A. Oni 4:14-16
A. Oni 4:14-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
Debora si wi fun Baraki pe, Dide; nitoripe oni li ọjọ́ ti OLUWA fi Sisera lé ọ lọwọ: OLUWA kò ha ti ṣaju rẹ lọ bi? Bẹ̃ni Baraki sọkalẹ lati òke Tabori lọ, ẹgba marun ọkunrin si tẹle e lẹhin. OLUWA si fi oju idà ṣẹgun Sisera, ati gbogbo kẹkẹ́ rẹ̀, ati gbogbo ogun rẹ̀, niwaju Baraki; Sisera si sọkalẹ kuro li ori kẹkẹ́ rẹ̀, o si fi ẹsẹ̀ rẹ̀ sálọ. Ṣugbọn Baraki lepa awọn kẹkẹ́, ati ogun na, titi dé Haroṣeti awọn orilẹ-ède: gbogbo ogun Sisera si ti oju idà ṣubu; ọkunrin kanṣoṣo kò si kù.
A. Oni 4:14-16 Yoruba Bible (YCE)
Debora wí fún Baraki pé, “Dìde nítorí pé òní ni ọjọ́ tí OLUWA yóo fi Sisera lé ọ lọ́wọ́. Ṣebí OLUWA ni ó ń ṣáájú ogun rẹ lọ?” Baraki bá sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè Tabori pẹlu ẹgbaarun (10,000) ọmọ ogun lẹ́yìn rẹ̀. OLUWA mú ìdàrúdàpọ̀ bá Sisera ati gbogbo kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ níwájú Baraki. Bí àwọn ọmọ ogun Baraki ti ń fi idà pa wọ́n, Sisera sọ̀kalẹ̀ ninu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ. Baraki lépa àwọn kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ọmọ ogun Sisera títí dé Haroṣeti-ha-goimu, wọ́n sì fi idà pa àwọn ọmọ ogun Sisera láìku ẹyọ ẹnìkan.
A. Oni 4:14-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Debora sì wí fún Baraki pé, “Lọ! Lónìí ni OLúWA fi Sisera lé ọ lọ́wọ́, OLúWA ti lọ síwájú rẹ.” Baraki sì síwájú, àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá sì tẹ̀lé e lẹ́yìn, wọ́n sì kọjá sí òkè Tabori. OLúWA sì mú ìdàrúdàpọ̀ wá sí àárín ogun Sisera, OLúWA sì fi ojú idà ṣẹ́gun Sisera àti àwọn oníkẹ̀kẹ́ ogun àti ọmọ-ogun orí ilẹ̀ ní iwájú Baraki. Sisera sì sọ̀kalẹ̀ lórí kẹ̀kẹ́-ẹṣin rẹ̀ ó sì fi ẹsẹ̀ sálọ. Baraki àti àwọn ogun rẹ̀ sì lé àwọn ọ̀tá náà, àwọn ọmọ-ogun orílẹ̀ àti àwọn kẹ̀kẹ́ ogun wọn títí dé Haroseti ti àwọn orílẹ̀-èdè, gbogbo ogun Sisera sì ti ojú idà ṣubú, kò sí ọ̀kan tí ó lè sálà tàbí tí ó wà láààyè.