Isa 9:7
Isa 9:7 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ijọba yio bi si i, alafia ki yio ni ipẹkun: lori itẹ Dafidi, ati lori ijọba rẹ̀, lati ma tọ́ ọ, ati lati fi idi rẹ̀ mulẹ, nipa idajọ, ati ododo lati isisiyi lọ, ani titi lai. Itara Oluwa awọn ọmọ-ogun yio ṣe eyi.
Pín
Kà Isa 9Isa 9:7 Yoruba Bible (YCE)
Ìjọba rẹ̀ yóo máa tóbi sí i, alaafia kò sì ní lópin ní ìjọba rẹ̀ lórí ìtẹ́ Dafidi. Yóo fìdí rẹ̀ múlẹ̀, yóo sì gbé e ró pẹlu ẹ̀tọ́ ati òdodo, láti ìgbà yìí lọ, títí ayérayé. Ìtara OLUWA àwọn ọmọ ogun ni yóo ṣe èyí
Pín
Kà Isa 9Isa 9:7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ti ìgbòòrò Ìjọba rẹ̀ àti àlàáfíà rẹ̀ ni kì yóò ní ìpẹ̀kun. Yóò jẹ ọba lórí ìtẹ́ Dafidi àti lórí ẹ̀kún un rẹ̀ gbogbo, nípa ìfìdímúlẹ̀ àti ìgbéró rẹ̀, pẹ̀lú òtítọ́ àti òdodo láti ìgbà náà lọ àti títí láéláé. Ìtara OLúWA àwọn ọmọ-ogun ni yóò mú èyí ṣẹ.
Pín
Kà Isa 9