Jak 2:10-13
Jak 2:10-13 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí ẹni tí ó bá pa gbogbo òfin mọ́, ṣugbọn tí ó rú ẹyọ kan ṣoṣo, ó jẹ̀bi gbogbo òfin. Nítorí ẹnìkan náà tí ó wí pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe àgbèrè,” òun náà ni ó wí pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ paniyan.” Bí o kò bá ṣe àgbèrè ṣugbọn o paniyan, o ti di arúfin. Ẹ máa sọ̀rọ̀, kí ẹ sì máa hùwà gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó wà lábẹ́ ìdájọ́ òfin tí ó ń sọ eniyan di òmìnira. Nítorí kò ní sí àánú ninu ìdájọ́ fún àwọn tí kò ní ojú àánú, bẹ́ẹ̀ sì ni àánú ló borí ìdájọ́.
Jak 2:10-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá pa gbogbo òfin mọ́, tí ó sì rú ọ̀kan, ó jẹ̀bi rírú gbogbo rẹ̀. Nítorí ẹni tí ó wí pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà,” òun ni ó sì wí pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn.” Ǹjẹ́ bí ìwọ kò ṣe panṣágà, ṣùgbọ́n tí ìwọ pànìyàn, ìwọ jásí arúfin. Ẹ máa sọ̀rọ̀, ẹ sì máa hùwà, bí àwọn tí a ó fi òfin òmìnira dá lẹ́jọ́. Nítorí ẹni tí kò ṣàánú, ni a ó ṣe ìdájọ́ fún láìsí àánú; àánú ń ṣògo lórí ìdájọ́.
Jak 2:10-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori ẹnikẹni ti o ba pa gbogbo ofin mọ́, ti o si rú ọ̀kan, o jẹbi gbogbo rẹ̀. Nitori ẹniti o wipe, Máṣe ṣe panṣaga, on li o si wipe, Máṣe pania. Njẹ bi iwọ kò ṣe panṣaga, ṣugbọn ti iwọ pania, iwọ di arufin. Ẹ mã sọrọ bẹ̃, ẹ si mã huwa bẹ̃, bi awọn ti a o fi ofin omnira dá li ẹjọ. Nitori ẹniti kò ṣãnu, li a o ṣe idajọ fun laisi ãnu; ãnu nṣogo lori idajọ.