Isa 6:1-13

Isa 6:1-13 Bibeli Mimọ (YBCV)

LI ọdun ti Ussiah ọba kú, emi ri Oluwa joko lori itẹ ti o ga, ti o si gbe ara soke, iṣẹti aṣọ igunwà rẹ̀ kun tempili. Awọn serafu duro loke rẹ̀: ọkọ̃kan wọn ni iyẹ mẹfa, o fi meji bò oju rẹ̀, o si fi meji bò ẹsẹ rẹ̀, o si fi meji fò. Ikini si ke si ekeji pe, Mimọ́, mimọ́, mimọ́, li Oluwa awọn ọmọ-ogun, gbogbo aiye kún fun ogo rẹ̀. Awọn òpo ilẹ̀kun si mì nipa ohùn ẹniti o ke, ile na si kún fun ẹ̃fin. Nigbana ni mo wipe, Egbe ni fun mi, nitori mo gbé, nitoriti mo jẹ́ ẹni alaimọ́ etè, mo si wà lãrin awọn enia alaimọ́ etè, nitoriti oju mi ti ri Ọba, Oluwa awọn ọmọ-ogun. Nigbana ni ọkan ninu awọn serafu fò wá sọdọ mi, o ni ẹṣẹ́-iná li ọwọ́ rẹ̀, ti o ti fi ẹmú mu lati ori pẹpẹ wá. O si fi kàn mi li ẹnu, o si wipe, Kiyesi i, eyi ti kàn etè rẹ, a mu aiṣedede rẹ kuro, a si fọ ẹ̀ṣẹ rẹ nù. Emi si gbọ́ ohùn Oluwa pẹlu wipe, Tali emi o rán, ati tani yio si lọ fun wa? Nigbana li emi wipe, Emi nĩ; rán mi. On si wipe, Lọ, ki o si wi fun awọn enia yi, Ni gbigbọ́, ẹ gbọ́, ṣugbọn oye ki yio ye nyin; ni riri, ẹ ri, ṣugbọn ẹnyin ki yio si mọ̀ oye. Mu ki aiya awọn enia yi ki o sebọ́, mú ki eti wọn ki o wuwo, ki o si di wọn li oju, ki nwọn ki o má ba fi eti wọn gbọ́, ki nwọn ki o má ba fi ọkàn wọn mọ̀, ki nwọn ki o má ba yipada, ki a má ba mu wọn li ara dá. Nigbana ni emi wipe, Oluwa, yio ti pẹ to? O si dahùn pe, Titi awọn ilu-nla yio fi di ahoro, li aisi olugbe, ati awọn ile li aisi enia, ati ilẹ yio di ahoro patapata. Titi Oluwa yio fi ṣi awọn enia na kuro lọ rére, ti ikọ̀silẹ nla yio si wà ni inu ilẹ na. Ṣugbọn sibẹ, idamẹwa yio wà ninu rẹ̀, yio si padà, yio si di rirun, bi igi teili, ati bi igi oakù eyiti ọpá wà ninu wọn, nigbati ewe wọn ba rẹ̀: bẹ̃ni iru mimọ́ na yio jẹ ọpá ninu rẹ̀.

Isa 6:1-13 Yoruba Bible (YCE)

Ní ọdún tí Usaya Ọba kú, mo rí OLUWA: ó jókòó lórí ìtẹ́, a gbé e ga sókè, aṣọ ìgúnwà rẹ̀ sì kún inú tẹmpili. Àwọn Serafu dúró lókè rẹ̀. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu wọn ní ìyẹ́ mẹfa mẹfa: ó fi meji bo ojú, ó fi meji bo ẹsẹ̀, ó sì ń fi meji fò. Ekinni ń ké sí ekeji pé: “Mímọ́, mímọ́, mímọ́ ni OLUWA àwọn ọmọ ogun; gbogbo ayé kún fún ògo rẹ̀.” Ìpìlẹ̀ ilé náà mì títí nígbà tí ẹni náà kígbe, èéfín sì kún ilé náà. Mo bá pariwo, mo ní, “Mo gbé! Mo ti sọnù, nítorí pé ọ̀rọ̀ ẹnu mi kò mọ́, ọ̀rọ̀ ẹnu àwọn tí mò ń gbé ààrin wọn náà kò sì mọ́. Bẹ́ẹ̀ sì ni mo ti fi ojú rí Ọba, OLUWA àwọn ọmọ ogun.” Ọ̀kan ninu àwọn Serafu náà bá fi ẹ̀mú mú ẹ̀yinná kan lórí pẹpẹ, ó mú un lọ́wọ́, ó bá fò wá sọ́dọ̀ mi. Ó sì fi ògúnná náà kàn mí lẹ́nu, ó ní: “Wò ó, èyí ti kàn ọ́ ní ètè: A ti mú ẹ̀bi rẹ kúrò, a sì ti dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.” Mo wá gbọ́ ohùn OLUWA ó ní, “Ta ni kí n rán? Ta ni yóo lọ fún wa?” Mo bá dáhùn, mo ní: “Èmi nìyí, rán mi.” OLUWA bá ní: “Lọ, sọ fún àwọn eniyan wọnyi pé; wọn óo gbọ́ títí, ṣugbọn kò ní yé wọn; wọn óo wò títí, ṣugbọn wọn kò ní rí nǹkankan. Mú kí ọkàn àwọn eniyan wọnyi ó yigbì, jẹ́ kí etí wọn di. Fi nǹkan bò wọ́n lójú, kí wọn má baà ríran, kí wọn má sì gbọ́ràn, kí òye má baà yé wọn, kí wọn má baà yipada, kí wọn sì rí ìwòsàn.” Mo bá bi í pé: “OLUWA mi, títí di ìgbà wo?” Ó sì dáhùn pé: “Títí tí àwọn ìlú yóo fi di ahoro, láìsí ẹni tí yóo máa gbé inú wọn; títí tí ilé yóo fi tú láì ku ẹnìkan, títí tí ilẹ̀ náà yóo fi di ahoro patapata. Tí OLUWA yóo kó àwọn eniyan lọ sí ilẹ̀ òkèèrè, tí ibi tí a kọ̀tì yóo sì di pupọ ní ilẹ̀ náà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdámẹ́wàá àwọn eniyan náà ni ó kù ní ilẹ̀ náà, sibẹsibẹ iná yóo tún jó o bí igi terebinti tabi igi Oaku, tí kùkùté rẹ̀ wà lórí ilẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n gé e lulẹ̀.” Èso mímọ́ ni kùkùté rẹ̀.

