Isa 62:6-7
Isa 62:6-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
Emi ti fi awọn alore sori odi rẹ, iwọ Jerusalemu, ti kì yio pa ẹnu wọn mọ lọsan ati loru titilai: ẹnyin ti nṣe iranti Oluwa, ẹ máṣe dakẹ. Ẹ máṣe fun u ni isimi, titi yio fi fi idi Jerusalemu mulẹ, ti yio ṣe e ni iyìn li aiye.
Pín
Kà Isa 62Isa 62:6-7 Yoruba Bible (YCE)
Jerusalẹmu, mo ti fi àwọn aṣọ́de sí orí odi rẹ; lojoojumọ, tọ̀sán-tòru, wọn kò gbọdọ̀ panumọ́. Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń rán OLUWA létí, ẹ má dákẹ́. Ẹ má jẹ́ kí ó sinmi, títí yóo fi fi ìdí Jerusalẹmu múlẹ̀, títí yóo fi sọ ọ́ di ìlú ìyìn láàrin gbogbo ayé.
Pín
Kà Isa 62Isa 62:6-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èmi ti fi olùṣọ́ ránṣẹ́ sórí odi rẹ ìwọ Jerusalẹmu; wọn kì yóò lè dákẹ́ tọ̀sán tòru. Ẹ̀yin tí ń ké pe OLúWA, ẹ má ṣe fúnrayín ní ìsinmi, àti kí ẹ má ṣe fún òun pẹ̀lú ní ìsinmi títí tí yóò fi fi ìdí Jerusalẹmu múlẹ̀ tí yóò sì fi ṣe ìyìn orí ilẹ̀ ayé.
Pín
Kà Isa 62