Isa 63:11-14
Isa 63:11-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbana ni o ranti ọjọ atijọ, Mose, awọn enia rẹ̀, wipe, Nibo li ẹniti o mu wọn ti inu okun jade gbe wà, ti on ti olùṣọ agutan ọwọ́-ẹran rẹ̀? nibo li ẹniti o fi Ẹmi mimọ́ rẹ̀ sinu rẹ̀ gbe wà? Ti o fi ọwọ́ ọtun Mose dà wọn, pẹlu apá rẹ̀ ti o logo, ti o npin omi meji niwaju wọn, lati ṣe orukọ aiyeraiye fun ara rẹ̀? Ti o mu wọn là ibú ja, bi ẹṣin li aginjù, ki nwọn ki o má ba kọsẹ? Gẹgẹ bi ẹran ti isọ̀kalẹ lọ si afonifoji, bẹ̃ni Ẹmi Oluwa mu u simi: bẹ̃ni iwọ tọ́ awọn enia rẹ, lati ṣe orukọ ti o li ogo fun ara rẹ.
Isa 63:11-14 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn ó ranti ìgbà àtijọ́, ní àkókò Mose, iranṣẹ rẹ̀. Wọ́n bèèrè pé, ẹni tí ó kó wọn la òkun já dà? Olùṣọ́-aguntan agbo rẹ̀, tí ó fi Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀ sáàrin wọn? Ẹni tí ó gbé agbára rẹ̀ tí ó lógo wọ Mose, tí ó pín òkun níyà níwájú wọn, kí orúkọ rẹ̀ lè lókìkí títí lae. Ó mú wọn la ibú omi kọjá, bí ẹṣin ninu aṣálẹ̀; wọ́n rìn, wọn kò fẹsẹ̀ kọ. Wọ́n rìn wọnú àfonífojì bíi mààlúù, Ẹ̀mí OLUWA sì fún wọn ní ìsinmi. Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe darí àwọn eniyan rẹ̀, kí ó lè gba ògo fún orúkọ rẹ̀.
Isa 63:11-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Lẹ́yìn náà ni àwọn ènìyàn rẹ̀ rántí ọjọ́ ìgbà n nì, àwọn ọjọ́ Mose àti àwọn ènìyàn rẹ̀ níbo ni ẹni náà wà tí ó mú wọn la Òkun já, pẹ̀lú olùṣọ́-àgùntàn agbo ẹran rẹ̀? Níbo ni ẹni náà wà tí ó rán Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀ sáàrín wọn, ta ni ó rán apá ògo ti agbára rẹ̀ láti wà ní apá ọ̀tún Mose, ta ni ó pín omi ní yà níwájú wọn, láti gba òkìkí ayérayé fún ara rẹ̀, ta ni ó síwájú wọn la àwọn ọ̀gbun nì já? Gẹ́gẹ́ bí ẹṣin ni gbangba ìlú wọn tí kò sì kọsẹ̀; gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ ẹran tí ó lọ sí pápá oko, a fún wọn ní ìsinmi láti ọwọ́ Ẹ̀mí OLúWA. Báyìí ni ẹ ṣe tọ́ àwọn ènìyàn yín láti fún ara yín ní orúkọ kan tí ó lógo.