Isa 58:6-12
Isa 58:6-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
Awẹ ti mo ti yàn kọ́ eyi? lati tú ọjá aiṣododo, lati tú ẹrù wiwo, ati lati jẹ ki anilara lọ lọfẹ, ati lati já gbogbo ajàga. Kì ha ṣe lati fi onjẹ rẹ fun awọn ti ebi npa, ati ki iwọ ki o mu awọn otòṣi ti a tì sode wá si ile rẹ? nigbati iwọ ba ri arinhòho, ki iwọ ki o bò o, ki iwọ, ki o má si fi ara rẹ pamọ kuro lọdọ ẹran-ara tirẹ. Nigbana ni imọlẹ rẹ yio bẹ́ jade bi owurọ, ilera rẹ yio sọ jade kánkán: ododo rẹ yio si lọ ṣaju rẹ; ogo Oluwa yio kó ọ jọ. Nigbana ni iwọ o pè, Oluwa yio si dahun; iwọ o kigbe, on o si wipe, Emi nĩ. Bi iwọ ba mu àjaga, ninà ika, ati sisọ asan, kuro lãrin rẹ. Bi iwọ ba fà ọkàn rẹ jade fun ẹniti ebi npa, ti o si tẹ́ ọkàn ti a npọ́n loju lọrùn, nigbana ni imọlẹ rẹ yio si là ninu okùnkun, ati okùnkun rẹ bi ọ̀san gangan. Oluwa yio ma tọ́ ọ nigbagbogbo, yio si tẹ́ ọkàn rẹ lọrun ni ibi gbigbẹ, yio si mu egungun rẹ sanra; iwọ o si dabi ọgbà ti a bomirin, ati bi isun omi ti omi rẹ̀ ki itán. Ati awọn tirẹ yio mọ ibi ahoro atijọ wọnni: iwọ o gbé ipilẹ iran ọ̀pọlọpọ ró, a o si ma pe ọ ni, Alatunṣe ẹyà nì, Olumupada ọ̀na wọnni lati gbe inu rẹ̀.
Isa 58:6-12 Yoruba Bible (YCE)
“Ṣebí irú ààwẹ̀ tí mo yàn ni pé: kí á tú ìdè ìwà burúkú, kí á yọ irin tí a fi di igi àjàgà; kí á dá àwọn tí ìyà ń jẹ sílẹ̀ lọ́fẹ̀ẹ́, kí á já gbogbo àjàgà? Àní kí ẹ fún ẹni tí ebi ń pa ní oúnjẹ, kí ẹ mú àwọn òtòṣì aláìnílé wá sinu ilé yín, bí ẹ bá rí ẹnikẹ́ni ní ìhòòhò, kí ẹ fi aṣọ bò ó, kí ẹ má sì fojú pamọ́ fún ẹni tí ó jẹ́ ẹbí yín. “Nígbà náà ni ìmọ́lẹ̀ yín yóo tàn bí ìgbà tí ilẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ́, ara yín yóo sì tètè yá. Òdodo yín yóo máa tàn níwájú yín. Ògo mi yóo ṣe ààbò lẹ́yìn yín. Ẹ óo ké pè mí nígbà náà, n óo sì da yín lóhùn. Ẹ óo kígbe pè mí, n óo sì dáhùn pé, ‘Èmi nìyí.’ “Bí ẹ bá mú àjàgà kúrò láàrin yín, tí ẹ kò fi ìka gún ara yín nímú mọ́, tí ẹ kò sì sọ ọ̀rọ̀ ibi mọ́. Bí ẹ bá ṣe làálàá láti fún ẹni tí ebi ń pa ní oúnjẹ, tí ẹ sì wá ọ̀nà ìtẹ́lọ́rùn fún ẹni tí ìyà ń jẹ, ìmọ́lẹ̀ yín yóo tàn ninu òkùnkùn, òkùnkùn biribiri yín yóo dàbí ọ̀sán. N óo máa tọ yín sọ́nà nígbà gbogbo, n óo fi nǹkan rere tẹ yín lọ́rùn; n óo mú kí egungun yín ó le, ẹ óo sì dàbí ọgbà tí à ń bomi rin, ati bí orísun omi, tí omi rẹ̀ kì í gbẹ. Ẹ óo tún odi yín tí ó ti wó lulẹ̀ mọ, ẹ óo sì gbé àwọn ìpilẹ̀ṣẹ̀ àtijọ́ dìde. Àwọn eniyan yóo máa pè yín ní alátùn-únṣe ibi tí odi ti wó, alátùn-únṣe òpópónà àdúgbò fún gbígbé.
Isa 58:6-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ǹjẹ́ irú àwẹ̀ tí mo ti yàn kọ́ ni èyí: láti já gbogbo ẹ̀wọ̀n àìṣòdodo àti láti tú gbogbo okùn àjàgà, láti tú gbogbo àwọn ti à ń ni lára sílẹ̀ àti láti fọ́ gbogbo àjàgà? Kì í ha á ṣe láti pín oúnjẹ yín fún àwọn tí ebi ń pa àti láti pèsè ibùgbé fún àwọn òtòṣì tí ń rìn káàkiri. Nígbà tí ẹ bá rí ẹni tí ó wà níhòhò, láti daṣọ bò ó, àti láti má ṣe lé àwọn ìbátan yín sẹ́yìn? Nígbà náà ni ìmọ́lẹ̀ rẹ yóò tàn jáde bí òwúrọ̀ àti ìmúláradá rẹ yóò farahàn kíákíá; nígbà náà ni òdodo rẹ yóò sì lọ níwájú rẹ, ògo OLúWA yóò sì jẹ́ ààbò lẹ́yìn rẹ. Nígbà yìí ni ẹ̀yin yóò pè, tí OLúWA yóò sì dáhùn; ẹ̀yin yóò kígbe fún ìrànlọ́wọ́, òun yóò sì wí pé: Èmi nìyí. “Bí ìwọ bá mú àjàgà aninilára, nínà ìka àlébù àti sísọ ọ̀rọ̀ asán kúrò láàrín rẹ, àti bí ẹ̀yin bá ná ara yín bí owó nítorí àwọn tí ebi ń pa tí ẹ sì tẹ́ ìfẹ́ àwọn tí à ń ni lára lọ́rùn, nígbà náà ni ìmọ́lẹ̀ yín yóò ràn nínú òkùnkùn, àti òru yín yóò dàbí ọ̀sán gangan. OLúWA yóò máa tọ́ ọ yín nígbà gbogbo; òun yóò tẹ́ gbogbo àìní yín lọ́rùn ní ilẹ̀ tí oòrùn ń tan ìmọ́lẹ̀ yóò sì fún egungun rẹ lókun. Ìwọ yóò sì dàbí ọgbà tí a bomirin dáradára, àti bí orísun tí omi rẹ̀ kì í gbẹ. Àwọn ènìyàn rẹ yóò tún ahoro àtijọ́ kọ́ wọn yóò sì gbé ìpìlẹ̀ àtijọ́-tijọ́ ró a ó sì pè ọ́ ní alátúnṣe ògiri tí ó ti wó àti olùmúbọ̀sípò àwọn òpópónà tí ènìyàn gbé inú rẹ̀.