Isa 6:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ní ọdún tí ọba Ussiah kú, mo rí Olúwa tí ó jókòó lórí ìtẹ́ tí ó ga tí a gbé sókè, ìṣẹ́tí aṣọ ìgúnwà rẹ̀ sì kún inú tẹmpili. Àwọn Serafu wà ní òkè rẹ̀, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ìyẹ́ mẹ́fà, wọ́n fi ìyẹ́ méjì bo ojú wọn, wọ́n fi méjì bo ẹsẹ̀ wọn, wọ́n sí ń fi méjì fò. Wọ́n sì ń kọ sí ara wọn wí pé: “Mímọ́, mímọ́, mímọ́ ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun gbogbo ayé kún fún ògo rẹ̀.” Nípa ìró ohùn un wọn, òpó ìlẹ̀kùn àti gbogbo ògiri ilé náà sì mì tìtì, gbogbo inú tẹmpili sì kún fún èéfín. Mo kígbe pé “Ègbé ni fún mi! Mo ti gbé!” Nítorí mo jẹ́ ènìyàn aláìmọ́ ètè, mo sì ń gbé láàrín àwọn ènìyàn aláìmọ́ ètè, ojú mi sì ti rí ọba, OLúWA àwọn ọmọ-ogun jùlọ. Nígbà náà ni ọ̀kan nínú àwọn Serafu wọ̀nyí fò wá sí ọ̀dọ̀ mi pẹ̀lú ẹ̀yín iná ní ọwọ́ rẹ̀, èyí tí ó ti fi ẹ̀mú mú ní orí pẹpẹ. Èyí ni ó fi kàn mí ní ẹnu tí ó sì wí pé, “Wò ó, èyí ti kan ètè rẹ; a ti mú ẹ̀bi rẹ kúrò, a sì ti wẹ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ nù.” Nígbà náà ni mo sì gbọ́ ohùn Olúwa wí pé, “Ta ni èmi yóò rán? Ta ni yóò sì lọ fún wa?” Nígbà náà ni èmi sì wí pé, “Èmi nìyí, rán mi!” Òun sì wí pé, “Tọ àwọn ènìyàn yìí lọ kí o sì wí fún wọn pé: “ ‘Ní gbígbọ́ ẹ̀yin yóò gbọ́, kì yóò sì yé e yín; ní rí rí ẹ̀yin yóò ri, ẹ̀yin kì yóò mọ òye.’ Mú kí àyà àwọn ènìyàn wọ̀nyí yigbì, mú kí etí wọn kí ó wúwo, kí o sì dìwọ́n ní ojú. Kí wọn kí ó má ba fi ojú wọn ríran, kí wọn kí ó má ba fi etí wọn gbọ́rọ̀, kí òye kí ó má ba yé ọkàn wọn, kí wọn kí ó má ba yípadà kí a má ba mú wọn ní ara dá.” Nígbà náà ni mo wí pé, “Báwo ni yóò ti pẹ́ tó OLúWA?” Òun sì dáhùn pé: “Títí àwọn ìlú ńlá yóò fi dahoro, láìsí olùgbé nínú rẹ̀ mọ́, títí tí àwọn ilé yóò fi wà láìsí ènìyàn, títí tí ilẹ̀ yóò fi dahoro pátápátá. Títí tí OLúWA yóò fi rán gbogbo wọn jìnnà réré tí ilẹ̀ náà sì di ìkọ̀sílẹ̀ pátápátá. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdámẹ́wàá ṣẹ́kù lórí ilẹ̀ náà, yóò sì tún pàpà padà di rírun. Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí igi tẹrẹbinti àti igi óákù, ti í fi kùkùté sílẹ̀ nígbà tí a bá gé wọn lulẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni irúgbìn mímọ́ náà yóò di kùkùté ní ilẹ̀ náà.”