Isa 5:8-30
Isa 5:8-30 Bibeli Mimọ (YBCV)
Egbe ni fun awọn ti o ni ile kún ile, ti nfi oko kún oko, titi ãyè kò fi si mọ, ki nwọn bà le nikan wà li ãrin ilẹ aiye! Li eti mi ni Oluwa awọn ọmọ-ogun sọ pe, Nitõtọ ọ̀pọ ile ni yio di ahoro, ile nla ati daradara laisi olugbe. Nitõtọ ìwọn akeri mẹwa ọ̀gba àjara yio mu òṣuwọn bati kan wá, ati òṣuwọn irugbìn homeri kan yio mu òṣuwọn efa kan wá. Egbe ni fun awọn ti ima dide ni kùtukutu, ki nwọn le ma lepa ọti lile; ti nwọn wà ninu rẹ̀ titi di alẹ, titi ọti-waini mu ara wọn gbona! Ati durù, ati fioli, tabreti, ferè, ati ọti-waini wà ninu àse wọn: ṣugbọn nwọn kò kà iṣẹ Oluwa si, bẹ̃ni nwọn kò rò iṣẹ ọwọ́ rẹ̀. Nitorina awọn enia mi lọ si oko-ẹrú, nitoriti oye kò si, awọn ọlọla wọn di rirù, ati ọ̀pọlọpọ wọn gbẹ fun orùngbẹ. Nitorina ipò-òkú ti fun ara rẹ̀ li àye, o si là ẹnu rẹ̀ li aini ìwọn: ati ogo wọn, ati ọ̀pọlọpọ wọn, ati ọṣọ́ wọn, ati awọn ẹniti nyọ̀, yio sọkalẹ sinu rẹ̀. Enia lasan li a o rẹ̀ silẹ, ati ẹni-alagbara li a o rẹ̀ silẹ, oju agberaga li a o si rẹ̀ silẹ. Ṣugbọn Oluwa awọn ọmọ-ogun li a o gbe ga ni idajọ, ati Ọlọrun Ẹni-Mimọ́ yio jẹ mimọ́ ninu ododo. Nigbana li awọn ọdọ-agutan yio ma jẹ̀ gẹgẹ bi iṣe wọn, ati ibi ahoro awọn ti o sanra li awọn alejò yio ma jẹ. Egbe ni fun awọn ti nfi ohun asan fà ìwa buburu, ati awọn ti o dabi ẹnipe nfi okùn kẹkẹ́ fà ẹ̀ṣẹ. Awọn ti o wipe, Jẹ ki o yara, ki o si mu iṣẹ rẹ̀ yara, ki awa ki o le ri i: ati jẹ ki ìmọ Ẹni-Mimọ́ Israeli sunmọ ihin, ki o si wá, ki awa ki o le mọ̀ ọ. Egbe ni fun awọn ti npè ibi ni rere, ati rere ni ibi, ti nfi okùnkun ṣe imọlẹ, ati imọlẹ ṣe okùnkun: ti nfi ikorò pe adùn, ati adùn pe ikorò! Egbe ni fun awọn ti nwọn gbọ́n li oju ara wọn, ti nwọn si mọ̀ oye li oju ara wọn! Egbe ni fun awọn ti o ni ipá lati mu ọti-waini, ati awọn ọkunrin alagbara lati ṣe adàlu ọti lile: Awọn ẹniti o da are fun ẹni-buburu nitori ère, ti nwọn si mu ododo olododo kuro li ọwọ́ rẹ̀. Nitorina bi iná ti ijo akekù koriko run, ti ọwọ́ iná si ijo iyàngbo; bẹ̃ni egbò wọn yio da bi rirà; itanna wọn yio si gòke bi ekuru; nitori nwọn ti ṣá ofin Oluwa awọn ọmọ-ogun tì, nwọn si ti gàn ọ̀rọ Ẹni-Mimọ Israeli. Nitorina ni ibinu Oluwa fi ràn si enia rẹ̀, o si ti na ọwọ́ rẹ̀ si wọn, o si ti lù wọn: awọn òke si warìri, okú wọn si wà bi igbẹ li ãrin igboro. Ni gbogbo eyi ibinu rẹ̀ kò yi kuro, ṣugbọn ọwọ́ rẹ̀ nà jade sibẹ. Yio si gbe ọpágun soke si awọn orilẹ-ède ti o jìna, yio si kọ si wọn lati opin ilẹ wá, si kiyesi i, nwọn o yara wá kánkán. Kò si ẹniti yio rẹ̀, tabi ti yio kọsẹ ninu wọn, kò si ẹniti yio tõgbe tabi ti yio sùn: bẹ̃ni amùre ẹgbẹ wọn kì yio tu, bẹ̃ni okùn bàta wọn kì yio ja. Awọn ẹniti ọfà wọn mu, ti gbogbo ọrun wọn si kàn, a o ka patakò ẹsẹ ẹṣin wọn si okuta akọ, ati kẹkẹ́ wọn bi ãja. Kike wọn yio dabi ti kiniun, nwọn o ma ke bi awọn ọmọ kiniun, nitõtọ nwọn o ma ke, nwọn o si di ohun ọdẹ na mu, nwọn a si gbe e lọ li ailewu, kò si ẹnikan ti yio gbà a. Ati li ọjọ na nwọn o ho si wọn, bi hiho okun: bi ẹnikan ba si wo ilẹ na, kiyesi i, okùnkun ati ipọnju, imọlẹ si di okùnkun ninu awọsanma dudu rẹ̀.
