Jak 3:5-8
Jak 3:5-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bẹ̃ pẹlu li ahọn jẹ ẹ̀ya kekere, o si nfọnnu ohun nla. Wo igi nla ti iná kekere nsun jóna! Iná si ni ahọ́n, aiye ẹ̀ṣẹ si ni: li arin awọn ẹ̀ya ara wa, li ahọn ti mba gbogbo ara jẹ́ ti o si ntinabọ ipa aiye wa; ọrun apãdi si ntinabọ on na. Nitori olukuluku ẹda ẹranko, ati ti ẹiyẹ, ati ti ejò, ati ti ohun ti mbẹ li okun, li a ntù loju, ti a si ti tù loju lati ọwọ ẹda enia wá. Ṣugbọn ahọn li ẹnikẹni kò le tù loju; ohun buburu alaigbọran ni, o kún fun oró iku ti ipa-ni.
Jak 3:5-8 Yoruba Bible (YCE)
Bẹ́ẹ̀ ni ahọ́n, ẹ̀yà ara kékeré ni, ṣugbọn ìhàlẹ̀ rẹ̀ pọ̀. Ẹ wo bírà tí iná kékeré lè dá ninu igbó ńlá! Iná ni ahọ́n. Ó kún fún àwọn nǹkan burúkú ayé yìí. Ninu àwọn ẹ̀yà ara wa, ahọ́n ni ó ń kó nǹkan ibi bá gbogbo ara. A máa mú kí gbogbo ara wá gbóná, iná ọ̀run àpáàdì ni ó túbọ̀ ń fún un ní agbára. Gbogbo ẹ̀dá pátá: ati ẹranko ni, ati ẹyẹ, ati àwọn ohun tí ń fàyà fà, ati àwọn ẹran omi, gbogbo wọn ni eniyan lè so lójú rọ̀. Ṣugbọn kò sí ẹnìkan tí ó kápá ahọ́n. Nǹkan burúkú tí ó kanpá ni, ó kún fún oró tí ó lè paniyan kíákíá.
Jak 3:5-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni ahọ́n jẹ́ ẹ̀yà kékeré, ó sì ń fọhùn ohùn ńlá. Wo igi ńlá tí iná kékeré ń sun jóná! Iná sì ni ahọ́n, ayé ẹ̀ṣẹ̀ sì ni: ní àárín àwọn ẹ̀yà ara wa, ní ahọ́n ti ń bá gbogbo ara jẹ́, tí yóò sì ti iná bọ ipa ayé wa; ọ̀run àpáàdì a sì tiná bọ òun náà. Nítorí olúkúlùkù ẹ̀dá ẹranko, àti ti ẹyẹ, àti ti ejò, àti ti ohun tí ó ń bẹ ní Òkun, ni à ń tù lójú, tí a sì ti tù lójú láti ọwọ́ ẹ̀dá ènìyàn wá. Ṣùgbọ́n ahọ́n ni ẹnikẹ́ni kò le tù lójú; ohun búburú aláìgbọ́ràn ni, ó kún fún oró ikú tí í pa ni.