Isa 55:1-3
Isa 55:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
NJẸ gbogbo ẹniti ongbẹ ngbẹ, ẹ wá sibi omi, ati ẹniti kò li owo; ẹ wá, ẹ rà, ki ẹ si jẹ; lõtọ, ẹ wá, ẹ rà ọti-waini ati wàra, laini owo ati laidiyele. Nitori kini ẹ ṣe nná owo fun eyiti kì iṣe onjẹ? ati lãla nyin fun eyi ti kì itẹnilọrun? ni gbigbọ́, ẹ gbọ́ t'emi, ki ẹ si jẹ eyi ti o dara, si jẹ ki inu nyin dùn ninu ọra. Ẹ tẹtilelẹ, ki ẹ si wá sọdọ mi: ẹ gbọ́, ọkàn nyin yio si yè: emi o si ba nyin dá majẹmu ainipẹkun, ãnu Dafidi ti o daju.
Isa 55:1-3 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA ní, “Gbogbo ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ, ẹ máa bọ̀ níbi tí omi wà; bí ẹ kò tilẹ̀ lówó lọ́wọ́, ẹ wá ra oúnjẹ kí ẹ sì jẹ. Ẹ wá ra ọtí waini láì mú owó lọ́wọ́, kí ẹ sì ra omi wàrà, tí ẹnikẹ́ni kò díyelé. Kí ló dé tí ẹ̀ ń ná owó yín lórí ohun tí kì í ṣe oúnjẹ? Tí ẹ sì ń ṣe làálàá lórí ohun tí kì í tẹ́ni lọ́rùn? Ẹ fetí sí ọ̀rọ̀ mi dáradára, kí ẹ sì jẹ ohun tí ó dára, ẹ jẹ oúnjẹ aládùn, kí inú yín ó dùn. “Ẹ tẹ́tí sílẹ̀ kí ẹ súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi, ẹ gbọ́ ohun tí mò ń wí kí ẹ lè yè. N óo ba yín dá majẹmu ayérayé, ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀ tí mo ṣe ìlérí fún Dafidi.
Isa 55:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ẹ wá, gbogbo ẹ̀yin tí òǹgbẹ ń gbẹ, ẹ wá sí ibi omi; àti ẹ̀yin tí kò ní owó; ẹ wá, ẹ rà kí ẹ sì jẹ! Ẹ wá ra wáìnì àti wàrà láìsí owó àti láìdíyelé. Èéṣe tí ẹ fi ń ná owó fún èyí tí kì í ṣe àkàrà àti làálàá yín lórí ohun tí kì í tẹ́nilọ́rùn? Tẹ́tí sílẹ̀, tẹ́tí sí mi, kí ẹ sì jẹ èyí tí ó dára, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn yín yóò láyọ̀ nínú ọrọ̀ tí ó bójúmu. Tẹ́tí sílẹ̀ kí o sì wá sọ́dọ̀ mi gbọ́ tèmi, kí ọkàn rẹ lè wà láààyè. Èmi yóò dá májẹ̀mú ayérayé pẹ̀lú rẹ, ìfẹ́ òtítọ́ tí mo ṣèlérí fún Dafidi.