Isa 61:1-11

Isa 61:1-11 Bibeli Mimọ (YBCV)

ẸMI Oluwa Jehofah mbẹ lara mi: nitori o ti fi ami ororo yàn mi lati wãsu ihin-rere fun awọn òtoṣi; o ti rán mi lati ṣe awotán awọn onirobinujẹ ọkàn, lati kede idasilẹ fun awọn igbekùn, ati iṣisilẹ tubu fun awọn ondè. Lati kede ọdun itẹwọgba Oluwa, ati ọjọ ẹsan Ọlọrun wa; lati tù gbogbo awọn ti ngbãwẹ̀ ninu. Lati yàn fun awọn ti nṣọ̀fọ fun Sioni, lati fi ọṣọ́ fun wọn nipo ẽrú, ororo ayọ̀ nipo ọ̀fọ, aṣọ iyìn nipo ẹmi ibanujẹ, ki a le pè wọn ni igi ododo, ọgbìn Oluwa, ki a le yìn i logo. Nwọn o si mọ ibi ahoro atijọ wọnni, nwọn o gbe ahoro atijọ wọnni ro, nwọn o si tun ilu wọnni ti o ṣofo ṣe, ahoro iran ọ̀pọlọpọ. Awọn alejò yio si duro, nwọn o si bọ́ ọwọ́ ẹran nyin, awọn ọmọ alejò yio si ṣe atulẹ nyin, ati olurẹ́ ọwọ́ àjara nyin. Ṣugbọn a o ma pè nyin ni Alufa Oluwa: nwọn o ma pè nyin ni Iranṣẹ Ọlọrun wa: ẹ o jẹ ọrọ̀ awọn Keferi, ati ninu ogo wọn li ẹ o mã ṣogo. Nipo itijú nyin ẹ o ni iṣẹpo-meji; ati nipo idãmu, nwọn o yọ̀ ninu ipin wọn: nitorina nwọn o ni iṣẹpo-meji ni ilẹ wọn: ayọ̀ ainipẹkun yio jẹ ti wọn. Nitori emi Oluwa fẹ idajọ, mo korira ijale ninu aiṣododo; emi o si fi iṣẹ wọn fun wọn ni otitọ, emi o si ba wọn da majẹmu aiyeraiye. A o si mọ̀ iru wọn ninu awọn Keferi, ati iru-ọmọ wọn lãrin awọn enia, gbogbo ẹniti o ri wọn yio mọ̀ wọn, pé, iru-ọmọ ti Oluwa busi ni nwọn. Emi o yọ̀ gidigidi ninu Oluwa, ọkàn mi yio yọ̀ ninu Ọlọrun mi; nitori o ti fi agbáda wọ̀ mi, o ti fi aṣọ ododo bò mi, gẹgẹ bi ọkọ iyawó ti iṣe ara rẹ̀ lọṣọ́, ati bi iyawó ti ifi ohun ọṣọ́ ṣe ara rẹ̀ lọṣọ́. Nitori gẹgẹ bi ilẹ ti imu ẽhù rẹ̀ jade, ati bi ọgbà ti imu ohun ti a gbìn sinu rẹ̀ hù soke; bẹ̃ni Oluwa Jehofah yio mu ododo ati iyìn hù soke niwaju gbogbo orilẹ-ède.

Isa 61:1-11 Yoruba Bible (YCE)

Ẹ̀mí OLUWA, Ọlọrun tí bà lé mi, nítorí ó ti fi àmì òróró yàn mí, láti mú ìròyìn ayọ̀ wá fún àwọn tí a ni lára. Ó rán mi pé kí n máa tu àwọn tí ó ní ìbànújẹ́ ninu, kí n máa kéde ìdásílẹ̀ fún àwọn tí ó wà ní ìgbèkùn, kí n sì máa ṣí ìlẹ̀kùn ọgbà ẹ̀wọ̀n sílẹ̀ fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n. Ó ní kí n máa kéde ọdún ojurere OLUWA, ati ọjọ́ ẹ̀san Ọlọrun wa; kí n sì máa tu àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ ninu. Ó ní kí n máa fún àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ ní Sioni, ní inú dídùn dípò ìkáàánú, kí n fún wọn ní ayọ̀ dípò ìbànújẹ́, kí n jẹ́ kí wọn máa kọrin ìyìn dípò ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn, kí á lè máa pè wọ́n ní igi òdodo, tí OLUWA gbìn, kí á lè máa yìn ín lógo. Wọn óo tún àlàpà ahoro àtijọ́ kọ́, wọn óo tún gbogbo ilé tí ó ti wó lulẹ̀ kọ́, wọn óo sì tún ìlú tí a ti parun láti ọdún gbọọrọ kọ́. Àwọn àjèjì ni yóo máa ba yín bọ́ agbo ẹran yín, àwọn ni yóo sì máa ṣe alágbàṣe ninu ọgbà àjàrà yín; ṣugbọn a óo máa pe ẹ̀yin ní alufaa OLUWA, àwọn eniyan yóo sì máa sọ̀rọ̀ yín bí iranṣẹ Ọlọrun wa. Ẹ̀yin ni ẹ óo máa jẹ ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, ọrọ̀ wọn ni ẹ óo sì máa fi ṣògo. Dípò ìtìjú ìpín tiyín yóo jẹ́ meji, dípò àbùkù ẹ óo láyọ̀ ninu ìpín tí ó kàn yín. Ìlọ́po meji ni ìpín yín yóo jẹ́ ninu ilẹ̀ yín, ayọ̀ ayérayé yóo sì jẹ́ tiyín. OLUWA ní, “Nítorí pé mo fẹ́ ẹ̀tọ́, mo sì kórìíra ìfipá jalè ati ohun tí kò tọ́. Dájúdájú n óo san ẹ̀san fún wọn, n óo sì bá wọn dá majẹmu ayérayé. Àwọn ọmọ wọn yóo dá yàtọ̀ láàrin orílẹ̀-èdè, a óo dá arọmọdọmọ wọn mọ̀ láàrin àwọn eniyan, gbogbo àwọn tí ó bá rí wọn, yóo gbà pé èmi OLUWA ti bukun wọn.” N óo máa yọ̀ ninu OLUWA, ọkàn mi yóo kún fún ayọ̀ sí Ọlọrun mi. Nítorí ó ti fi ìgbàlà wọ̀ mí bí ẹ̀wù, ó sì ti fi òdodo bòmí lára bí aṣọ; bí ọkọ iyawo tí ó ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́, ati bí iyawo tí ó ṣe ọ̀ṣọ́ jìngbìnnì. Bí ilẹ̀ tíí mú kí ewéko hù jáde, tí ọgbà sì ń mú kí ohun tí a gbìn sinu rẹ̀ hù, bẹ́ẹ̀ ni OLUWA Ọlọrun yóo mú kí òdodo ati orin ìyìn yọ jáde níwájú gbogbo orílẹ̀-èdè.

Isa 61:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ẹ̀mí OLúWA Olódùmarè wà lára mi nítorí OLúWA ti fi ààmì òróró yàn mí láti wàásù ìhìnrere fún àwọn tálákà. Ó ti rán mi láti ṣe àwòtán oníròbìnújẹ́ láti kéde ìdásílẹ̀ fún àwọn ìgbèkùn àti ìtúsílẹ̀ kúrò nínú òkùnkùn fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n, Láti kéde ọdún ojúrere OLúWA àti ọjọ́ ẹ̀san ti Ọlọ́run wa, láti tu àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ nínú, àti láti pèsè fún àwọn tí inú wọn bàjẹ́ ní Sioni láti dé wọn ládé ẹwà dípò eérú, òróró ayọ̀ dípò ọ̀fọ̀, àti aṣọ ìyìn dípò ìpòrúru ọkàn. A ó sì pè wọ́n ní igi óákù òdodo, irúgbìn OLúWA láti fi ọláńlá rẹ̀ hàn. Wọn yóò tún àwọn ahoro àtijọ́ kọ́ wọn yóò sì mú àwọn ibi ìparun àtijọ́-tijọ́ náà bọ̀ sípò; wọn yóò jí àwọn ahoro ìlú náà padà tí a ti parun láti ìrandíran sẹ́yìn. Àwọn àjèjì ni yóò máa da ọ̀wọ́ ẹran rẹ; àwọn àlejò yóò sì ṣiṣẹ́ nínú oko àti ọgbà àjàrà rẹ. A ó sì máa pè yín ní àlùfáà OLúWA, a ó pè yín ní ìránṣẹ́ Ọlọ́run wa. Ẹ ó máa jẹ nínú ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè àti nínú ọrọ̀ wọn ni ẹ̀yin yóò máa ṣògo. Dípò àbùkù wọn àwọn ènìyàn mi yóò gba ìlọ́po méjì, àti dípò àbùkù wọn wọn yóò yọ̀ nínú ìní wọn; bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò sì jogún ìlọ́po méjì ní ilẹ̀ wọn, ayọ̀ ayérayé yóò sì jẹ́ tiwọn. “Nítorí Èmi, OLúWA fẹ́ràn ìdájọ́ òdodo; mo kórìíra olè jíjà àti ẹ̀ṣẹ̀ Ní òtítọ́ mi èmi yóò sẹ̀san fún wọn èmi yóò sì dá májẹ̀mú ayérayé pẹ̀lú wọn. A ó mọ ìrandíran wọn láàrín àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn ìran wọn láàrín àwọn ènìyàn Gbogbo àwọn tí ó bá rí wọn yóò mọ̀ pé wọ́n jẹ́ àwọn ènìyàn tí OLúWA ti bùkún.” Èmi yọ̀ gidigidi nínú OLúWA; ọkàn mi yọ̀ nínú Ọlọ́run mi. Nítorí ó ti wọ̀ mí ní aṣọ ìgbàlà ó sì ṣe mí lọ́ṣọ̀ọ́ nínú aṣọ òdodo; gẹ́gẹ́ bí ọkọ ìyàwó ti ṣe orí rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́ bí àlùfáà, àti bí ìyàwó ṣe ń ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú ohun ọ̀ṣọ́. Gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ti í mú irúgbìn jáde àti bí ọgbà ṣe ń mú irúgbìn dàgbà, Bẹ́ẹ̀ ni OLúWA Olódùmarè yóò ṣe mú òdodo àti ìyìn kí ó ru sókè níwájú gbogbo orílẹ̀-èdè.

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa