Isa 58:5-6
Isa 58:5-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ãwẹ̀ iru eyi ni mo yàn bi? ọjọ ti enia njẹ ọkàn rẹ̀ ni ìya? lati tẹ ori rẹ̀ ba bi koriko odo? ati lati tẹ́ aṣọ ọ̀fọ ati ẽru labẹ rẹ̀? iwọ o ha pe eyi ni ãwẹ̀, ati ọjọ itẹwọgba fun Oluwa? Awẹ ti mo ti yàn kọ́ eyi? lati tú ọjá aiṣododo, lati tú ẹrù wiwo, ati lati jẹ ki anilara lọ lọfẹ, ati lati já gbogbo ajàga.
Isa 58:5-6 Yoruba Bible (YCE)
Ṣé irú ààwẹ̀ tí mo yàn nìyí, ọjọ́ tí eniyan yóo rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ lásán? Ṣé kí eniyan lè doríkodò bíi koríko etí odò nìkan ni? Tabi kí ó lè jókòó lórí aṣọ ọ̀fọ̀ ati eérú nìkan? Ṣé èyí ni ẹ̀ ń pè ní ààwẹ̀, ati ọjọ́ tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ OLUWA? “Ṣebí irú ààwẹ̀ tí mo yàn ni pé: kí á tú ìdè ìwà burúkú, kí á yọ irin tí a fi di igi àjàgà; kí á dá àwọn tí ìyà ń jẹ sílẹ̀ lọ́fẹ̀ẹ́, kí á já gbogbo àjàgà?
Isa 58:5-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)
Ǹjẹ́ èyí ha ni irú àwẹ̀ tí mo yàn bí, ọjọ́ kan ṣoṣo fún ènìyàn láti rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀? Ó ha jẹ pe kí ènìyàn tẹ orí rẹ̀ ba bí i koríko lásán ni bí àti sísùn nínú aṣọ ọ̀fọ̀ àti eérú? Ṣé ohun tí ẹ̀ ń pè ní àwẹ̀ nìyí, ọjọ́ ìtẹ́wọ́gbà fún OLúWA? “Ǹjẹ́ irú àwẹ̀ tí mo ti yàn kọ́ ni èyí: láti já gbogbo ẹ̀wọ̀n àìṣòdodo àti láti tú gbogbo okùn àjàgà, láti tú gbogbo àwọn ti à ń ni lára sílẹ̀ àti láti fọ́ gbogbo àjàgà?