Isa 61:1-7

Isa 61:1-7 Yoruba Bible (YCE)

Ẹ̀mí OLUWA, Ọlọrun tí bà lé mi, nítorí ó ti fi àmì òróró yàn mí, láti mú ìròyìn ayọ̀ wá fún àwọn tí a ni lára. Ó rán mi pé kí n máa tu àwọn tí ó ní ìbànújẹ́ ninu, kí n máa kéde ìdásílẹ̀ fún àwọn tí ó wà ní ìgbèkùn, kí n sì máa ṣí ìlẹ̀kùn ọgbà ẹ̀wọ̀n sílẹ̀ fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n. Ó ní kí n máa kéde ọdún ojurere OLUWA, ati ọjọ́ ẹ̀san Ọlọrun wa; kí n sì máa tu àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ ninu. Ó ní kí n máa fún àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ ní Sioni, ní inú dídùn dípò ìkáàánú, kí n fún wọn ní ayọ̀ dípò ìbànújẹ́, kí n jẹ́ kí wọn máa kọrin ìyìn dípò ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn, kí á lè máa pè wọ́n ní igi òdodo, tí OLUWA gbìn, kí á lè máa yìn ín lógo. Wọn óo tún àlàpà ahoro àtijọ́ kọ́, wọn óo tún gbogbo ilé tí ó ti wó lulẹ̀ kọ́, wọn óo sì tún ìlú tí a ti parun láti ọdún gbọọrọ kọ́. Àwọn àjèjì ni yóo máa ba yín bọ́ agbo ẹran yín, àwọn ni yóo sì máa ṣe alágbàṣe ninu ọgbà àjàrà yín; ṣugbọn a óo máa pe ẹ̀yin ní alufaa OLUWA, àwọn eniyan yóo sì máa sọ̀rọ̀ yín bí iranṣẹ Ọlọrun wa. Ẹ̀yin ni ẹ óo máa jẹ ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, ọrọ̀ wọn ni ẹ óo sì máa fi ṣògo. Dípò ìtìjú ìpín tiyín yóo jẹ́ meji, dípò àbùkù ẹ óo láyọ̀ ninu ìpín tí ó kàn yín. Ìlọ́po meji ni ìpín yín yóo jẹ́ ninu ilẹ̀ yín, ayọ̀ ayérayé yóo sì jẹ́ tiyín.

Isa 61:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ẹ̀mí OLúWA Olódùmarè wà lára mi nítorí OLúWA ti fi ààmì òróró yàn mí láti wàásù ìhìnrere fún àwọn tálákà. Ó ti rán mi láti ṣe àwòtán oníròbìnújẹ́ láti kéde ìdásílẹ̀ fún àwọn ìgbèkùn àti ìtúsílẹ̀ kúrò nínú òkùnkùn fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n, Láti kéde ọdún ojúrere OLúWA àti ọjọ́ ẹ̀san ti Ọlọ́run wa, láti tu àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ nínú, àti láti pèsè fún àwọn tí inú wọn bàjẹ́ ní Sioni láti dé wọn ládé ẹwà dípò eérú, òróró ayọ̀ dípò ọ̀fọ̀, àti aṣọ ìyìn dípò ìpòrúru ọkàn. A ó sì pè wọ́n ní igi óákù òdodo, irúgbìn OLúWA láti fi ọláńlá rẹ̀ hàn. Wọn yóò tún àwọn ahoro àtijọ́ kọ́ wọn yóò sì mú àwọn ibi ìparun àtijọ́-tijọ́ náà bọ̀ sípò; wọn yóò jí àwọn ahoro ìlú náà padà tí a ti parun láti ìrandíran sẹ́yìn. Àwọn àjèjì ni yóò máa da ọ̀wọ́ ẹran rẹ; àwọn àlejò yóò sì ṣiṣẹ́ nínú oko àti ọgbà àjàrà rẹ. A ó sì máa pè yín ní àlùfáà OLúWA, a ó pè yín ní ìránṣẹ́ Ọlọ́run wa. Ẹ ó máa jẹ nínú ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè àti nínú ọrọ̀ wọn ni ẹ̀yin yóò máa ṣògo. Dípò àbùkù wọn àwọn ènìyàn mi yóò gba ìlọ́po méjì, àti dípò àbùkù wọn wọn yóò yọ̀ nínú ìní wọn; bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò sì jogún ìlọ́po méjì ní ilẹ̀ wọn, ayọ̀ ayérayé yóò sì jẹ́ tiwọn.