Isa 49:8-12
Isa 49:8-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bayi ni Oluwa wi, Li akoko itẹwọgba emi ti gbọ́ tirẹ, ati li ọjọ igbala, mo si ti ràn ọ lọwọ: emi o si pa ọ mọ, emi o si fi ọ ṣe majẹmu awọn enia, lati fi idi aiye mulẹ, lati mu ni jogun ahoro ilẹ nini wọnni. Ki iwọ ki o le wi fun awọn igbekùn pe, Ẹ jade lọ; fun awọn ti o wà ni okùnkun pe, Ẹ fi ara nyin hàn. Nwọn o jẹ̀ li ọ̀na wọnni, pápa ijẹ wọn o si wà ni gbogbo ibi giga. Ebi kì yio pa wọn, bẹ̃ni ongbẹ kì yio si gbẹ wọn; õru kì yio mu wọn, bẹ̃ni õrùn kì yio si pa wọn: nitori ẹniti o ti ṣãnu fun wọn yio tọ́ wọn, ani nihà isun omi ni yio dà wọn. Emi o si sọ gbogbo awọn òke-nla mi wọnni di ọ̀na, a o si gbe ọ̀na opopo mi wọnni ga. Kiye si i, awọn wọnyi yio wá lati ọ̀na jijìn: si wò o, awọn wọnyi lati ariwa wá; ati lati iwọ-õrun wá, ati awọn wọnyi lati ilẹ Sinimu wá.
Isa 49:8-12 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA ní, “Ní àkókò ìtẹ́wọ́gbà mo dá ọ lóhùn, lọ́jọ́ ìgbàlà, mo ràn ọ́ lọ́wọ́. Mo ti pa ọ́ mọ́, mo sì ti fi ọ́ dá majẹmu pẹlu àwọn aráyé, láti fìdí ilẹ̀ náà múlẹ̀, láti pín ilẹ̀ tí ó ti di ahoro. Kí o máa sọ fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n pé, ‘Ẹ jáde,’ ati fún àwọn tí ó wà ninu òkùnkùn pé, ‘Ẹ farahàn.’ Wọn óo rí ohun jíjẹ ní gbogbo ọ̀nà, gbogbo orí òkè yóo sì jẹ́ ibùjẹ fún wọn. Ebi kò ní pa wọ́n, òùngbẹ kò sì ní gbẹ wọ́n, atẹ́gùn gbígbóná kò ní fẹ́ lù wọ́n, bẹ́ẹ̀ ni oòrùn kò ní pa wọ́n, nítorí ẹni tí ó ṣàánú wọn ni yóo máa darí wọn, yóo sì mú wọn gba ẹ̀gbẹ́ omi tí ń ṣàn. “N óo sọ gbogbo òkè mi di ojú ọ̀nà, n óo kún gbogbo òpópó ọ̀nà mi. Wò ó! Òkèèrè ni èyí yóo ti wá, láti àríwá ati láti ìwọ̀ oòrùn, àní láti ilẹ̀ Sinimu.”
Isa 49:8-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ohun tí OLúWA wí nìyìí: “Ní àkókò ojúrere mi, èmi yóò dá ọ lóhùn, àti ní ọjọ́ ìgbàlà, èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́; Èmi yóò pa ọ́ mọ́, n ó sì ṣe ọ́ láti jẹ́ májẹ̀mú fún àwọn ènìyàn, láti mú ilẹ̀ padà bọ̀ sípò àti láti ṣe àtúnpín ogún rẹ̀ tí ó ti dahoro, Láti sọ fún àwọn ìgbèkùn pé, ‘Ẹ jáde wá’ àti fún àwọn tí ó wà nínú òkùnkùn pé, ‘Ẹ gba òmìnira!’ “Wọn yóò máa jẹ ní ẹ̀bá ọ̀nà àti koríko tútù lórí òkè aláìléwéko. Ebi kì yóò pa wọ́n bẹ́ẹ̀ ni òǹgbẹ kì yóò gbẹ wọ́n, tàbí kí ooru inú aṣálẹ̀ tàbí oòrùn kí ó pa wọ́n. Ẹni tí ó ṣàánú fún wọn ni yóò máa tọ́ wọn, tí yóò sì mú wọn lọ sí ibi orísun omi. Èmi yóò sọ gbogbo àwọn òkè-ńlá mi di ojú ọ̀nà àti gbogbo òpópónà mi ni a ó gbé sókè. Kíyèsi i, wọn yóò wá láti ọ̀nà jíjìn àwọn díẹ̀ láti àríwá àti àwọn díẹ̀ láti ìwọ̀-oòrùn, àwọn díẹ̀ láti ẹkùn Siene.”