Isa 64:1-4
Isa 64:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Ò bá jẹ́ fa awọsanma ya kí o sì sọ̀kalẹ̀, kí àwọn òkè ńlá máa mì tìtì níwájú rẹ; bí ìgbà tí iná ń jó igbó ṣúúrú, tí iná sì ń mú kí omi hó. Kí orúkọ rẹ di mímọ̀ fún àwọn ọ̀tá rẹ, kí àwọn orílẹ̀-èdè lè máa gbọ̀n níwájú rẹ! Nígbà tí o bá ṣe nǹkan tí ó bani lẹ́rù, tí ẹnikẹ́ni kò retí, o sọ̀kalẹ̀, àwọn òkè ńlá sì mì tìtì níwájú rẹ. Láti ìgbà àtijọ́, ẹnìkan kò gbọ́ rí, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò tíì fi ojú rí Ọlọrun mìíràn lẹ́yìn rẹ, tí ń ṣe irú nǹkan wọnyi fún àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé e.
Isa 64:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
IWỌ iba jẹ fà awọn ọrun ya, ki iwọ si sọkalẹ, ki awọn oke-nla ki o le yọ́ niwaju rẹ. Gẹgẹ bi igbati iná ileru ti njo, bi iná ti imu omi hó, lati sọ orukọ rẹ di mimọ̀ fun awọn ọta rẹ, ki awọn orilẹ-ède ki o le warìri niwaju rẹ! Nigbati iwọ ṣe nkan wọnni ti o lẹ̀ru ti awa kò fi oju sọna fun, iwọ sọkalẹ wá, awọn oke-nla yọ́ niwaju rẹ. Nitori lati ipilẹṣẹ aiye wá, a kò ti igbọ́, bẹ̃ni eti kò ti gbọ́ ọ, bẹ̃ni oju kò ti iri Ọlọrun kan lẹhin rẹ, ti o ti pèse fun ẹniti o duro dè e.
Isa 64:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Ò bá jẹ́ fa awọsanma ya kí o sì sọ̀kalẹ̀, kí àwọn òkè ńlá máa mì tìtì níwájú rẹ; bí ìgbà tí iná ń jó igbó ṣúúrú, tí iná sì ń mú kí omi hó. Kí orúkọ rẹ di mímọ̀ fún àwọn ọ̀tá rẹ, kí àwọn orílẹ̀-èdè lè máa gbọ̀n níwájú rẹ! Nígbà tí o bá ṣe nǹkan tí ó bani lẹ́rù, tí ẹnikẹ́ni kò retí, o sọ̀kalẹ̀, àwọn òkè ńlá sì mì tìtì níwájú rẹ. Láti ìgbà àtijọ́, ẹnìkan kò gbọ́ rí, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò tíì fi ojú rí Ọlọrun mìíràn lẹ́yìn rẹ, tí ń ṣe irú nǹkan wọnyi fún àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé e.
Isa 64:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìwọ ìbá fa ọ̀run ya kí o sì sọ̀kalẹ̀ wá, tí àwọn òkè ńlá yóò fi wárìrì níwájú rẹ! Gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí iná mú ẹ̀ka igi jó tí ó sì mú kí omi ó hó, sọ̀kalẹ̀ wá kí orúkọ rẹ le di mí mọ̀ fún àwọn ọ̀tá rẹ kí o sì jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè kí ó wárìrì níwájú rẹ! Nítorí nígbà tí o bá ṣe àwọn ohun ẹ̀rù tí àwa kò nírètí, o sọ̀kalẹ̀ wá, àwọn òkè ńlá sì wárìrì níwájú rẹ̀. Láti ìgbà àtijọ́ kò sí ẹni tí ó gbọ́ rí kò sí etí kan tí ó gbọ́ ọ, kò sí ojú tí ó tí ì rí Ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn rẹ, tí ó máa ń ṣe nǹkan lórúkọ àwọn tí ó dúró dè é.