Isa 5:8-30 Yoruba Bible (YCE)
Ègbé ni fún àwọn tí ó ń kọ́lé mọ́lé, tí wọn ń gba ilẹ̀ kún ilẹ̀, títí tí kò fi sí ilẹ̀ mọ́, kí ẹ̀yin nìkan baà lè máa gbé ilẹ̀ náà. OLUWA ọmọ ogun ti búra lójú mi, ó ní, “Láìsí àní-àní, ọpọlọpọ ilé ni yóo di ahoro, ọ̀pọ̀ ilé ńláńlá, ati ilé dáradára yóo sì wà láìsí olùgbé. Apẹ̀rẹ̀ èso àjàrà kan ni a óo rí ká ninu ọgbà àjàrà sarè mẹ́wàá. Kóńgò èso kan ni ẹni tí ó gbin kóńgò marun-un yóo rí ká.” Ègbé ni fún àwọn tí wọ́n jí ní òwúrọ̀ kutukutu, láti máa wá ọtí líle kiri, tí wọ́n ń mu ún títí di ìrọ̀lẹ́, títí tí ọtí yóo fi máa pa wọ́n! Dùùrù, hapu, ìlù, fèrè ati ọtí waini wà níbi àsè wọn; ṣugbọn wọn kì í bìkítà fún iṣẹ́ Ọlọrun, wọn kìí sìí náání iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀. Nítorí náà àwọn eniyan mi óo lọ sí oko ẹrú nítorí àìmòye wọn, ebi ni yóo pa àwọn ọlọ́lá wọn ní àpakú, òùngbẹ óo sì gbẹ ọpọlọpọ wọn. Isà òkú ti ṣetán, yóo gbé wọn mì, ó ti yanu kalẹ̀. Àwọn ọlọ́lá Jerusalẹmu yóo já sinu rẹ́, ati ọ̀pọ̀ ninu àwọn ará ìlú, ati àwọn tí ń fi ìlú Jerusalẹmu yangàn. A tẹ eniyan lórí ba, a sì rẹ̀ wọ́n sílẹ̀ ojú àwọn onigbeeraga yóo sì wálẹ̀. Ṣugbọn OLUWA àwọn ọmọ ogun ni a óo gbéga ninu ẹ̀tọ́ nítorí ìdájọ́ òdodo Ọlọrun Mímọ́ yóo fi ara rẹ̀ hàn, pé mímọ́ ni òun ninu òdodo. Nígbà náà ni àwọn ọ̀dọ́ aguntan yóo máa jẹ oko ninu pápá oko wọn àwọn àgbò ati ewúrẹ́ yóo sì máa jẹko ninu ahoro wọn. Àwọn tí ń ṣe àfọwọ́fà ẹ̀ṣẹ̀ gbé! Àwọn tí wọn ń fi ìwà aiṣododo fa ẹ̀ṣẹ̀ bí ẹni tí ń fi okùn fa ẹṣin. Tí wọn ń wí pé: “Kí ó tilẹ̀ ṣe kíá, kí ó ṣe ohun tí yóo ṣe, kí á rí i. Jẹ́ kí àbá Ẹni Mímọ́ Israẹli di òtítọ́ kí ó ṣẹlẹ̀, kí á lè mọ̀ ọ́n!” Àwọn tí ń pe ibi ní ire gbé; tí wọn ń pe ire ní ibi! Àwọn tí wọn ń fi òkùnkùn ṣe ìmọ́lẹ̀, tí wọn sì fi ìmọ́lẹ̀ ṣe òkùnkùn! Tí wọ́n fi ìkorò ṣe adùn, tí wọ́n sì fi adùn ṣe ìkorò. Àwọn tí ó gbọ́n lójú ara wọn gbé; tí wọ́n ka ara wọn kún ẹni tí ó ní ìmọ̀! Àwọn tí wọ́n jẹ́ ọ̀gá ninu ọtí mímu gbé; tí wọ́n jẹ́ akikanju bí ó bá di pé kí á da ọtí líle pọ̀ mọ́ ara wọn! Àwọn tí wọn ń dá ẹni tí ó jẹ̀bi sílẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ti gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ tán; tí wọn kì í jẹ́ kí aláìṣẹ̀ rí ẹ̀tọ́ gbà. Nítorí náà, bí iná tíí jó àgékù igi kanlẹ̀, tíí sìí jó ewéko ní àjórun; bẹ́ẹ̀ ní gbòǹgbò wọn yóo ṣe rà, tí ìtànná wọn yóo