Jak 1:13-27

Jak 1:13-27 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ki ẹnikẹni ti a danwò máṣe wipe, Lati ọwọ́ Ọlọrun li a ti dán mi wò: nitori a kò le fi buburu dán Ọlọrun wò, on na kì isi idán ẹnikẹni wò: Ṣugbọn olukuluku ni a ndanwò, nigbati a ba ti ọwọ́ ifẹkufẹ ara rẹ̀ fà a lọ ti a si tàn a jẹ. Njẹ, ifẹkufẹ na nigbati o ba lóyun, a bí ẹ̀ṣẹ: ati ẹ̀ṣẹ na nigbati o ba si dagba tan, a bí ikú. Ki a má ṣe tan nyin jẹ, ẹnyin ará mi olufẹ. Gbogbo ẹ̀bun rere ati gbogbo ẹ̀bun pipé lati oke li o ti wá, o si nsọkalẹ lati ọdọ Baba imọlẹ wá, lọdọ Ẹniti kò le si iyipada tabi ojiji àyida. Nipa ifẹ ara rẹ̀ li o fi ọ̀rọ otitọ bí wa, ki awa ki o le jẹ bi akọso awọn ẹda rẹ̀. Ẹnyin mọ eyi, ẹnyin ará mi olufẹ; ṣugbọn jẹ ki olukuluku enia ki o mã yara lati gbọ́, ki o lọra lati fọhùn, ki o lọra lati binu: Nitori ibinu enia kì iṣiṣẹ ododo Ọlọrun. Nitorina ẹ fi gbogbo ẽri ati buburu aṣeleke lelẹ li apakan, ki ẹ si fi ọkàn tutù gbà ọ̀rọ na ti a gbin, ti o le gbà ọkàn nyin là. Ṣugbọn ki ẹ jẹ oluṣe ọ̀rọ na, ki o má si ṣe olugbọ́ nikan, ki ẹ mã tàn ara nyin jẹ. Nitori bi ẹnikan ba jẹ olugbọ́ ọ̀rọ na, ti kò si jẹ oluṣe, on dabi ọkunrin ti o nṣakiyesi oju ara rẹ̀ ninu awojiji: Nitori o ṣakiyesi ara rẹ̀, o si ba tirẹ̀ lọ, lojukanna o si gbagbé bi on ti ri. Ṣugbọn ẹniti o ba nwo inu ofin pipé, ofin omnira nì, ti o si duro ninu rẹ̀, ti on kò jẹ olugbọ́ ti ngbagbé, bikoṣe oluṣe iṣẹ, oluwarẹ̀ yio jẹ alabukun ninu iṣẹ rẹ̀. Bi ẹnikẹni ba ro pe on nsìn Ọlọrun nigbati kò kó ahọn rẹ̀ ni ijanu, ṣugbọn ti o ntàn ọkàn ara rẹ̀ jẹ, ìsin oluwarẹ̀ asan ni. Ìsin mimọ́ ati ailẽri niwaju Ọlọrun ati Baba li eyi, lati mã bojutó awọn alainibaba ati awọn opó ninu ipọnju wọn, ati lati pa ara rẹ̀ mọ́ lailabawọn kuro li aiyé.

Jak 1:13-27 Yoruba Bible (YCE)

Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá ní ìdánwò má ṣe sọ pé, “Láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni ìdánwò yìí ti wá.” Nítorí kò sí ẹni tí ó lè fi nǹkan burúkú dán Ọlọrun wò. Ọlọrun náà kò sì jẹ́ fi nǹkan burúkú dán ẹnikẹ́ni wò. Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn olukuluku ni ó ń tàn án, tí ó ń fa ìdánwò. Nígbà tí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ bá lóyún, á bí ẹ̀ṣẹ̀; nígbà tí ẹ̀ṣẹ̀ bá gbilẹ̀ tán á bí ikú. Ẹ̀yin ará mi olùfẹ́, ẹ má tan ara yín jẹ. Láti òkè ni gbogbo ẹ̀bùn rere ati gbogbo ẹ̀bùn pípé ti ń wá, a máa wá láti ọ̀dọ̀ Baba tí ó dá ìmọ́lẹ̀, baba tí kì í yí pada, tí irú òjìji tíí máa wà ninu ìṣípò pada kò sì sí ninu rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀, ó fi ọ̀rọ̀ òtítọ́ bí wa, kí á lè jẹ́ àkọ́kọ́ ninu àwọn ẹ̀dá rẹ̀. Ẹ̀yin ará mi olùfẹ́ ọ̀wọ́n, mo fẹ́ kí ẹ mọ nǹkankan: eniyan níláti tètè gbọ́ ọ̀rọ̀, ṣugbọn kí ó lọ́ra láti désì pada, kí ó sì lọ́ra láti bínú. Nítorí ibinu eniyan kì í yọrí sí ire tí Ọlọrun fẹ́. Nítorí náà, ẹ mú gbogbo ìwà èérí ati gbogbo ìwàkiwà à-ń-wá-ipò-aṣaaju kúrò, kí á lè wà ní ipò kinni. Ẹ fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ gba ọ̀rọ̀ tí a gbìn sinu yín, tí ó lè gba ọkàn yín là. Ẹ máa fi ọ̀rọ̀ ìyìn rere ṣe ìwà hù; ẹ má kàn máa gbọ́ ọ lásán. Bí ẹ bá ń gbọ́ lásán, ara yín ni ẹ̀ ń tàn jẹ. Nítorí bí eniyan bá gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí kò fi ṣe ìwà hù, olúwarẹ̀ dàbí ẹni tí ó wo ojú ara rẹ̀ ninu dígí. Ó wo ara rẹ̀ dáradára, ó kúrò níbẹ̀, kíá ó ti gbàgbé bí ojú rẹ̀ ti rí. Ṣugbọn ẹni tí ó bá wo òfin tí ó pé, tíí ṣe orísun òmìnira, tí ó sì dúró lé e lórí, olúwarẹ̀ kì í ṣe ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ tí ó gbàgbé rẹ̀, ṣugbọn ó ń fi ọ̀rọ̀ náà ṣe ìwà hù. Olúwarẹ̀ di ẹni ibukun nítorí ó ń fi ọ̀rọ̀ tí ó gbọ́ ṣe ìwà hù. Bí ẹnìkan bá rò pé òun jẹ́ olùfọkànsìn, tí kò bá kó ahọ́n rẹ̀ níjàánu, ó ń tan ara rẹ̀ jẹ ni, asán sì ni ẹ̀sìn rẹ̀. Ẹ̀sìn tí ó pé, tí kò lábàwọ́n níwájú Ọlọrun Baba ni pé kí eniyan máa ran àwọn ọmọ tí kò ní òbí ati àwọn opó lọ́wọ́ ninu ipò ìbànújẹ́ wọn, kí eniyan sì pa ara rẹ̀ mọ́ láìléèérí ninu ayé.

