Isa 50:4-11
Isa 50:4-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Oluwa Jehofa ti fi ahọn akẹ́kọ fun mi, ki emi ki o le mọ̀ bi a iti sọ̀rọ li akokò fun alãrẹ, o nji li oròwurọ̀, o ṣi mi li eti lati gbọ́ bi akẹkọ. Oluwa Jehofa ti ṣí mi li eti, emi kò si ṣe aigbọràn, bẹ̃ni emi kò yipada. Mo fi ẹ̀hìn mi fun awọn aluni, ati ẹ̀rẹkẹ mi fun awọn ti ntú irun: emi kò pa oju mi mọ́ kuro ninu itìju ati itutọ́ si. Nitori Oluwa Jehofa yio ràn mi lọwọ: nitorina emi kì yio dãmu; nitorina ni mo ṣe gbe oju mi ró bi okuta lile, emi si mọ̀ pe oju kì yio tì mi. Ẹniti o dá mi lare wà ni tosí, tani o ba mi jà? jẹ ki a duro pọ̀: tani iṣe ẹlẹ́jọ mi? jẹ ki o sunmọ mi. Kiye si i, Oluwa Jehofa yio ràn mi lọwọ, tani o dá mi li ẹbi? wò o, gbogbo wọn o di ogbó bi ẹwù; kokòro yio jẹ wọn run. Tani ninu nyin ti o bẹ̀ru Oluwa, ti o gba ohùn iranṣẹ rẹ̀ gbọ́, ti nrìn ninu okùnkun, ti kò si ni imọlẹ? jẹ ki on gbẹkẹ̀le orukọ Oluwa, ki o si fi ẹ̀hìn tì Ọlọrun rẹ̀. Kiye si i, gbogbo ẹnyin ti o dá iná, ti ẹ fi ẹta iná yi ara nyin ká: ẹ mã rìn ninu imọlẹ iná nyin, ati ninu ẹta iná ti ẹ ti dá. Eyi ni yio jẹ ti nyin lati ọwọ́ mi wá; ẹnyin o dubulẹ ninu irora.
Isa 50:4-11 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA Ọlọrun ti fi ọ̀rọ̀ ìmọ̀ sí mi lẹ́nu. Kí n lè mọ bí a tií gba àwọn tí ọkàn wọn rẹ̀wẹ̀sì níyànjú. Ojoojumọ ni ó ń ṣí mi létí láràárọ̀, kí n lè máa gbọ́rọ̀ bí àwọn akẹ́kọ̀ọ́. OLUWA Ọlọrun ti ṣí mi létí, n kò sì ṣe oríkunkun, tabi kí n pada sẹ́yìn. Mo tẹ́ ẹ̀yìn sílẹ̀ fún àwọn tí ń nani lẹ́gba; mo sì kọ ẹ̀rẹ̀kẹ́ sí àwọn tí ń fa eniyan ní irùngbọ̀n tu. N kò fojú pamọ́ nítorí ẹ̀gàn, bẹ́ẹ̀ ni n kò gbójú sá fún itọ́ títu síni lójú. OLUWA Ọlọrun ń ràn mí lọ́wọ́, nítorí náà ojú kò tì mí; nítorí náà mo múra gírí, mo jẹ́ kí ojú mi le koko, mo sì mọ̀ pé ojú kò ní tì mí. Ẹni tí yóo dá mi láre wà nítòsí, ta ló fẹ́ bá mi jà? Ta ló fẹ́ fi ẹ̀sùn kàn mí? Kí olúwarẹ̀ súnmọ́ tòsí mi, kí á jọ kojú ara wa? Wò ó! OLUWA Ọlọrun ń ràn mí lọ́wọ́, ta ni yóo dá mi lẹ́bi? Gbogbo wọn ni yóo gbọ̀n dànù bí aṣọ, kòkòrò yóo sì jẹ wọ́n. Ta ló bẹ̀rù OLUWA ninu yín, tí ń gbọ́ràn sí iranṣẹ rẹ̀ lẹ́nu, tí ń rìn ninu òkùnkùn, tí kò ní ìmọ́lẹ̀, ṣugbọn sibẹ, tí ó gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, tí ó fẹ̀yìn ti Ọlọrun rẹ̀. Gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń dáná, tí ẹ tan iná yí ara yín ká, ẹ máa rìn lọ ninu iná tí ẹ dá; ẹ máa la iná tí ẹ fi yí ara yín ká kọjá. Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe fun yín. Ẹ óo wà ninu ìrora.
Isa 50:4-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA Olódùmarè ti fún mi ni ahọ́n tí a fi iṣẹ́ rán, láti mọ àwọn ọ̀rọ̀ tí ó lè gbé àwọn aláàárẹ̀ ró. O jí mi láràárọ̀, o jí etí mi láti gbọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí à ń kọ́. OLúWA Olódùmarè ti ṣí mi ní etí, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ṣọ̀tẹ̀ rí; Èmi kò sì padà sẹ́yìn. Mo ṣí ẹ̀yìn mi sílẹ̀ fún àwọn tí ó ń nà mí, àti ẹ̀rẹ̀kẹ́ mi fún àwọn tí ń fa irùngbọ̀n mi; Èmi kò fi ojú mi pamọ́ kúrò lọ́wọ́ ẹlẹ́yà àti ìyọṣùtì sí. Nítorí OLúWA Olódùmarè ràn mí lọ́wọ́; A kì yóò dójútì mí. Nítorí náà ni mo ṣe gbé ojú mi ró bí òkúta akọ èmi sì mọ pé, ojú kò ní tì mí. Ẹni tí ó dá mi láre wà nítòsí. Ta ni ẹni náà tí yóò fẹ̀sùn kàn mí? Jẹ́ kí a kojú ara wa! Ta ni olùfisùn mi? Jẹ́ kí ó kò mí lójú! OLúWA Olódùmarè ni ó ń ràn mí lọ́wọ́. Ta ni ẹni náà tí yóò dá mi lẹ́bi? Gbogbo wọn yóò gbó bí aṣọ; kòkòrò ni yóò sì jẹ wọn run. Ta ni nínú yín tí ó bẹ̀rù OLúWA tí ó sì ń gbọ́rọ̀ sí ìránṣẹ́ rẹ̀ lẹ́nu? Jẹ́ kí ẹni tí ń rìn ní òkùnkùn tí kò ní ìmọ́lẹ̀, kí ó gbẹ́kẹ̀lé orúkọ OLúWA kí o sì gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run rẹ̀. Ṣùgbọ́n ní àkókò yìí, gbogbo ẹ̀yin ti ń tanná tí ẹ sì ń fi pèsè iná ìléwọ́ fún ara yín, ẹ lọ, kí ẹ sì máa rìn nínú ìmọ́lẹ̀ iná yín, àti nínú ẹta iná tí ẹ ti dá. Èyí ni yóò jẹ́ tiyín láti ọwọ́ mi wá: Ẹ̀yin ó dùbúlẹ̀ nínú ìrora.