Isa 58:1-4
Isa 58:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
KE rara, máṣe dasi, gbe ohùn rẹ soke bi ipè, ki o si fi irekọja awọn enia mi hàn wọn, ati ile Jakobu, ẹ̀ṣẹ wọn. Ṣugbọn nwọn nwá mi lojojumọ, nwọn si ni inu didun lati mọ̀ ọ̀na mi, bi orilẹ-ède ti nṣe ododo, ti kò si fi ilàna Ọlọrun wọn silẹ: nwọn mbere ilàna ododo wọnnì lọwọ mi; nwọn a ma ṣe inu didun ati sunmọ Ọlọrun. Nitori kini awa ṣe ngbãwẹ̀, ti iwọ kò si ri i? nitori kini awa jẹ ọkàn wa ni ìya, ti iwọ kò si mọ̀? Kiyesi i, li ọjọ ãwẹ̀ nyin ẹnyin nṣe afẹ́, ẹ si nfi agbara mu ni ṣe gbogbo iṣẹ nyin. Kiyesi i, ẹnyin ngbãwẹ̀ fun ìja ati ãwọ̀, ati lilù, nipa ikũku ìwa-buburu: ẹ máṣe gbãwẹ bi ti ọjọ yi, ki a le gbọ́ ohùn nyin li oke.
Isa 58:1-4 Yoruba Bible (YCE)
“Kígbe sókè, má dákẹ́, ké sókè bíi fèrè ogun, sọ ìrékọjá àwọn eniyan mi fún wọn ní àsọyé, sọ ẹ̀ṣẹ̀ ilé Jakọbu fún wọn. Nítòótọ́ ni wọ́n ń wá mi lojoojumọ, wọ́n sì fẹ́ mọ ìlànà mi, wọ́n ṣe bí orílẹ̀-èdè tí ó mọ òdodo, tí kò kọ òfin Ọlọrun wọn sílẹ̀. Wọ́n ń bèèrè ìdájọ́ òdodo lọ́dọ̀ mi, wọ́n ní ìfẹ́ ati súnmọ́ Ọlọrun.” Wọ́n ń bèèrè pé, “Kí ló dé tí à ń gbààwẹ̀, ṣugbọn tí OLUWA kò rí wa? Tí à ń fìyà jẹ ara wa, ṣugbọn tí kò náání wa?” OLUWA wí pé, “Ìdí rẹ̀ ni pé, nígbà tí ẹ bá ń gbààwẹ̀, ẹ̀ máa ṣe ìfẹ́ ọkàn yín. Ẹ̀ sì máa ni gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ yín lára. Ẹ̀ ń kún fún ìjà ati asọ̀ ní àkókò ààwẹ̀ yín, ẹ̀ ń lu ara yín ní ìlù ìkà. Irú ààwẹ̀ tí ẹ̀ ń gbà yìí kò ní jẹ́ kí Ọlọrun gbọ́ ohùn yín lọ́run.
Isa 58:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Kígbe rẹ̀ sókè, má ṣe fàsẹ́yìn. Gbé ohùn rẹ sókè bí i ti fèrè. Jẹ́ kí ó di mí mọ̀ fún àwọn ènìyàn mi, ọ̀tẹ̀ wọn àti fún ilé Jakọbu ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Nítorí ọjọ́ dé ọjọ́ ni wọ́n ń wá mi kiri; wọ́n ṣe bí ẹni ní ìtara láti mọ ọ̀nà mi, àfi bí ẹni pé wọ́n jẹ́ orílẹ̀-èdè kan tí ń ṣe ohun tí ó tọ̀nà tí òun kò sì tí ì kọ àṣẹ Ọlọ́run rẹ̀. Wọ́n ń béèrè lọ́wọ́ mi fún ìpinnu nìkan wọ́n sì ṣe bí ẹni ń tara fún Ọlọ́run láti súnmọ́ ọ̀dọ̀ wọn. ‘Èéṣe tí àwa fi ń gbààwẹ̀,’ ni wọ́n wí, ‘tí ìwọ kò sì tí ì rí? Èéṣe tí àwa fi rẹra wa sílẹ̀, tí ìwọ kò sì tí ì ṣe àkíyèsí?’ “Síbẹ̀síbẹ̀ ní ọjọ́ àwẹ̀ yín, ẹ̀yin ń ṣe bí ó ti wù yín ẹ sì ń pọ́n àwọn òṣìṣẹ́ yín gbogbo lójú. Àwẹ̀ yín sì parí nínú ìjà àti asọ̀, àti lílu ọmọnìkejì ẹni pa pẹ̀lú ìkùùkuu. Ẹ̀yin kò le è gbààwẹ̀ bí ẹ ti ń ṣe lónìí kí ẹ sì retí kí a gbọ́ ohùn un yín ní ibi gíga.