Isa 55:1-11

Isa 55:1-11 Bibeli Mimọ (YBCV)

NJẸ gbogbo ẹniti ongbẹ ngbẹ, ẹ wá sibi omi, ati ẹniti kò li owo; ẹ wá, ẹ rà, ki ẹ si jẹ; lõtọ, ẹ wá, ẹ rà ọti-waini ati wàra, laini owo ati laidiyele. Nitori kini ẹ ṣe nná owo fun eyiti kì iṣe onjẹ? ati lãla nyin fun eyi ti kì itẹnilọrun? ni gbigbọ́, ẹ gbọ́ t'emi, ki ẹ si jẹ eyi ti o dara, si jẹ ki inu nyin dùn ninu ọra. Ẹ tẹtilelẹ, ki ẹ si wá sọdọ mi: ẹ gbọ́, ọkàn nyin yio si yè: emi o si ba nyin dá majẹmu ainipẹkun, ãnu Dafidi ti o daju. Kiye si i, emi ti fi on fun awọn enia fun ẹlẹri, olori ati alaṣẹ fun awọn enia. Kiyesi i, iwọ o pe orilẹ-ède ti iwọ kò mọ̀, ati orilẹ-ède ti kò mọ̀ ọ yio sare wá sọdọ rẹ, nitori Oluwa Ọlọrun rẹ, ati nitori Ẹni-Mimọ Israeli; nitori on ti ṣe ọ li ogo. Ẹ wá Oluwa nigbati ẹ le ri i, ẹ pè e nigbati o wà nitosí. Jẹ ki enia buburu kọ̀ ọ̀na rẹ̀ silẹ, ki ẹ̀lẹṣẹ si kọ̀ ironu rẹ̀ silẹ: si jẹ ki o yipada si Oluwa, on o si ṣãnu fun u, ati si Ọlọrun wa, yio si fi jì li ọpọlọpọ. Nitori èro mi kì iṣe èro nyin, bẹ̃ni ọ̀na nyin kì iṣe ọ̀na mi, li Oluwa wi. Nitori bi ọrun ti ga ju aiye lọ, bẹ̃ni ọ̀na mi ga ju ọ̀na nyin lọ, ati èro mi ju èro nyin lọ. Nitori gẹgẹ bi òjo ati ojo-didì ti iti ọrun wá ilẹ, ti kì isi tun pada sọhun, ṣugbọn ti o nrin ilẹ, ti o si nmu nkan hù jade ki o si rudi, ki o le fi irú fun awọn afúnrúgbìn, ati onjẹ fun ọjẹun: Bẹ̃ni ọ̀rọ mi ti o ti ẹnu mi jade yio ri: kì yio pada sọdọ mi lofo, ṣugbọn yio ṣe eyiti o wù mi, yio si ma ṣe rere ninu ohun ti mo rán a.

Isa 55:1-11 Yoruba Bible (YCE)

OLUWA ní, “Gbogbo ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ, ẹ máa bọ̀ níbi tí omi wà; bí ẹ kò tilẹ̀ lówó lọ́wọ́, ẹ wá ra oúnjẹ kí ẹ sì jẹ. Ẹ wá ra ọtí waini láì mú owó lọ́wọ́, kí ẹ sì ra omi wàrà, tí ẹnikẹ́ni kò díyelé. Kí ló dé tí ẹ̀ ń ná owó yín lórí ohun tí kì í ṣe oúnjẹ? Tí ẹ sì ń ṣe làálàá lórí ohun tí kì í tẹ́ni lọ́rùn? Ẹ fetí sí ọ̀rọ̀ mi dáradára, kí ẹ sì jẹ ohun tí ó dára, ẹ jẹ oúnjẹ aládùn, kí inú yín ó dùn. “Ẹ tẹ́tí sílẹ̀ kí ẹ súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi, ẹ gbọ́ ohun tí mò ń wí kí ẹ lè yè. N óo ba yín dá majẹmu ayérayé, ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀ tí mo ṣe ìlérí fún Dafidi. Wò ó! Mo fi í ṣe olórí fún àwọn eniyan, olórí ati aláṣẹ àwọn orílẹ̀-èdè. O óo pe àwọn orílẹ̀-èdè tí o kò mọ̀ rí, àwọn orílẹ̀-èdè tí kò mọ̀ ọ́ rí yóo sáré wá sọ́dọ̀ rẹ, nítorí OLUWA Ọlọrun rẹ, ati nítorí Ẹni Mímọ́ Israẹli, tí ó ṣe ọ́ lógo.” Ẹ wá OLUWA nígbà tí ẹ lè rí i, ẹ pè é nígbà tí ó wà nítòsí. Kí eniyan burúkú fi ọ̀nà ibi rẹ̀ sílẹ̀, kí alaiṣododo kọ èrò burúkú rẹ̀ sílẹ̀, kí ó yipada sí OLUWA, kí OLUWA lè ṣàánú rẹ̀. Kí ó yipada sọ́dọ̀ Ọlọrun wa, nítorí Ọlọrun yóo dáríjì í lọpọlọpọ. OLUWA ní, “Nítorí èrò tèmi yàtọ̀ sí tiyín, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà mi yàtọ̀ sí tiyín, Bí ọ̀run ṣe ga ju ayé lọ, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà mi ga ju ọ̀nà yín, tí èrò mi sì ga ju èrò yín. “Bí òjò ati yìnyín, tí ń rọ̀ láti ojú ọ̀run, tí wọn kì í pada sibẹ mọ́, ṣugbọn tí wọn ń bomi rin ilẹ̀, tí ń mú kí nǹkan hù jáde; kí àgbẹ̀ lè rí èso gbìn, kí eniyan sì rí oúnjẹ jẹ. Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ tó ń jáde lẹ́nu mi yóo rí, kò ní pada sí ọ̀dọ̀ mi lọ́wọ́ òfo, ṣugbọn yóo ṣe ohun tí mo fẹ́ kí ó ṣe, yóo sì ṣe é ní àṣeyọrí.

