Jak 1:22-25
Jak 1:22-25 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn ki ẹ jẹ oluṣe ọ̀rọ na, ki o má si ṣe olugbọ́ nikan, ki ẹ mã tàn ara nyin jẹ. Nitori bi ẹnikan ba jẹ olugbọ́ ọ̀rọ na, ti kò si jẹ oluṣe, on dabi ọkunrin ti o nṣakiyesi oju ara rẹ̀ ninu awojiji: Nitori o ṣakiyesi ara rẹ̀, o si ba tirẹ̀ lọ, lojukanna o si gbagbé bi on ti ri. Ṣugbọn ẹniti o ba nwo inu ofin pipé, ofin omnira nì, ti o si duro ninu rẹ̀, ti on kò jẹ olugbọ́ ti ngbagbé, bikoṣe oluṣe iṣẹ, oluwarẹ̀ yio jẹ alabukun ninu iṣẹ rẹ̀.
Jak 1:22-25 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ máa fi ọ̀rọ̀ ìyìn rere ṣe ìwà hù; ẹ má kàn máa gbọ́ ọ lásán. Bí ẹ bá ń gbọ́ lásán, ara yín ni ẹ̀ ń tàn jẹ. Nítorí bí eniyan bá gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí kò fi ṣe ìwà hù, olúwarẹ̀ dàbí ẹni tí ó wo ojú ara rẹ̀ ninu dígí. Ó wo ara rẹ̀ dáradára, ó kúrò níbẹ̀, kíá ó ti gbàgbé bí ojú rẹ̀ ti rí. Ṣugbọn ẹni tí ó bá wo òfin tí ó pé, tíí ṣe orísun òmìnira, tí ó sì dúró lé e lórí, olúwarẹ̀ kì í ṣe ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ tí ó gbàgbé rẹ̀, ṣugbọn ó ń fi ọ̀rọ̀ náà ṣe ìwà hù. Olúwarẹ̀ di ẹni ibukun nítorí ó ń fi ọ̀rọ̀ tí ó gbọ́ ṣe ìwà hù.
Jak 1:22-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ má kan jẹ́ olùgbọ́ ọ̀rọ̀ náà lásán, kí ẹ má ba à ti ipa èyí tan ara yín jẹ́. Ẹ ṣe ohun tí ó sọ. Nítorí bí ẹnikẹ́ni bá jẹ́ olùgbọ́ ọ̀rọ̀ náà tí kò sì jẹ́ olùṣe, òun dàbí ọkùnrin tí ó ń ṣàkíyèsí ojú ara rẹ̀ nínú dígí Nítorí, lẹ́yìn tí ó bá ti ṣàkíyèsí ara rẹ̀, tí ó sì bá tirẹ̀ lọ, lójúkan náà òun sì gbàgbé bí òun ti rí. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń wo inú òfin pípé, òfin òmìnira ni, tí ó sì dúró nínú rẹ̀, tí òun kò sì jẹ́ olùgbọ́ tí ń gbàgbé bí kò ṣe olùṣe rẹ̀, òun yóò jẹ́ alábùkún nínú iṣẹ́ rẹ̀.