Jak 2:1-26

Jak 2:1-26 Bibeli Mimọ (YBCV)

ẸNYIN ará mi, ẹ máṣe fi iṣãju enia dì igbagbọ́ Oluwa wa Jesu Kristi Oluwa ogo mu. Nitori bi ọkunrin kan ba wá si ajọ nyin, pẹlu oruka wura, ati aṣọ daradara, ti talakà kan si wá pẹlu li aṣọ ẽri; Ti ẹnyin si bu iyìn fun ẹniti o wọ̀ aṣọ daradara, ti ẹ si wipe, Iwọ joko nihinyi ni ibi daradara; ti ẹ si wi fun talakà na pe, Iwọ duro nibẹ̀, tabi joko nihin labẹ apoti itisẹ mi: Ẹnyin kò ha nda ara nyin si meji ninu ara nyin, ẹ kò ha si di onidajọ ti o ni ero buburu? Ẹ fi etí silẹ, ẹnyin ará mi olufẹ, Ọlọrun kò ha ti yàn awọn talakà aiye yi ṣe ọlọrọ̀ ni igbagbọ́, ati ajogun ijọba na, ti o ti ṣe ileri fun awọn ti o fẹ ẹ? Ṣugbọn ẹnyin ti bù talakà kù. Awọn ọlọrọ̀ kò ha npọ́n nyin loju, nwọn kò ha si nwọ́ nyin lọ si ile ẹjọ? Nwọn kò ha nsọ ọrọ-odi si orukọ rere nì ti a fi npè nyin? Ṣugbọn bi ẹnyin ba nmu olú ofin nì ṣẹ gẹgẹ bi iwe-mimọ́, eyini ni, Iwọ fẹ ẹnikeji rẹ bi ara rẹ, ẹnyin nṣe daradara. Ṣugbọn bi ẹnyin ba nṣe ojuṣãju enia, ẹnyin ndẹ̀ṣẹ, a si nda nyin lẹbi nipa ofin bi arufin. Nitori ẹnikẹni ti o ba pa gbogbo ofin mọ́, ti o si rú ọ̀kan, o jẹbi gbogbo rẹ̀. Nitori ẹniti o wipe, Máṣe ṣe panṣaga, on li o si wipe, Máṣe pania. Njẹ bi iwọ kò ṣe panṣaga, ṣugbọn ti iwọ pania, iwọ di arufin. Ẹ mã sọrọ bẹ̃, ẹ si mã huwa bẹ̃, bi awọn ti a o fi ofin omnira dá li ẹjọ. Nitori ẹniti kò ṣãnu, li a o ṣe idajọ fun laisi ãnu; ãnu nṣogo lori idajọ. Ere kili o jẹ, ará mi, bi ẹnikan wipe on ni igbagbọ́, ṣugbọn ti kò ni iṣẹ? igbagbọ́ nì le gbà a là bi? Bi arakunrin tabi arabinrin kan ba wà ni ìhoho, ti o si ṣe aili onjẹ õjọ, Ti ẹnikan ninu nyin si wi fun wọn pe, Ẹ mã lọ li alafia, ki ara nyin ki o maṣe tutu, ki ẹ si yó; ṣugbọn ẹ kò fi nkan wọnni ti ara nfẹ fun wọn; ère kili o jẹ? Bẹ̃ si ni igbagbọ́, bi kò ba ni iṣẹ, o kú ninu ara. Ṣugbọn ẹnikan le wipe, Iwọ ni igbagbọ́, emi si ni iṣẹ: fi igbagbọ́ rẹ hàn mi li aisi iṣẹ, emi o si fi igbagbọ́ mi hàn ọ nipa iṣẹ mi. Iwọ gbagbọ́ pe Ọlọrun kan ni mbẹ; o dara: awọn ẹmí èṣu pẹlu gbagbọ́, nwọn si warìri. Ṣugbọn, iwọ alaimoye enia, iwọ ha fẹ mọ̀ pe, igbagbọ́ li aisi iṣẹ asan ni? Kì ha iṣe nipa iṣẹ li a dá Abrahamu baba wa lare, nigbati o fi Isaaki ọmọ rẹ̀ rubọ lori pẹpẹ? Iwọ ri pe igbagbọ́ bá iṣẹ rẹ̀ rìn, ati pe nipa iṣẹ li a sọ igbagbọ́ di pipé. Iwe-mimọ́ si ṣẹ ti o wipe, Abrahamu gbà Ọlọrun gbọ́, a si kà a si ododo fun u: a si pè e li ọ̀rẹ́ Ọlọrun. Njẹ ẹnyin ri pe nipa iṣẹ li a ndá enia lare, kì iṣe nipa igbagbọ́ nikan. Gẹgẹ bẹ̃ pẹlu kí a ha dá Rahabu panṣaga lare nipa iṣẹ, nigbati o gbà awọn onṣẹ, ti o si rán wọn jade gba ọ̀na miran? Nitori bi ara li aisi ẹmí ti jẹ́ okú, bẹ̃ gẹgẹ pẹlu ni igbagbọ́ li aisi iṣẹ jẹ́ okú.

