Isa 61:2-3
Isa 61:2-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
Lati kede ọdun itẹwọgba Oluwa, ati ọjọ ẹsan Ọlọrun wa; lati tù gbogbo awọn ti ngbãwẹ̀ ninu. Lati yàn fun awọn ti nṣọ̀fọ fun Sioni, lati fi ọṣọ́ fun wọn nipo ẽrú, ororo ayọ̀ nipo ọ̀fọ, aṣọ iyìn nipo ẹmi ibanujẹ, ki a le pè wọn ni igi ododo, ọgbìn Oluwa, ki a le yìn i logo.
Isa 61:2-3 Yoruba Bible (YCE)
Ó ní kí n máa kéde ọdún ojurere OLUWA, ati ọjọ́ ẹ̀san Ọlọrun wa; kí n sì máa tu àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ ninu. Ó ní kí n máa fún àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ ní Sioni, ní inú dídùn dípò ìkáàánú, kí n fún wọn ní ayọ̀ dípò ìbànújẹ́, kí n jẹ́ kí wọn máa kọrin ìyìn dípò ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn, kí á lè máa pè wọ́n ní igi òdodo, tí OLUWA gbìn, kí á lè máa yìn ín lógo.
Isa 61:2-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Láti kéde ọdún ojúrere OLúWA àti ọjọ́ ẹ̀san ti Ọlọ́run wa, láti tu àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ nínú, àti láti pèsè fún àwọn tí inú wọn bàjẹ́ ní Sioni láti dé wọn ládé ẹwà dípò eérú, òróró ayọ̀ dípò ọ̀fọ̀, àti aṣọ ìyìn dípò ìpòrúru ọkàn. A ó sì pè wọ́n ní igi óákù òdodo, irúgbìn OLúWA láti fi ọláńlá rẹ̀ hàn.