sì fẹ́ lọ bí eruku. Nítorí wọ́n kọ òfin OLUWA àwọn ọmọ ogun sílẹ̀, wọ́n sì kẹ́gàn ọ̀rọ̀ Ẹni Mímọ́ Israẹli. Nítorí náà ni inú ṣe bí OLUWA sí àwọn eniyan rẹ̀, ó sì na ọwọ́ rẹ̀, ó sì pa wọ́n, àwọn òkè sì mì tìtì. Òkú wọn dàbí pàǹtí láàrin ìgboro, sibẹsibẹ inú OLUWA kò rọ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sì dá ọwọ́ ìjà dúró. Ó ta àsíá, ó fi pe orílẹ̀-èdè kan tí ó wà ní òkèèrè; ó sì fọn fèrè sí i láti òpin ayé. Wò ó! Àwọn eniyan orílẹ̀-èdè náà ń bọ̀ kíákíá. Kò rẹ ẹnikẹ́ni ninu wọn, ẹnikẹ́ni ninu wọn kò fẹsẹ̀ kọ. Ẹyọ ẹnìkan wọn kò sì sùn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò tòògbé. Àmùrè ẹnìkankan kò tú, bẹ́ẹ̀ ni okùn bàtà ẹnìkankan kò já. Ọfà wọn mú wọ́n kẹ́ ọrun wọn. Pátákò ẹsẹ̀ ẹṣin wọn le bí òkúta akọ; ẹsẹ̀ kẹ̀kẹ́ ogun wọn dàbí ìjì líle. Bíbú wọn dàbí ti kinniun, wọn a bú ramúramù bí ọmọ kinniun, wọn a kígbe, wọn a sì ki ohun ọdẹ wọn mọ́lẹ̀, wọn a gbé e lọ, láìsí ẹni tí ó lè gbà á lọ́wọ́ wọn. Wọn óo hó lé Israẹli lórí lọ́jọ́ náà bí ìgbà tí omi òkun ń hó. Bí eniyan bá wọ ilẹ̀ náà yóo rí òkùnkùn ati ìnira. Ìkùukùu rẹ̀ yóo sì bo ìmọ́lẹ̀.
Isa 5:8-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ègbé ni fún àwọn tí ń kọ́lé mọ́lé tí ó sì ń ra ilẹ̀ mọ́lẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ààyè kò ṣẹ́kù tí ó sì nìkan gbé lórí ilẹ̀. OLúWA àwọn ọmọ-ogun ti sọ ọ́ sí mi létí: “Ó dájú pé àwọn ilé ńláńlá yóò di ahoro, àwọn ilé dáradára yóò wà láìní olùgbé. Ọgbà àjàrà sáré oko mẹ́wàá yóò mú ìkòkò wáìnì kan wá, nígbà tí òṣùwọ̀n homeri kan yóò mú agbọ̀n irúgbìn kan wá.” Ègbé ni fún àwọn tí wọ́n dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ láti lépa ọtí líle, tí wọ́n sì mu ún títí alẹ́ fi lẹ́ títí wọ́n fi gbinájẹ pẹ̀lú wáìnì. Wọ́n ní dùùrù àti ohun èlò orin olókùn níbi àsè wọn, ṣaworo òun fèrè àti wáìnì, ṣùgbọ́n wọn kò ka iṣẹ́ OLúWA sí, wọn kò sí bọ̀wọ̀ fún iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀. Nítorí náà àwọn ènìyàn mi yóò lọ sí ìgbèkùn nítorí òye kò sí fún wọn, ebi ni yóò pa àwọn ọlọ́lá wọn kú; ẹgbàágbèje wọn ni òǹgbẹ yóò sì gbẹ. Nítorí náà isà òkú ti ń dátọ́mì gidigidi, ó sì ti ya ẹnu rẹ̀ sílẹ̀ gbagada, nínú rẹ̀ ni àwọn gbajúmọ̀ àti mẹ̀kúnnù yóò sọ̀kalẹ̀ sí pẹ̀lú ọlá àti ògo wọn. Báyìí, ènìyàn yóò di ìrẹ̀sílẹ̀ àti ọmọ ènìyàn ni a sọ di onírẹ̀lẹ̀ ojú agbéraga ni a sì