi. Baraki si pè Sebuluni ati Naftali si Kedeṣi; on si lọ pẹlu ẹgba marun ọkunrin lẹhin rẹ̀: Debora si gòke lọ pẹlu rẹ̀. Njẹ Heberi ọmọ Keni, ti yà ara rẹ̀ kuro lọdọ awọn ọmọ Keni, ani awọn ọmọ Hobabu, ana Mose, o si pa agọ́ rẹ̀ titi dé igi-oaku Saanannimu, ti o wà li àgbegbe Kedeṣi. Nwọn si sọ fun Sisera pe, Baraki ọmọ Abinoamu ti lọ si òke Tabori. Sisera si kó gbogbo kẹkẹ́ rẹ̀ jọ, ẹdẹgbẹrun kẹkẹ́ irin, ati gbogbo awọn enia ti o wà pẹlu rẹ̀, lati Haroṣeti awọn orilẹ-ède wá si odò Kiṣoni. Debora si wi fun Baraki pe, Dide; nitoripe oni li ọjọ́ ti OLUWA fi Sisera lé ọ lọwọ: OLUWA kò ha ti ṣaju rẹ lọ bi? Bẹ̃ni Baraki sọkalẹ lati òke Tabori lọ, ẹgba marun ọkunrin si tẹle e lẹhin. OLUWA si fi oju idà ṣẹgun Sisera, ati gbogbo kẹkẹ́ rẹ̀, ati gbogbo ogun rẹ̀, niwaju Baraki; Sisera si sọkalẹ kuro li ori kẹkẹ́ rẹ̀, o si fi ẹsẹ̀ rẹ̀ sálọ. Ṣugbọn Baraki lepa awọn kẹkẹ́, ati ogun na, titi dé Haroṣeti awọn orilẹ-ède: gbogbo ogun Sisera si ti oju idà ṣubu; ọkunrin kanṣoṣo kò si kù. Ṣugbọn Sisera ti fi ẹsẹ̀ rẹ̀ sálọ si agọ́ Jaeli aya Heberi ọmọ Keni: nitoriti alafia wà lãrin Jabini ọba Hasori ati ile Heberi ọmọ Keni. Jaeli si jade lọ ipade Sisera, o si wi fun u pe, Yà wá, oluwa mi, yà sọdọ mi; má bẹ̀ru. On si yà sọdọ rẹ̀ sinu agọ́, o si fi kubusu bò o. On si wi fun u pe, Emi bẹ̀ ọ, fun mi li omi diẹ mu; nitoriti ongbẹ ngbẹ mi. O si ṣí igo warà kan, o si fi fun u mu, o si bò o lara. On si wi fun u pe, Duro li ẹnu-ọ̀na agọ́, yio si ṣe, bi ẹnikan ba wá, ti o si bi ọ lère pe, ọkunrin kan wà nihin bi? ki iwọ wipe, Kò sí. Nigbana ni Jaeli aya Heberi mú iṣo-agọ́ kan, o si mú õlù li ọwọ́ rẹ̀, o si yọ́ tọ̀ ọ, o si kàn iṣo na mọ́ ẹbati rẹ̀, o si wọ̀ ilẹ ṣinṣin; nitoriti o sùn fọnfọn; bẹ̃ni o daku, o si kú. Si kiyesi i, bi Baraki ti nlepa Sisera, Jaeli wá pade, rẹ̀, o si wi fun u pe, Wá, emi o si fi ọkunrin ti iwọ nwá hàn ọ. O si wá sọdọ rẹ̀; si kiyesi i, Sisera dubulẹ li okú, iṣo-agọ́ na si wà li ẹbati rẹ̀. Bẹ̃li Ọlọrun si tẹ̀ ori Jabini ọba Kenaani ba li ọjọ́ na niwaju awọn ọmọ Israeli. Ọwọ́ awọn ọmọ Israeli si le siwaju ati siwaju si Jabini ọba Kenaani, titi nwọn fi run Jabini ọba Kenaani.
A. Oni 4:4-24 Yoruba Bible (YCE)
Wolii obinrin kan, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Debora aya Lapidotu, ni adájọ́ ní ilẹ̀ Israẹli nígbà náà. Lábẹ́ ọ̀pẹ kan, tí wọ́n sọ ní ọ̀pẹ Debora, tí ó wà láàrin Rama ati Bẹtẹli ní agbègbè olókè ti Efuraimu ní í máa ń jókòó sí, ibẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli tií máa ń lọ bá a fún ìdájọ́. Ó ranṣẹ pe Baraki, ọmọ Abinoamu, ní Kedeṣi, tí ó wà ní Nafutali, ó wí fún un pé, “OLUWA Ọlọrun Israẹli ń pàṣẹ fún ọ pé kí o lọ kó àwọn eniyan rẹ̀ jọ ní òkè Tabori. Kó ẹgbaarun (10,000) eniyan ninu ẹ̀yà Nafutali ati Sebuluni jọ. N óo ti Sisera olórí ogun Jabini jáde láti pàdé rẹ lẹ́bàá odò Kiṣoni pẹlu àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ati àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, n óo sì fà á lé ọ lọ́wọ́.” Baraki bá dá a lóhùn pé, “Bí o óo bá bá mi lọ ni n óo lọ, bí o kò bá ní bá mi lọ, n kò ní lọ.” Debora dáhùn pé, “Láìṣe àní àní, n óo bá ọ lọ. Ṣugbọn ṣá o, ohun tí o fẹ́ ṣe yìí kò ní já sí ògo fún ọ, nítorí pé, OLUWA yóo fi Sisera lé obinrin kan lọ́wọ́.” Debora bá gbéra, ó bá Baraki lọ sí Kedeṣi. Baraki bá pe àwọn ọmọ Sebuluni ati Nafutali sí Kedeṣi; ẹgbaarun (10,000) ọkunrin ninu wọn ni wọ́n tẹ̀lé Baraki, Debora náà sì bá wọn lọ. Ní àkókò yìí, Heberi ará Keni ti kúrò ní ọ̀dọ̀ àwọn ará Keni yòókù tí wọ́n jẹ́ ìran Hobabu, àna Mose, ó sì pàgọ́ sí ẹ̀bá Kedeṣi lẹ́bàá igi oaku kan ní Saananimu. Nígbà tí Sisera gbọ́ pé Baraki ti lọ sí orí òkè Tabori, ó kó ẹẹdẹgbẹrun (900) kẹ̀kẹ́ ogun onírin rẹ̀ jọ, ó sì pe àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jọ láti Haroṣeti-ha-goimu títí dé odò Kiṣoni. Debora wí fún Baraki pé, “Dìde nítorí pé òní ni ọjọ́ tí OLUWA yóo fi Sisera lé ọ lọ́wọ́. Ṣebí OLUWA ni ó ń ṣáájú ogun rẹ lọ?” Baraki bá sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè Tabori pẹlu ẹgbaarun (10,000) ọmọ ogun lẹ́yìn rẹ̀. OLUWA mú ìdàrúdàpọ̀ bá Sisera ati gbogbo kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ níwájú Baraki. Bí àwọn ọmọ ogun Baraki ti ń fi idà pa wọ́n, Sisera sọ̀kalẹ̀ ninu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ. Baraki lépa àwọn kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ọmọ ogun Sisera títí dé Haroṣeti-ha-goimu, wọ́n sì fi idà pa àwọn ọmọ ogun Sisera láìku ẹyọ ẹnìkan. Ṣugbọn Sisera sá lọ sí àgọ́ Jaeli, aya Heberi, ará Keni, nítorí pé alaafia wà ní ààrin Jabini, ọba Hasori, ati ìdílé Heberi ará Keni. Jaeli bá jáde lọ pàdé Sisera, ó wí fún un pé, “Máa bọ̀ níhìn-ín, oluwa mi. Yà wá sọ́dọ̀ mi, má bẹ̀rù.” Sisera bá yà sinu àgọ́ rẹ̀, ó sì fi aṣọ tí ó nípọn bò ó. Sisera bá bẹ̀ ẹ́ pé, “Jọ̀wọ́ òùngbẹ ń gbẹ mí, fún mi lómi mu.” Jaeli bá ṣí ìdérí ìgò tí wọ́n fi awọ ṣe, tí wọ́n da wàrà sí, ó fún un ní wàrà mu, ó sì tún da aṣọ bò ó. Sisera wí fún un pé, “Jọ̀wọ́ dúró ní ẹnu ọ̀nà àgọ́. Bí ẹnikẹ́ni bá wá, tí ó sì bi ọ́ léèrè pé, ‘Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni wà níbí?’ Wí fún olúwarẹ̀ pé, ‘Kò sí.’ ” Ó ti rẹ Sisera tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi sùn lọ fọnfọn. Jaeli bá mú òòlù kan, ati èèkàn àgọ́, ó yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ lọ sí ibi tí Sisera sùn sí, ó kan èèkàn náà mọ́ ọn lẹ́bàá etí títí tí èèkàn náà fi wọlé, ó sì kú. Bí Baraki ti ń wá Sisera kiri, Jaeli lọ pàdé rẹ̀, ó wí fún un pé, “Máa bọ̀ níhìn-ín, n óo sì fi ẹni tí ò ń wá hàn ọ́.” Baraki bá bá a wọlé lọ, ó sì bá Sisera nílẹ̀ níbi tí ó kú sí, pẹlu èèkàn àgọ́ tí wọn gbá mọ́ ọn lẹ́bàá etí. Ní ọjọ́ náà ni Ọlọrun bá àwọn ọmọ Israẹli ṣẹgun Jabini, ọba àwọn ará Kenaani. Àwọn ọmọ Israẹli bẹ̀rẹ̀ sí kọlu Jabini, ọba Kenaani lemọ́lemọ́ títí wọ́n fi pa á run.
A. Oni 4:4-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Debora, wòlíì obìnrin, aya Lapidoti ni olórí àti aṣíwájú àwọn ará Israẹli ní àsìkò náà. Òun a máa jókòó ṣe ìdájọ́ ní abẹ́ igi ọ̀pẹ tí a sọ orúkọ rẹ̀ ní ọ̀pẹ Debora láàrín Rama àti Beteli ní ilẹ̀ òkè Efraimu, àwọn ará Israẹli a sì máa wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti yanjú èdè-àìyedè tí wọ́n bá ní sí ara wọn, tàbí láti gbọ́ ohùn OLúWA láti ẹnu rẹ̀. Ní ọjọ́ kan, ó ránṣẹ́ pe Baraki ọmọ Abinoamu, ẹni tí ń gbé ní Kedeṣi ní ilẹ̀ Naftali, ó sì wí fún un pé, “OLúWA, Ọlọ́run Israẹli pa á ní àṣẹ fún un pé: ‘Kí ó kó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá àwọn akọni ọkùnrin jọ láti ẹ̀yà Naftali àti ẹ̀yà Sebuluni bí ẹgbẹ́ ogun, kí o sì síwájú wọn lọ sí òkè Tabori. Èmi yóò sì fa Sisera olórí ogun Jabini, pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ ogun rẹ àti àwọn ogun rẹ, sí odò Kiṣoni èmi yóò sì fi lé ọ lọ́wọ́ ìwọ yóò sì ṣẹ́gun wọn níbẹ̀.’ ” Baraki sì dá a lóhùn pé, “Èmi yóò lọ tí ìwọ ó bá bá mi lọ, ṣùgbọ́n tí ìwọ kì yóò bá bá mi lọ, èmi kì yóò lọ.” Debora dá a lóhùn pé, “ó dára, èmi yóò bá ọ lọ. Ṣùgbọ́n ọlá ìṣẹ́gun tí o ń lọ yìí kò ní jẹ́ tìrẹ, nítorí OLúWA yóò fi Sisera lé obìnrin lọ́wọ́” Báyìí Debora bá Baraki lọ sí Kedeṣi. Nígbà tí Baraki pe ẹ̀yà Sebuluni àti ẹ̀yà Naftali sí Kedeṣi ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá akíkanjú ọkùnrin ogun tẹ̀lé e, Debora pẹ̀lú bá wọn lọ. Ǹjẹ́ Heberi ọmọ Keni, ti ya ara rẹ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ Keni, àní àwọn ọmọ Hobabu, àna Mose, ó sì pa àgọ́ rẹ̀ títí dé ibi igi óákù Saananimu, tí ó wà ni agbègbè Kedeṣi. Nígbà tí a sọ fún Sisera pé Baraki ọmọ Abinoamu ti kó ogun jọ sí òkè Tabori, Sisera kó gbogbo kẹ̀kẹ́ ogun irin rẹ̀ tí ṣe ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀run (900) àti gbogbo àwọn ènìyàn (ọmọ-ogun) tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, láti Haroseti tí àwọn orílẹ̀-èdè wá sí odò Kiṣoni. Debora sì wí fún Baraki pé, “Lọ! Lónìí ni OLúWA fi Sisera lé ọ lọ́wọ́, OLúWA ti lọ síwájú rẹ.” Baraki sì síwájú, àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá sì tẹ̀lé e lẹ́yìn, wọ́n sì kọjá sí òkè Tabori. OLúWA sì mú ìdàrúdàpọ̀ wá sí àárín ogun Sisera, OLúWA sì fi ojú idà ṣẹ́gun Sisera àti àwọn oníkẹ̀kẹ́ ogun àti ọmọ-ogun orí ilẹ̀ ní iwájú Baraki. Sisera sì sọ̀kalẹ̀ lórí kẹ̀kẹ́-ẹṣin rẹ̀ ó sì fi ẹsẹ̀ sálọ. Baraki àti àwọn ogun rẹ̀ sì lé àwọn ọ̀tá náà, àwọn ọmọ-ogun orílẹ̀ àti àwọn kẹ̀kẹ́ ogun wọn títí dé Haroseti ti àwọn orílẹ̀-èdè, gbogbo ogun Sisera sì ti ojú idà ṣubú, kò sí ọ̀kan tí ó lè sálà tàbí tí ó wà láààyè. Ṣùgbọ́n Sisera ti fi ẹsẹ̀ sálọ sí àgọ́ Jaeli aya Heberi ẹ̀yà Keni: nítorí ìbá dá ọ̀rẹ́ àlàáfíà wà láàrín Jabini ọba Hasori àti ìdílé Heberi ti ẹ̀yà Keni. Jaeli sì jáde síta láti pàdé Sisera, ó sì wí fún un pé, “Wọlé sínú àgọ́ mi, OLúWA mi, wọlé wá má ṣe bẹ̀rù nítorí pé ààbò ń bẹ fún ọ.” Ó sì yà sínú àgọ́ rẹ̀, ó sì fi aṣọ bò ó. Sisera wí pé, “Òrùngbẹ ń gbẹ́ mí, jọ̀wọ́ fún mi ní omi mu.” Ó sì ṣí awọ wàrà kan, ó sì fún un mu ó sì tún daṣọ bò ó padà. Sisera sọ fún Jaeli pé, “Kí ó dúró ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́, àti pé bí ẹnikẹ́ni bá béèrè bóyá òun wà níbẹ̀ kí ó sọ pé, ‘Kò sí ẹnìkankan ní ibẹ̀.’ ” Ṣùgbọ́n Jaeli ìyàwó Heberi mú ìṣó àgọ́ tí ó mú àti òòlù ní ọwọ́ rẹ̀, ó sì yọ́ wọ inú ibi tí ó sùn, nígbà tí ó ti sùn fọnfọn, nígbà náà ni ó kan ìṣó náà mọ́ òkè ìpéǹpéjú rẹ̀, ó sì wọlé ṣinṣin, ó sì kú. Nígbà tí Baraki dé bí ó ti ń lépa Sisera, Jaeli láti pàdé rẹ̀, wá, èmi yóò fi ẹni tí ìwọ ń wá hàn ọ́, báyìí ni ó tẹ̀lé e wọ inú àgọ́ lọ, kíyèsi Sisera dùbúlẹ̀ síbẹ̀ pẹ̀lú ìṣó àgọ́ ní agbárí rẹ̀ tí a ti kàn mọ́lẹ̀ ṣinṣin tí ó sì ti kú. Ní ọjọ́ náà ni Ọlọ́run ṣẹ́gun Jabini ọba àwọn ará Kenaani ní iwájú àwọn ẹ̀yà Israẹli. Ọwọ́ àwọn ọmọ Israẹli sì le, ó sì ń lágbára síwájú àti síwájú sí i lára Jabini ọba Kenaani, títí wọ́n fi run òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀.