Isa 64:8-12
Isa 64:8-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn nisisiyi, Oluwa, iwọ ni baba wa; awa ni amọ̀, iwọ si ni ọ̀mọ; gbogbo wa si ni iṣẹ ọwọ́ rẹ. Máṣe binu kọja àla, Oluwa, ki o má si ranti aiṣedede wa titilai: kiyesi i, wò, awa bẹ̀ ọ, enia rẹ ni gbogbo wa iṣe. Awọn ilu mimọ́ rẹ di aginju, Sioni dí aginju, Jerusalemu di ahoro. Ile wa mimọ́ ati ologo, nibiti awọn baba wa ti nyìn ọ, li a fi iná kun: gbogbo ohun ãyo wa si ti run. Iwọ o ha da ara rẹ duro nitori nkan wọnyi, Oluwa? iwọ o ha dakẹ, ki o si pọn wa loju kọja àla?
Isa 64:8-12 Yoruba Bible (YCE)
Sibẹsibẹ OLUWA, ìwọ ni baba wa, amọ̀ ni wá, ìwọ sì ni amọ̀kòkò; iṣẹ́ ọwọ́ rẹ ni gbogbo wa. OLUWA má bínú pupọ jù, má máa ranti ẹ̀ṣẹ̀ wa títí lae. Jọ̀wọ́, ro ọ̀rọ̀ wa wò, nítorí pé eniyan rẹ ni gbogbo wa. Àwọn ìlú mímọ́ rẹ ti di aṣálẹ̀, Sioni ti di aṣálẹ̀, Jerusalẹmu sì ti di ahoro. Wọ́n ti dáná sun ilé mímọ́ wa tí ó lẹ́wà, níbi tí àwọn baba wa ti yìn ọ́, gbogbo ibi dáradára tí a ní, ló ti di ahoro. OLUWA, ṣé o kò ní ṣe nǹkankan sí ọ̀rọ̀ yìí ni? Ṣé o óo dákẹ́, o óo máa fìyà jẹ wá ni?
Isa 64:8-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Síbẹ̀síbẹ̀, OLúWA, ìwọ ni Baba wa. Àwa ni amọ̀, ìwọ ni amọ̀kòkò; gbogbo wa jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. Má ṣe bínú kọjá ààlà, ìwọ OLúWA: Má ṣe rántí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa títí láé. Jọ̀wọ́, bojú wò wá, ni a gbàdúrà, nítorí ènìyàn rẹ ni gbogbo wa. Àwọn ìlú mímọ́ rẹ ti di aṣálẹ̀; Sioni pàápàá di aṣálẹ̀, Jerusalẹmu di ahoro. Tẹmpili mímọ́ ológo wa, níbi tí àwọn baba wa ti yìn ọ́, ni a ti fi iná sun, àti ohun gbogbo tí í ṣe ìṣúra wa ti dahoro. Lẹ́yìn gbogbo nǹkan wọ̀nyí, OLúWA, ìwọ ó ha sì tún fi ara rẹ pamọ́ bí? Ìwọ ó ha dákẹ́ kí o sì fìyà jẹ wá kọjá ààlà bí?