rẹ̀ sílẹ̀. Ṣùgbọ́n OLúWA àwọn ọmọ-ogun ni a ó gbéga nípa ẹ̀tọ́ rẹ̀, Ọlọ́run ẹni mímọ́ yóò sì fi ara rẹ̀ hàn ní mímọ́ nípa òdodo rẹ̀. Nígbà náà ni àwọn àgùntàn yóò máa jẹ́ ko ní ibùgbé e wọn, àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn yóò máa jẹ nínú ahoro àwọn ọlọ́rọ̀. Ègbé ni fún àwọn tí ń fi ohun asán fa ẹ̀ṣẹ̀, àti àwọn tí o dàbí ẹni pé wọ́n ń fi okùn kẹ̀kẹ́ ẹ̀sìn fa ẹsẹ̀, sí àwọn tí ó sọ pé, “Jẹ́ kí Ọlọ́run ṣe kíákíá, jẹ́ kí ó yára ṣiṣẹ́ rẹ̀ kí a lè rí i, jẹ́ kí ó súnmọ́ bí jẹ́ kí ètò ẹni mímọ́ Israẹli kí ó dé, kí àwa kí ó le mọ̀ ọ́n.” Ègbé ni fún àwọn tí ń pe ibi ní rere, àti rere ní ibi, tí ń fi òkùnkùn ṣe ìmọ́lẹ̀ àti ìmọ́lẹ̀ ṣe òkùnkùn, tí ń fi ìkorò ṣe adùn àti adùn ṣe ìkorò. Ègbé ni fún àwọn tí ó gbọ́n lójú ara wọn tí wọ́n jáfáfá lójú ara wọn. Ègbé ni fún àwọn akọni nínú wáìnì mímu àti àwọn akíkanjú nínú àdàlú ọtí, tí wọ́n dá ẹlẹ́bi sílẹ̀ nítorí àbẹ̀tẹ́lẹ̀, tí wọn sì du aláre ní ẹ̀tọ́. Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí ahọ́n iná ṣe ń jó àgékù koríko run àti bí koríko ṣe rẹlẹ̀ wẹ̀sì nínú iná, bẹ́ẹ̀ ni egbò wọn yóò jẹrà tí òdodo wọn yóò sì fẹ́ lọ bí eruku: nítorí pé wọ́n ti kọ òfin OLúWA àwọn ọmọ-ogun sílẹ̀ wọ́n sì gan ọ̀rọ̀ Ẹni mímọ́ Israẹli. Nítorí náà, ìbínú OLúWA gbóná si àwọn ènìyàn rẹ̀, ó ti gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè, ó sì lù wọ́n bolẹ̀. Àwọn òkè sì wárìrì, òkú wọn sì dàbí ààtàn ní àárín ìgboro. Pẹ̀lú gbogbo èyí, ìbínú rẹ̀ kò yí kúrò, ṣùgbọ́n ọ̀wọ́ rẹ̀ sì ná jáde síbẹ̀. Yóò sì gbé ọ̀págun sókè sí àwọn orílẹ̀-èdè tí ó jìnnà, yóò sì kọ sí wọn tí ó wà ní ìpẹ̀kun ilẹ̀. Sì kíyèsi, wọ́n yóò yára wá kánkán. Kò sí ẹni tí yóò rẹ̀ nínú wọn, tàbí tí yóò kọsẹ̀, kò sí ẹni tí yóò tòògbé tàbí tí yóò sùn; bẹ́ẹ̀ ni àmùrè ẹ̀gbẹ́ wọn kì yóò tú, bẹ́ẹ̀ ni okùn sálúbàtà wọn kì yóò ja. Àwọn ọfà wọn múná, gbogbo ọrun wọn sì le; pátákò àwọn ẹṣin wọn le bí òkúta akọ, àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ wọn sì dàbí ìjì líle. Bíbú wọn dàbí tí kìnnìún, wọ́n bú bí ẹgbọrọ kìnnìún, wọ́n ń kọ bí wọ́n ti di ẹran ọdẹ wọn mú tí wọn sì gbé e lọ láìsí ẹni tí yóò gbà á là. Ní ọjọ́ náà, wọn yóò hó lé e lórí gẹ́gẹ́ bí i rírú omi Òkun. Bí ènìyàn bá sì wo ilẹ̀, yóò rí òkùnkùn àti ìbànújẹ́; pẹ̀lúpẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ yóò di òkùnkùn pẹ̀lú kurukuru rẹ̀.