Jak 2:1-26 Yoruba Bible (YCE)

Ẹ̀yin ará mi, níwọ̀n ìgbà tí ẹ ní igbagbọ ninu Oluwa wa, Jesu Kristi, Oluwa tí ó lógo, ẹ má máa ṣe ojuṣaaju. Bí àpẹẹrẹ, bí ẹnìkan bá wọ àwùjọ yín, tí ó fi òrùka wúrà sọ́wọ́, tí ó wọ aṣọ tí ń dán, tí talaka kan náà bá wọlé tí ó wọ aṣọ tí ó dọ̀tí; ẹ óo máa fi ojurere wo ẹni tí ó wọ aṣọ dídán, ẹ óo sọ fún un pé, “Wá jókòó níbi dáradára yìí.” Ṣugbọn ẹ óo wá sọ fún talaka pé, “Dúró níbẹ̀, tabi wá jókòó nílẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ mi níhìn-ín.” Ǹjẹ́ ẹ kò fi bẹ́ẹ̀ dá ìyapa sílẹ̀ láàrin ara yín, ǹjẹ́ ẹ kò sì máa ṣe ìdájọ́ pẹlu èrò burúkú. Ẹ fi etí sílẹ̀, ẹ̀yin ará mi olùfẹ́. Ọlọrun ti yan àwọn mẹ̀kúnnù ayé yìí láti jẹ́ ọlọ́rọ̀ ninu igbagbọ ati láti jogún ìjọba tí ó ti ṣe ìlérí fún àwọn tí ó fẹ́ràn rẹ̀. Ṣugbọn ẹ̀ ń kẹ́gàn mẹ̀kúnnù. Ṣebí àwọn ọlọ́rọ̀ níí máa fìtínà yín, tí wọn máa ń fà yín lọ sí kóòtù! Ṣebí àwọn ni wọ́n máa ń sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí orúkọ rere tí a fi ń pè yín! Ẹ̀ ń ṣe dáradára tí ẹ bá pa òfin ìjọba Ọlọrun mọ́, gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti sọ pé, “Ìwọ fẹ́ràn ọmọnikeji rẹ bí o ti fẹ́ràn ara rẹ.” Ṣugbọn tí ẹ bá ń ṣe ojuṣaaju, ẹ di arúfin, ati ẹni ìbáwí lábẹ́ òfin gẹ́gẹ́ bí arúfin. Nítorí ẹni tí ó bá pa gbogbo òfin mọ́, ṣugbọn tí ó rú ẹyọ kan ṣoṣo, ó jẹ̀bi gbogbo òfin. Nítorí ẹnìkan náà tí ó wí pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe àgbèrè,” òun náà ni ó wí pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ paniyan.” Bí o kò bá ṣe àgbèrè ṣugbọn o paniyan, o ti di arúfin. Ẹ máa sọ̀rọ̀, kí ẹ sì máa hùwà gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó wà lábẹ́ ìdájọ́ òfin tí ó ń sọ eniyan di òmìnira. Nítorí kò ní sí àánú ninu ìdájọ́ fún àwọn tí kò ní ojú àánú, bẹ́ẹ̀ sì ni àánú ló borí ìdájọ́. Ẹ̀yin ará mi, èrè kí ni ó jẹ́, tí ẹnìkan bá sọ pé òun ní igbagbọ, ṣugbọn tí igbagbọ yìí kò hàn ninu iṣẹ́ rẹ̀? Ṣé igbagbọ yìí lè gbà á là? Bí arakunrin kan tabi arabinrin kan bá wà ní ìhòòhò, tí kò jẹun fún odidi ọjọ́ kan, tí ẹnìkan ninu yín wá sọ fún un pé, “Máa lọ ní alaafia, Ọlọrun yóo pèsè aṣọ ati oúnjẹ fún ọ,” ṣugbọn tí kò fún olúwarẹ̀ ní ohun tí ó nílò, anfaani wo ni ọ̀rọ̀ tí ó sọ ṣe? Bẹ́ẹ̀ gan-an ni igbagbọ tí kò bá ní iṣẹ́: òkú ni. Ṣugbọn ẹnìkan lè sọ pé, “Ìwọ ní igbagbọ, èmi ní iṣẹ́.” Fi igbagbọ rẹ hàn mí láìsí iṣẹ́, èmi óo fi igbagbọ mi hàn ọ́ nípa iṣẹ́ mi. Ìwọ gbàgbọ́ pé Ọlọrun kan ní ń bẹ. Ó dára bẹ́ẹ̀. Àwọn ẹ̀mí èṣù pàápàá gbàgbọ́ bẹ́ẹ̀, ìbẹ̀rùbojo sì mú wọn. Ìwọ eniyan lásán! O fẹ́ ẹ̀rí pé igbagbọ ti kò ní iṣẹ́ ninu jẹ́ òkú? Nípa iṣẹ́ kọ́ ni Abrahamu baba wa fi gba ìdáláre, nígbà tí ó fa Isaaki ọmọ rẹ̀ lọ sí orí pẹpẹ ìrúbọ? O rí i pé igbagbọ ń farahàn ninu iṣẹ́ rẹ̀, ati pé iṣẹ́ rẹ̀ ni ó ṣe igbagbọ rẹ̀ ní àṣepé. Èyí ni ó mú kí Ìwé Mímọ́ ṣẹ tí ó sọ pé, “Abrahamu gba Ọlọrun gbọ́, Ọlọrun sì kà á sí olódodo.” A wá pè é ní ọ̀rẹ́ Ọlọrun. Ṣé ẹ wá rí i pé nípa iṣẹ́ ni eniyan fi ń gba ìdáláre, kì í ṣe nípa igbagbọ nìkan? Ṣebí bákan náà ni Rahabu aṣẹ́wó gba ìdáláre nípa iṣẹ́, nígbà tí ó ṣe àwọn amí ní àlejò, tí ó jẹ́ kí wọ́n bá ọ̀nà mìíràn pada lọ? Bí ara láìsí ẹ̀mí ti jẹ́ òkú, bẹ́ẹ̀ ni igbagbọ láìsí iṣẹ́.

Jak 2:1-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ẹ̀yin ará mi, gẹ́gẹ́ bí onígbàgbọ́ nínú ògo Olúwa wá Jesu Kristi, ẹ máa ṣe ojúsàájú ẹnikẹ́ni. Nítorí bí ọkùnrin kan bá wá sí ìpéjọpọ̀ yín, pẹ̀lú òrùka wúrà àti aṣọ dáradára, tí tálákà kan sì wá pẹ̀lú nínú aṣọ èérí; tí ẹ̀yin sì bu ọlá fún ẹni tí ó wọ aṣọ dáradára tí ẹ sì wí pé, “Ìwọ jókòó níhìn-ín yìí ní ibi dáradára” tí ẹ sì wí fún tálákà náà pé, “Ìwọ dúró níbẹ̀” tàbí “jókòó níhìn-ín lábẹ́ àpótí ìtìsẹ̀ mi,” ẹyin kò ha ń dá ara yín sí méjì nínú ara yín, ẹ̀yin kò sì di onídàájọ́ tí ó ní èrò búburú bí? Ẹ fi etí sílẹ̀, ẹ̀yin ará mi olùfẹ́: Ọlọ́run kò ha ti yan àwọn tálákà ayé yìí láti jẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú ìgbàgbọ́, àti ajogún ìjọba náà, tí ó ti ṣe ìlérí fún àwọn tí ó fẹ́ ẹ? Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti bu tálákà kù. Àwọn ọlọ́rọ̀ kò ha ń pọ́n yin lójú bí; wọn kò ha sì ń wọ́ yín lọ sílé ẹjọ́? Wọn kò ha ń sọ ọ̀rọ̀-òdì sí orúkọ rere nì tí a fi ń pè yín bí? Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá ń mú olú òfin nì ṣẹ gẹ́gẹ́ bí Ìwé mímọ́, èyí tí ó wí pé, “Ìwọ fẹ́ ẹni kejì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ,” ẹ̀yin ń ṣe dáradára. Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá ń ṣe ojúsàájú ènìyàn, ẹ̀yin ń dẹ́ṣẹ̀, a sì ń dá yín lẹ́bi nípa òfin bí arúfin. Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá pa gbogbo òfin mọ́, tí ó sì rú ọ̀kan, ó jẹ̀bi rírú gbogbo rẹ̀. Nítorí ẹni tí ó wí pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà,” òun ni ó sì wí pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn.” Ǹjẹ́ bí ìwọ kò ṣe panṣágà, ṣùgbọ́n tí ìwọ pànìyàn, ìwọ jásí arúfin. Ẹ máa sọ̀rọ̀, ẹ sì máa hùwà, bí àwọn tí a ó fi òfin òmìnira dá lẹ́jọ́. Nítorí ẹni tí kò ṣàánú, ni a ó ṣe ìdájọ́ fún láìsí àánú; àánú ń ṣògo lórí ìdájọ́. Èrè kí ni ó jẹ́, ará mi, bí ẹni kan wí pé òun ní ìgbàgbọ́, ṣùgbọ́n tí kò ní àwọn iṣẹ́ láti fihan? Ìgbàgbọ́ náà lè gbà á là bí? Bí arákùnrin tàbí arábìnrin kan bá wà ní àìní aṣọ, tí ó sì ṣe àìní oúnjẹ òòjọ́, Tí ẹni kan nínú yín sì wí fún pé, “Máa lọ ní àlàáfíà, kí ara rẹ kí ó má ṣe tutù, kí ó sì yó,” ṣùgbọ́n ẹ kò fi nǹkan wọ̀n-ọn-nì ti ara ń fẹ́ fún wọn; èrè kí ni ó jẹ́? Bẹ́ẹ̀ sì ni ìgbàgbọ́, bí kò bá ní iṣẹ́ rere, ó kú nínú ara rẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹnìkan lè wí pé, “Ìwọ ní ìgbàgbọ́, èmi sì ní iṣẹ́:” Fi ìgbàgbọ́ rẹ hàn mí ní àìsí iṣẹ́, èmi ó sì fi ìgbàgbọ́ mi hàn ọ́ nípa iṣẹ́ rere mi. Ìwọ gbàgbọ́ pé Ọlọ́run kan ní ó ń bẹ; ó dára! Àwọn ẹ̀mí èṣù pẹ̀lú gbàgbọ́ bẹ́ẹ̀, wọ́n sì wárìrì. Ṣùgbọ́n, ìwọ aláìmòye ènìyàn, ìwọ ha fẹ́ ní ìdánilójú pé, ìgbàgbọ́ ní àìsí iṣẹ́ rere asán ni? Kí ha í ṣe nípa iṣẹ́ ni a dá Abrahamu baba wa láre, nígbà tí ó fi Isaaki ọmọ rẹ̀ rú ẹbọ lórí pẹpẹ? Ìwọ rí i pé ìgbàgbọ́ rẹ bá iṣẹ́ rìn, àti pé nípa iṣẹ́ rere ni a sọ ìgbàgbọ́ di pípé. Ìwé Mímọ́ sì ṣẹ́ tí ó wí pé, “Abrahamu gba Ọlọ́run gbọ́, a sì kà á sí òdodo fún un,” a sì pè é ní ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Ǹjẹ́ ẹ̀yin rí i pé nípa iṣẹ́ rere ni à ń dá ènìyàn láre, kì í ṣe nípa ìgbàgbọ́ nìkan. Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú kí a dá Rahabu panṣágà láre nípa iṣẹ́ bí, nígbà tí ó gba àwọn ayọ́lẹ̀wò, tí ó sì rán wọn jáde gba ọ̀nà mìíràn? Nítorí bí ara ní àìsí ẹ̀mí ti jẹ́ òkú, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ pẹ̀lú ni ìgbàgbọ́ ní àìsí iṣẹ́ jẹ́ òkú.

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa