Jak 3:14-18
Jak 3:14-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn bi ẹnyin ba ni owú kikorò ati ìja li ọkàn nyin, ẹ máṣe ṣeféfe, ẹ má si ṣeke si otitọ. Ọgbọ́n yi ki iṣe eyiti o ti oke sọkalẹ wá, ṣugbọn ti aiye ni, ti ara ni, ti ẹmí èṣu ni. Nitori ibiti owú on ìja bá gbé wà, nibẹ̀ ni rudurudu ati iṣẹ buburu gbogbo wà. Ṣugbọn ọgbọ́n ti o ti oke wá, a kọ́ mọ́, a si ni alafia, a ni ipamọra, kì isí iṣoro lati bẹ̀, a kún fun ãnu ati fun eso rere, li aisi ègbè, ati laisi agabagebe. Eso ododo li a ngbìn li alafia fun awọn ti nṣiṣẹ alafia.
Jak 3:14-18 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn tí ẹ bá ń jowú ara yín kíkankíkan, tí ẹ ní ọkàn ìmọ-tara-ẹni-nìkan, ẹ má máa gbéraga, kí ẹ má sì purọ́ mọ́. Èyí kì í ṣe ọgbọ́n tí ó wá láti òkè, ọgbọ́n ayé ni, gẹ́gẹ́ bíi ti ẹran-ara, ati ti ẹ̀mí burúkú. Níbi tí owú ati ìlara bá wà, ìrúkèrúdò ati oríṣìíríṣìí ìwà burúkú a máa wà níbẹ̀. Ṣugbọn ní àkọ́kọ́, ọgbọ́n tí ó ti òkè wá jẹ́ pípé, lẹ́yìn náà a máa mú alaafia wá, a máa ṣe ẹ̀tọ́, a máa ro ọ̀rọ̀ dáradára, a máa ṣàánú; a máa so èso rere, kì í ṣe ẹnu meji, kì í ṣe àgàbàgebè. Àwọn tí wọn bá ń fúnrúgbìn ire pẹlu alaafia yóo kórè alaafia.
Jak 3:14-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá ní owú kíkorò àti ìjà ní ọkàn yín, ẹ má ṣe ṣe féfé, ẹ má sì ṣèké sí òtítọ́. Ọgbọ́n yìí kì í ṣe èyí tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, ṣùgbọ́n ti ayé ni, ti ara ni, ti ẹ̀mí èṣù ni. Nítorí níbi tí owú òun ìjà bá gbé wà, níbẹ̀ ni rúdurùdu àti iṣẹ́ búburú gbogbo wà. Ṣùgbọ́n ọgbọ́n tí ó ti òkè wá jẹ́ mímọ́ ní àkọ́kọ́, ti àlàáfíà, àti ti ìrẹ̀lẹ̀, kì í sì í ṣòro láti bẹ̀, ó kún fún àánú àti fún èso rere, kì í ṣe ojúsàájú, a sì máa sọ òtítọ́. Àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ àlàáfíà a sì máa gbin èso àlàáfíà ní àlàáfíà.