Jak 1:13-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Kí ẹnikẹ́ni tí a dánwò kí ó má ṣe wí pé, “Láti ọwọ́ Ọlọ́run ni a ti dán mi wò.” Nítorí a kò lè fi búburú dán Ọlọ́run wò, òun náà kì í sì í dán ẹnikẹ́ni wò; Ṣùgbọ́n olúkúlùkù ni a ń dánwò nígbà tí a bá fi ọwọ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara rẹ̀ fà á lọ tí a sì tàn án jẹ. Ǹjẹ́, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ nígbà tí ó bá lóyún a bí ẹ̀ṣẹ̀, àti ẹ̀ṣẹ̀ náà nígbà tí ó bá dàgbà tán, a bí ikú. Kí a má ṣe tàn yín jẹ, ẹ̀yin ará mi olùfẹ́. Gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ẹ̀bùn pípé láti òkè ni ó ti wá, ó sì sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ baba ìmọ́lẹ̀ wá, lọ́dọ̀ ẹni tí kò lè yípadà gẹ́gẹ́ bí òjìji àyídà. Ó pinnu láti fi ọ̀rọ̀ òtítọ́ bí wa kí àwa kí ó le jẹ́ àkọ́so nínú ohun gbogbo tí ó dá. Kí ẹ mọ èyí, ẹ̀yin ará mi olùfẹ́; jẹ́ kí olúkúlùkù ènìyàn kí ó máa yára láti gbọ́, kí ó lọ́ra láti fọhùn, kí ó si lọ́ra láti bínú; Nítorí ìbínú ènìyàn kì í ṣiṣẹ́ òdodo irú èyí tí Ọlọ́run ń fẹ́. Nítorí náà, ẹ lépa láti borí gbogbo èérí àti ìwà búburú tí ó gbilẹ̀ yíká, kí ẹ sì fi ọkàn tútù gba ọ̀rọ̀ náà tí a gbìn, tí ó lè gba ọkàn yín là. Ẹ má kan jẹ́ olùgbọ́ ọ̀rọ̀ náà lásán, kí ẹ má ba à ti ipa èyí tan ara yín jẹ́. Ẹ ṣe ohun tí ó sọ. Nítorí bí ẹnikẹ́ni bá jẹ́ olùgbọ́ ọ̀rọ̀ náà tí kò sì jẹ́ olùṣe, òun dàbí ọkùnrin tí ó ń ṣàkíyèsí ojú ara rẹ̀ nínú dígí Nítorí, lẹ́yìn tí ó bá ti ṣàkíyèsí ara rẹ̀, tí ó sì bá tirẹ̀ lọ, lójúkan náà òun sì gbàgbé bí òun ti rí. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń wo inú òfin pípé, òfin òmìnira ni, tí ó sì dúró nínú rẹ̀, tí òun kò sì jẹ́ olùgbọ́ tí ń gbàgbé bí kò ṣe olùṣe rẹ̀, òun yóò jẹ́ alábùkún nínú iṣẹ́ rẹ̀. Bí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun ń sin Ọlọ́run nígbà tí kò kó ahọ́n rẹ̀ ní ìjánu, ó ń tan ọkàn ara rẹ̀ jẹ, ìsìn rẹ̀ sì jẹ́ asán. Ìsìn mímọ́ àti aláìléèérí níwájú Ọlọ́run àti baba ni èyí, láti máa bojútó àwọn aláìní baba àti àwọn opó nínú ìpọ́njú wọn, àti láti pa ara rẹ̀ mọ́ láìlábàwọ́n kúrò nínú ayé.

Jak 1:13-27

Jak 1:13-27 YBCVJak 1:13-27 YBCVJak 1:13-27 YBCVJak 1:13-27 YBCV

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa