Isa 55:6-13
Isa 55:6-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ wá Oluwa nigbati ẹ le ri i, ẹ pè e nigbati o wà nitosí. Jẹ ki enia buburu kọ̀ ọ̀na rẹ̀ silẹ, ki ẹ̀lẹṣẹ si kọ̀ ironu rẹ̀ silẹ: si jẹ ki o yipada si Oluwa, on o si ṣãnu fun u, ati si Ọlọrun wa, yio si fi jì li ọpọlọpọ. Nitori èro mi kì iṣe èro nyin, bẹ̃ni ọ̀na nyin kì iṣe ọ̀na mi, li Oluwa wi. Nitori bi ọrun ti ga ju aiye lọ, bẹ̃ni ọ̀na mi ga ju ọ̀na nyin lọ, ati èro mi ju èro nyin lọ. Nitori gẹgẹ bi òjo ati ojo-didì ti iti ọrun wá ilẹ, ti kì isi tun pada sọhun, ṣugbọn ti o nrin ilẹ, ti o si nmu nkan hù jade ki o si rudi, ki o le fi irú fun awọn afúnrúgbìn, ati onjẹ fun ọjẹun: Bẹ̃ni ọ̀rọ mi ti o ti ẹnu mi jade yio ri: kì yio pada sọdọ mi lofo, ṣugbọn yio ṣe eyiti o wù mi, yio si ma ṣe rere ninu ohun ti mo rán a. Nitori ayọ̀ li ẹ o fi jade, alafia li a o fi tọ́ nyin: awọn oke-nla ati awọn oke kékèké yio bú si orin niwaju nyin, gbogbo igi igbẹ́ yio si ṣapẹ́. Igi firi yio hù jade dipò ẹgún, igi mirtili yio hù jade dipò oṣuṣu: yio si jẹ orukọ fun Oluwa, fun àmi aiyeraiye, ti a kì yio ke kuro.
Isa 55:6-13 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ wá OLUWA nígbà tí ẹ lè rí i, ẹ pè é nígbà tí ó wà nítòsí. Kí eniyan burúkú fi ọ̀nà ibi rẹ̀ sílẹ̀, kí alaiṣododo kọ èrò burúkú rẹ̀ sílẹ̀, kí ó yipada sí OLUWA, kí OLUWA lè ṣàánú rẹ̀. Kí ó yipada sọ́dọ̀ Ọlọrun wa, nítorí Ọlọrun yóo dáríjì í lọpọlọpọ. OLUWA ní, “Nítorí èrò tèmi yàtọ̀ sí tiyín, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà mi yàtọ̀ sí tiyín, Bí ọ̀run ṣe ga ju ayé lọ, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà mi ga ju ọ̀nà yín, tí èrò mi sì ga ju èrò yín. “Bí òjò ati yìnyín, tí ń rọ̀ láti ojú ọ̀run, tí wọn kì í pada sibẹ mọ́, ṣugbọn tí wọn ń bomi rin ilẹ̀, tí ń mú kí nǹkan hù jáde; kí àgbẹ̀ lè rí èso gbìn, kí eniyan sì rí oúnjẹ jẹ. Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ tó ń jáde lẹ́nu mi yóo rí, kò ní pada sí ọ̀dọ̀ mi lọ́wọ́ òfo, ṣugbọn yóo ṣe ohun tí mo fẹ́ kí ó ṣe, yóo sì ṣe é ní àṣeyọrí. “Nítorí tayọ̀tayọ̀ ni ẹ óo fi máa jáde ní Babiloni, alaafia ni wọ́n óo fi máa sìn yín sọ́nà, òkè ńlá ati kéékèèké yóo máa kọrin níwájú yín. Gbogbo igi inú igbó yóo sì máa pàtẹ́wọ́, igi Sipirẹsi ni yóo máa hù dípò igi ẹlẹ́gùn-ún, igi Mitili ni yóo sì máa hù dípò ẹ̀gún ọ̀gàn, yóo jẹ́ àmì ìrántí fún OLUWA, ati àpẹẹrẹ ayérayé tí a kò ní parẹ́.”
Isa 55:6-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ wá OLúWA nígbà tí ẹ lè rí i; ẹ pè é nígbà tí ó wà nítòsí. Jẹ́ kí ìkà kí ó kọ ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀ àti ènìyàn búburú èrò rẹ̀. Jẹ́ kí ó yípadà sí OLúWA, Òun yóò sì ṣàánú fún un, àti sí Ọlọ́run wa, nítorí Òun yóò sì dáríjì. “Nítorí èrò mi kì í ṣe èrò yín, tàbí ọ̀nà yín a ha máa ṣe ọ̀nà mi,” ni OLúWA wí. “Gẹ́gẹ́ bí ọ̀run ti ga ju ayé lọ, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà mi ga ju ọ̀nà yín lọ àti èrò mi ju èrò yín lọ. Gẹ́gẹ́ bí òjò àti yìnyín ti wálẹ̀ láti ọ̀run tí kì í sì padà sí ibẹ̀ láì bomirin ilẹ̀ kí ó sì mú kí ó tanná kí ó sì rudi, tó bẹ́ẹ̀ tí yóò fi mú irúgbìn fún afúnrúgbìn àti àkàrà fún ọ̀jẹun, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ mi tí ó jáde láti ẹnu mi wá; kì yóò padà sọ́dọ̀ mi lọ́wọ́ òfo, ṣùgbọ́n yóò ṣe ohun tí mo fẹ́, yóò sì mú ète mi tí mo fi rán an wá sí ìmúṣẹ. Ẹ̀yin yóò jáde lọ ní ayọ̀ a ó sì darí i yín lọ ní àlàáfíà; òkè ńláńlá àti kéékèèkéé yóò bú sí orin níwájú yín àti gbogbo igi inú pápá yóò máa pàtẹ́wọ́. Dípò igi ẹ̀gún ni igi junifa yóò máa dàgbà, àti dípò ẹ̀wọ̀n, maritili ni yóò yọ. Èyí yóò wà fún òkìkí OLúWA, fún ààmì ayérayé, tí a kì yóò lè parun.”