Jak 3:1-18

Jak 3:1-18 Bibeli Mimọ (YBCV)

ẸNYIN ará mi, ẹ máṣe jẹ olukọni pipọ, ki ẹnyin ki o mọ̀ pe awa ni yio jẹbi ju. Nitori ninu ohun pipọ ni gbogbo wa nṣì i ṣe. Bi ẹnikan kò ba ṣì i ṣe ninu ọ̀rọ, on na li ẹni pipé, on li o si le kó gbogbo ara ni ijanu. Bi a bá si fi ijanu bọ̀ ẹṣin li ẹnu, ki nwọn ki o le gbọ́ ti wa, gbogbo ara wọn li awa si nyi kiri pẹlu. Kiyesi awọn ọkọ̀ pẹlu, bi nwọn ti tobi to nì, ti a si nti ọwọ ẹfũfu lile gbá kiri, itọkọ̀ kekere li a fi ndari wọn kiri, sibikibi ti o bá wù ẹniti ntọ́ ọkọ̀. Bẹ̃ pẹlu li ahọn jẹ ẹ̀ya kekere, o si nfọnnu ohun nla. Wo igi nla ti iná kekere nsun jóna! Iná si ni ahọ́n, aiye ẹ̀ṣẹ si ni: li arin awọn ẹ̀ya ara wa, li ahọn ti mba gbogbo ara jẹ́ ti o si ntinabọ ipa aiye wa; ọrun apãdi si ntinabọ on na. Nitori olukuluku ẹda ẹranko, ati ti ẹiyẹ, ati ti ejò, ati ti ohun ti mbẹ li okun, li a ntù loju, ti a si ti tù loju lati ọwọ ẹda enia wá. Ṣugbọn ahọn li ẹnikẹni kò le tù loju; ohun buburu alaigbọran ni, o kún fun oró iku ti ipa-ni. On li awa fi nyìn Oluwa ati Baba, on li a si fi mbú enia, ti a dá li aworan Ọlọrun. Lati ẹnu kanna ni iyìn ati ẽbú ti njade. Ẹnyin ará mi, nkan wọnyi kò yẹ ki o ri bẹ̃. Orisun a ha mã sun omi tutù ati omiró jade lati ojusun kanna wá bi? Ẹnyin ará mi, igi ọpọtọ ha le so eso olifi bi? tabi ajara le so eso ọpọtọ? bẹ̃li orisun kan kò le sun omiró ati omi tutù. Tali o gbọ́n ti o si ni imọ̀ ninu nyin? ẹ jẹ ki o fi iṣẹ rẹ̀ hàn nipa ìwa rere, nipa ìwa tutù ti ọgbọn. Ṣugbọn bi ẹnyin ba ni owú kikorò ati ìja li ọkàn nyin, ẹ máṣe ṣeféfe, ẹ má si ṣeke si otitọ. Ọgbọ́n yi ki iṣe eyiti o ti oke sọkalẹ wá, ṣugbọn ti aiye ni, ti ara ni, ti ẹmí èṣu ni. Nitori ibiti owú on ìja bá gbé wà, nibẹ̀ ni rudurudu ati iṣẹ buburu gbogbo wà. Ṣugbọn ọgbọ́n ti o ti oke wá, a kọ́ mọ́, a si ni alafia, a ni ipamọra, kì isí iṣoro lati bẹ̀, a kún fun ãnu ati fun eso rere, li aisi ègbè, ati laisi agabagebe. Eso ododo li a ngbìn li alafia fun awọn ti nṣiṣẹ alafia.

