Jak 1:13-18
Jak 1:13-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ki ẹnikẹni ti a danwò máṣe wipe, Lati ọwọ́ Ọlọrun li a ti dán mi wò: nitori a kò le fi buburu dán Ọlọrun wò, on na kì isi idán ẹnikẹni wò: Ṣugbọn olukuluku ni a ndanwò, nigbati a ba ti ọwọ́ ifẹkufẹ ara rẹ̀ fà a lọ ti a si tàn a jẹ. Njẹ, ifẹkufẹ na nigbati o ba lóyun, a bí ẹ̀ṣẹ: ati ẹ̀ṣẹ na nigbati o ba si dagba tan, a bí ikú. Ki a má ṣe tan nyin jẹ, ẹnyin ará mi olufẹ. Gbogbo ẹ̀bun rere ati gbogbo ẹ̀bun pipé lati oke li o ti wá, o si nsọkalẹ lati ọdọ Baba imọlẹ wá, lọdọ Ẹniti kò le si iyipada tabi ojiji àyida. Nipa ifẹ ara rẹ̀ li o fi ọ̀rọ otitọ bí wa, ki awa ki o le jẹ bi akọso awọn ẹda rẹ̀.
Jak 1:13-18 Yoruba Bible (YCE)
Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá ní ìdánwò má ṣe sọ pé, “Láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni ìdánwò yìí ti wá.” Nítorí kò sí ẹni tí ó lè fi nǹkan burúkú dán Ọlọrun wò. Ọlọrun náà kò sì jẹ́ fi nǹkan burúkú dán ẹnikẹ́ni wò. Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn olukuluku ni ó ń tàn án, tí ó ń fa ìdánwò. Nígbà tí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ bá lóyún, á bí ẹ̀ṣẹ̀; nígbà tí ẹ̀ṣẹ̀ bá gbilẹ̀ tán á bí ikú. Ẹ̀yin ará mi olùfẹ́, ẹ má tan ara yín jẹ. Láti òkè ni gbogbo ẹ̀bùn rere ati gbogbo ẹ̀bùn pípé ti ń wá, a máa wá láti ọ̀dọ̀ Baba tí ó dá ìmọ́lẹ̀, baba tí kì í yí pada, tí irú òjìji tíí máa wà ninu ìṣípò pada kò sì sí ninu rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀, ó fi ọ̀rọ̀ òtítọ́ bí wa, kí á lè jẹ́ àkọ́kọ́ ninu àwọn ẹ̀dá rẹ̀.
Jak 1:13-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Kí ẹnikẹ́ni tí a dánwò kí ó má ṣe wí pé, “Láti ọwọ́ Ọlọ́run ni a ti dán mi wò.” Nítorí a kò lè fi búburú dán Ọlọ́run wò, òun náà kì í sì í dán ẹnikẹ́ni wò; Ṣùgbọ́n olúkúlùkù ni a ń dánwò nígbà tí a bá fi ọwọ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara rẹ̀ fà á lọ tí a sì tàn án jẹ. Ǹjẹ́, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ nígbà tí ó bá lóyún a bí ẹ̀ṣẹ̀, àti ẹ̀ṣẹ̀ náà nígbà tí ó bá dàgbà tán, a bí ikú. Kí a má ṣe tàn yín jẹ, ẹ̀yin ará mi olùfẹ́. Gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ẹ̀bùn pípé láti òkè ni ó ti wá, ó sì sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ baba ìmọ́lẹ̀ wá, lọ́dọ̀ ẹni tí kò lè yípadà gẹ́gẹ́ bí òjìji àyídà. Ó pinnu láti fi ọ̀rọ̀ òtítọ́ bí wa kí àwa kí ó le jẹ́ àkọ́so nínú ohun gbogbo tí ó dá.