Jak 5:1-5
Jak 5:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ wá nísinsin yìí, ẹ̀yin ọlọ́rọ̀, ẹ máa sọkún kí ẹ sì máa pohùnréré ẹkún nítorí òsì tí ó ń bọ̀ wá ta yín. Ọrọ̀ yín díbàjẹ́, kòkòrò sì ti jẹ aṣọ yín. Wúrà òun fàdákà yín díbàjẹ́; ìbàjẹ́ wọn ni yóò sì ṣe ẹlẹ́rìí sí yín, tí yóò sì jẹ ẹran-ara yín bí iná. Ẹ̀yin tí kó ìṣúra jọ de ọjọ́ ìkẹyìn. Kíyèsi i, ọ̀yà àwọn alágbàṣe tí wọ́n ti ṣe ìkórè oko yín, èyí tí ẹ kò san, ń ké rara; àti igbe àwọn tí ó ṣe ìkórè sì ti wọ inú etí Olúwa àwọn ọmọ-ogun. Ẹ̀yin ti jẹ adùn ní ayé, ẹ̀yin sì ti fi ara yín fún ayé jíjẹ; ẹ̀yin ti mú ara yín sanra de ọjọ́ pípa.
Jak 5:1-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ wá nisisiyi, ẹnyin ọlọrọ̀, ẹ mã sọkun ki ẹ si mã pohunréré ẹkun nitori òṣi ti mbọ̀wá ta nyin. Ọrọ̀ nyin dibajẹ, kòkoro si ti jẹ̀ aṣọ nyin. Wura on fadaka nyin diparà; iparà wọn ni yio si ṣe ẹlẹri si nyin, ti yio si jẹ ẹran ara nyin bi iná. Ẹnyin ti kó iṣura jọ dè ọjọ ikẹhin. Kiyesi i, ọ̀ya awọn alagbaṣe ti nwọn ti ṣe ikore oko nyin, eyiti ẹ kò san, nke rara; ati igbe awọn ti o ṣe ikore si ti wọ inu eti Oluwa awọn ọmọ-ogun. Ẹnyin ti jẹ adùn li aiye, ẹnyin si ti fi ara nyin fun aiye jijẹ; ẹnyin ti bọ́ li ọjọ pipa.
Jak 5:1-5 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọlọ́rọ̀. Ẹ máa sọkún, kí ẹ sì máa ké gidi nítorí ìṣẹ́ tí ó ń bọ̀ wá ṣẹ́ yín. Ọrọ̀ yín ti bàjẹ́. Kòkòrò ti jẹ gbogbo aṣọ yín. Wúrà yín ati fadaka yín ti dógùn-ún. Dídógùn-ún wọn ni yóo jẹ́ ẹ̀rí fun yín, nítorí yóo jẹ ara yín bí ìgbà tí iná bá ń jó nǹkan. Inú ayé tí ó fẹ́rẹ̀ dópin ni ẹ̀ ń to ìṣúra jọ sí! Owó iṣẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ tí wọ́n ṣiṣẹ́ ní oko yín, tí ẹ kò san fún wọn ń pariwo yín. Igbe àwọn òṣìṣẹ́ tí wọ́n ba yín kórè oko yín sì ti dé etí Oluwa Ọlọrun Olodumare. Ẹ̀ ń ṣe fàájì ninu ayé, ẹ̀ ń jẹ, ẹ̀ ń mu. Ẹ wá sanra bíi mààlúù, bẹ́ẹ̀ sì ni ọjọ́ tí wọn yóo dumbu mààlúù ló kù sí dẹ̀dẹ̀ yìí.