Jak 3:1-18 Yoruba Bible (YCE)

Ẹ̀yin ará mi, kí ọpọlọpọ yín má máa jìjàdù láti jẹ́ olùkọ́ni, kí ẹ mọ̀ pé ìdájọ́ ti àwa olùkọ́ni yóo le. Nítorí gbogbo wa ni à ń ṣe àṣìṣe ní ọ̀pọ̀ ìgbà. Bí ẹnikẹ́ni bá wà tí kò ṣi ọ̀rọ̀ sọ rí, a jẹ́ pé olúwarẹ̀ pé, ó lè kó gbogbo ara rẹ̀ níjàánu. Tí a bá fi ìjánu sí ẹṣin lẹ́nu, kí wọ́n lè ṣe bí a ti fẹ́, a máa darí gbogbo ara wọn bí a bá ti fẹ́. Bí àpẹẹrẹ, ẹ wo àwọn ọkọ̀ ojú omi. Bí wọ́n ti tóbi tó, tí ó jẹ́ pé afẹ́fẹ́ líle ní ń gbé wọn kiri, sibẹ ìtukọ̀ kékeré ni ọ̀gá àwọn atukọ̀ fi ń darí wọn sí ibi tí ó bá fẹ́. Bẹ́ẹ̀ ni ahọ́n, ẹ̀yà ara kékeré ni, ṣugbọn ìhàlẹ̀ rẹ̀ pọ̀. Ẹ wo bírà tí iná kékeré lè dá ninu igbó ńlá! Iná ni ahọ́n. Ó kún fún àwọn nǹkan burúkú ayé yìí. Ninu àwọn ẹ̀yà ara wa, ahọ́n ni ó ń kó nǹkan ibi bá gbogbo ara. A máa mú kí gbogbo ara wá gbóná, iná ọ̀run àpáàdì ni ó túbọ̀ ń fún un ní agbára. Gbogbo ẹ̀dá pátá: ati ẹranko ni, ati ẹyẹ, ati àwọn ohun tí ń fàyà fà, ati àwọn ẹran omi, gbogbo wọn ni eniyan lè so lójú rọ̀. Ṣugbọn kò sí ẹnìkan tí ó kápá ahọ́n. Nǹkan burúkú tí ó kanpá ni, ó kún fún oró tí ó lè paniyan kíákíá. Ahọ́n ni a fi ń yin Oluwa ati Baba. Òun kan náà ni a fi ń ṣépè fún eniyan tí a dá ní àwòrán Ọlọrun. Láti inú ẹnu kan náà ni ìyìn ati èpè ti ń jáde. Ẹ̀yin ará mi, kò yẹ kí èyí rí bẹ́ẹ̀. Ǹjẹ́ omi dídùn ati omi kíkorò lè ti inú orísun omi kan náà jáde? Ẹ̀yin ará mi, ṣé igi ọ̀pọ̀tọ́ lè so èso olifi, tabi kí àjàrà kó so ọ̀pọ̀tọ́? Ìsun omi kíkorò kò lè mú omi dídùn jáde. Ẹnikẹ́ni wà láàrin yín tí ó gbọ́n, tí ó tún mòye? Kí ó fihàn nípa ìgbé-ayé rere ati ìwà ìrẹ̀lẹ̀ tí ó fi ọgbọ́n hàn. Ṣugbọn tí ẹ bá ń jowú ara yín kíkankíkan, tí ẹ ní ọkàn ìmọ-tara-ẹni-nìkan, ẹ má máa gbéraga, kí ẹ má sì purọ́ mọ́. Èyí kì í ṣe ọgbọ́n tí ó wá láti òkè, ọgbọ́n ayé ni, gẹ́gẹ́ bíi ti ẹran-ara, ati ti ẹ̀mí burúkú. Níbi tí owú ati ìlara bá wà, ìrúkèrúdò ati oríṣìíríṣìí ìwà burúkú a máa wà níbẹ̀. Ṣugbọn ní àkọ́kọ́, ọgbọ́n tí ó ti òkè wá jẹ́ pípé, lẹ́yìn náà a máa mú alaafia wá, a máa ṣe ẹ̀tọ́, a máa ro ọ̀rọ̀ dáradára, a máa ṣàánú; a máa so èso rere, kì í ṣe ẹnu meji, kì í ṣe àgàbàgebè. Àwọn tí wọn bá ń fúnrúgbìn ire pẹlu alaafia yóo kórè alaafia.

Jak 3:1-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ẹ̀yin ará mi, ẹ má ṣe jẹ́ kí púpọ̀ nínú yín jẹ́ olùkọ́, kí ẹ̀yin kí ó mọ̀ pé àwa ni yóò jẹ̀bi jù. Nítorí nínú ohun púpọ̀ ni gbogbo wa ń ṣe àṣìṣe. Bí ẹnìkan kò bá ṣì ṣe nínú ọ̀rọ̀, òun náà ni ẹni pípé, òun ni ó sì le kó gbogbo ara ní ìjánu. Bí a bá sì fi ìjánu bọ ẹṣin lẹ́nu, kí wọn kí ó le gbọ́ tiwa, gbogbo ara wọn ni àwa sì ń tì kiri pẹ̀lú. Kíyèsi i, àwọn ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú, bí wọ́n ti tóbi tó nì, tí a sì ń ti ọwọ́ ẹ̀fúùfù líle gbá kiri, ìtọ́kọ̀ kékeré ni a fi ń darí wọn kiri, síbikíbi tí ó bá wu ẹni tí ó ń tọ́ ọkọ̀. Bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni ahọ́n jẹ́ ẹ̀yà kékeré, ó sì ń fọhùn ohùn ńlá. Wo igi ńlá tí iná kékeré ń sun jóná! Iná sì ni ahọ́n, ayé ẹ̀ṣẹ̀ sì ni: ní àárín àwọn ẹ̀yà ara wa, ní ahọ́n ti ń bá gbogbo ara jẹ́, tí yóò sì ti iná bọ ipa ayé wa; ọ̀run àpáàdì a sì tiná bọ òun náà. Nítorí olúkúlùkù ẹ̀dá ẹranko, àti ti ẹyẹ, àti ti ejò, àti ti ohun tí ó ń bẹ ní Òkun, ni à ń tù lójú, tí a sì ti tù lójú láti ọwọ́ ẹ̀dá ènìyàn wá. Ṣùgbọ́n ahọ́n ni ẹnikẹ́ni kò le tù lójú; ohun búburú aláìgbọ́ràn ni, ó kún fún oró ikú tí í pa ni. Òun ni àwa fi ń yin Olúwa àti Baba, òun ni a sì fi ń bú ènìyàn tí a dá ní àwòrán Ọlọ́run. Láti ẹnu kan náà ni ìyìn àti èébú ti ń jáde. Ẹ̀yin ará mi, nǹkan wọ̀nyí kò yẹ kí ó rí bẹ́ẹ̀. Orísun odò kan a ha máa sun omi dídára àti omi iyọ̀ jáde láti orísun kan náà bí? Ẹ̀yin ará mi, igi ọ̀pọ̀tọ́ ha le so èso olifi bí? Tàbí àjàrà ha lè so èso ọ̀pọ̀tọ́? Bẹ́ẹ̀ ni orísun kan kò le sun omíró àti omi tútù. Ta ni ó gbọ́n tí ó sì ní ìmọ̀ nínú yín? Ẹ jẹ́ kí ó fi iṣẹ́ rẹ̀ hàn nípa ìwà rere, nípa ìwà tútù ti ọgbọ́n. Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá ní owú kíkorò àti ìjà ní ọkàn yín, ẹ má ṣe ṣe féfé, ẹ má sì ṣèké sí òtítọ́. Ọgbọ́n yìí kì í ṣe èyí tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, ṣùgbọ́n ti ayé ni, ti ara ni, ti ẹ̀mí èṣù ni. Nítorí níbi tí owú òun ìjà bá gbé wà, níbẹ̀ ni rúdurùdu àti iṣẹ́ búburú gbogbo wà. Ṣùgbọ́n ọgbọ́n tí ó ti òkè wá jẹ́ mímọ́ ní àkọ́kọ́, ti àlàáfíà, àti ti ìrẹ̀lẹ̀, kì í sì í ṣòro láti bẹ̀, ó kún fún àánú àti fún èso rere, kì í ṣe ojúsàájú, a sì máa sọ òtítọ́. Àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ àlàáfíà a sì máa gbin èso àlàáfíà ní àlàáfíà.