Isa 55:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

“Ẹ wá, gbogbo ẹ̀yin tí òǹgbẹ ń gbẹ, ẹ wá sí ibi omi; àti ẹ̀yin tí kò ní owó; ẹ wá, ẹ rà kí ẹ sì jẹ! Ẹ wá ra wáìnì àti wàrà láìsí owó àti láìdíyelé. Èéṣe tí ẹ fi ń ná owó fún èyí tí kì í ṣe àkàrà àti làálàá yín lórí ohun tí kì í tẹ́nilọ́rùn? Tẹ́tí sílẹ̀, tẹ́tí sí mi, kí ẹ sì jẹ èyí tí ó dára, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn yín yóò láyọ̀ nínú ọrọ̀ tí ó bójúmu. Tẹ́tí sílẹ̀ kí o sì wá sọ́dọ̀ mi gbọ́ tèmi, kí ọkàn rẹ lè wà láààyè. Èmi yóò dá májẹ̀mú ayérayé pẹ̀lú rẹ, ìfẹ́ òtítọ́ tí mo ṣèlérí fún Dafidi. Kíyèsi i, mo ti fi òun ṣe ẹlẹ́rìí fún àwọn ènìyàn, olórí àti apàṣẹ fún àwọn ènìyàn. Lóòtítọ́ ìwọ yóò ké sí àwọn orílẹ̀-èdè tí ìwọ kò mọ̀ àti orílẹ̀-èdè tí ìwọ kò mọ̀ ni yóò sáré tọ̀ ọ́ wá, Nítorí OLúWA Ọlọ́run rẹ Ẹni Mímọ́ Israẹli nítorí pé ó ti fi ohun dídára dá ọ lọ́lá.” Ẹ wá OLúWA nígbà tí ẹ lè rí i; ẹ pè é nígbà tí ó wà nítòsí. Jẹ́ kí ìkà kí ó kọ ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀ àti ènìyàn búburú èrò rẹ̀. Jẹ́ kí ó yípadà sí OLúWA, Òun yóò sì ṣàánú fún un, àti sí Ọlọ́run wa, nítorí Òun yóò sì dáríjì. “Nítorí èrò mi kì í ṣe èrò yín, tàbí ọ̀nà yín a ha máa ṣe ọ̀nà mi,” ni OLúWA wí. “Gẹ́gẹ́ bí ọ̀run ti ga ju ayé lọ, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà mi ga ju ọ̀nà yín lọ àti èrò mi ju èrò yín lọ. Gẹ́gẹ́ bí òjò àti yìnyín ti wálẹ̀ láti ọ̀run tí kì í sì padà sí ibẹ̀ láì bomirin ilẹ̀ kí ó sì mú kí ó tanná kí ó sì rudi, tó bẹ́ẹ̀ tí yóò fi mú irúgbìn fún afúnrúgbìn àti àkàrà fún ọ̀jẹun, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ mi tí ó jáde láti ẹnu mi wá; kì yóò padà sọ́dọ̀ mi lọ́wọ́ òfo, ṣùgbọ́n yóò ṣe ohun tí mo fẹ́, yóò sì mú ète mi tí mo fi rán an wá sí ìmúṣẹ.

Isa 55:1-11

Isa 55:1-11 YBCV