Isa 55:8-10
Isa 55:8-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori èro mi kì iṣe èro nyin, bẹ̃ni ọ̀na nyin kì iṣe ọ̀na mi, li Oluwa wi. Nitori bi ọrun ti ga ju aiye lọ, bẹ̃ni ọ̀na mi ga ju ọ̀na nyin lọ, ati èro mi ju èro nyin lọ. Nitori gẹgẹ bi òjo ati ojo-didì ti iti ọrun wá ilẹ, ti kì isi tun pada sọhun, ṣugbọn ti o nrin ilẹ, ti o si nmu nkan hù jade ki o si rudi, ki o le fi irú fun awọn afúnrúgbìn, ati onjẹ fun ọjẹun
Isa 55:8-10 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA ní, “Nítorí èrò tèmi yàtọ̀ sí tiyín, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà mi yàtọ̀ sí tiyín, Bí ọ̀run ṣe ga ju ayé lọ, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà mi ga ju ọ̀nà yín, tí èrò mi sì ga ju èrò yín. “Bí òjò ati yìnyín, tí ń rọ̀ láti ojú ọ̀run, tí wọn kì í pada sibẹ mọ́, ṣugbọn tí wọn ń bomi rin ilẹ̀, tí ń mú kí nǹkan hù jáde; kí àgbẹ̀ lè rí èso gbìn, kí eniyan sì rí oúnjẹ jẹ.
Isa 55:8-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Nítorí èrò mi kì í ṣe èrò yín, tàbí ọ̀nà yín a ha máa ṣe ọ̀nà mi,” ni OLúWA wí. “Gẹ́gẹ́ bí ọ̀run ti ga ju ayé lọ, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà mi ga ju ọ̀nà yín lọ àti èrò mi ju èrò yín lọ. Gẹ́gẹ́ bí òjò àti yìnyín ti wálẹ̀ láti ọ̀run tí kì í sì padà sí ibẹ̀ láì bomirin ilẹ̀ kí ó sì mú kí ó tanná kí ó sì rudi, tó bẹ́ẹ̀ tí yóò fi mú irúgbìn fún afúnrúgbìn àti àkàrà fún ọ̀jẹun