Jak 4:13-17
Jak 4:13-17 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ wá nisisiyi, ẹnyin tí nwipe, Loni tabi lọla awa ó lọ si ilu bayi, a o si ṣe ọdún kan nibẹ, a o si ṣòwo, a o si jère: Nigbati ẹnyin kò mọ̀ ohun ti yio hù lọla. Kili ẹmí nyin? Ikũku sá ni nyin, ti o hàn nigba diẹ, lẹhinna a si túka lọ. Eyi ti ẹ bá fi wipe, bi Oluwa ba fẹ, awa o wà lãye, a o si ṣe eyi tabi eyini. Ṣugbọn nisisiyi ẹnyin nṣeféfe ninu ifọnnu nyin: gbogbo irú iṣeféfe bẹ̃, ibi ni. Nitorina ẹniti o ba mọ̀ rere iṣe ti kò si ṣe, ẹ̀ṣẹ ni fun u.
Jak 4:13-17 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ gbọ́ ná, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń wí pé, “Lónìí, tabi lọ́la, a óo lọ sí ibi báyìí, a óo ṣe ọdún kan níbẹ̀; a óo ṣòwò, a óo sì jèrè.” Ẹ kò mọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ si yín lọ́la. Nítorí ìkùukùu ni yín, tí ó wà fún àkókò díẹ̀, lẹ́yìn náà tí kò ní sí mọ́. Ohun tí ẹ̀ bá máa wí ni pé “Bí Oluwa bá dá ẹ̀mí sí, a óo ṣe báyìí báyìí.” Ṣugbọn ẹ̀ ń lérí, ẹ̀ ń fọ́nnu; irú ìlérí báyìí kò dára. Nítorí náà, ẹni tí ó bá mọ rere í ṣe tí kò ṣe é, ẹ̀ṣẹ̀ ni ó ń gbà.
Jak 4:13-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ wá nísinsin yìí, ẹ̀yin tí ó ń wí pé, “Lónìí tàbí lọ́la àwa ó lọ sí ìlú báyìí, a ó sì ṣe ọdún kan níbẹ̀, a ó sì ṣòwò, a ó sì jèrè.” Nígbà tí ẹ̀yin kò mọ ohun tí yóò hù lọ́la. Kí ni ẹ̀mí yín? Ìkùùkuu sá à ni yín, tí ó hàn nígbà díẹ̀, lẹ́yìn náà a sì túká lọ. Èyí tí ẹ̀ bá fi wí pé, “Bí Olúwa bá fẹ́, àwa yóò wà láààyè, àwa ó sì ṣe èyí tàbí èyí i nì.” Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹ̀yin ń gbéraga nínú ìfọ́nnu yín, gbogbo irú ìfọ́nnu bẹ́ẹ̀, ibi ni. Nítorí náà ẹni tí ó bá mọ rere í ṣe tí kò sì ṣe é, ẹ̀ṣẹ̀ ni fún un.