Isa 49:15-17
Isa 49:15-17 Bibeli Mimọ (YBCV)
Obinrin ha lè gbagbe ọmọ ọmú rẹ̀ bi, ti kì yio fi ṣe iyọ́nu si ọmọ inu rẹ̀? lõtọ, nwọn le gbagbe, ṣugbọn emi kì yio gbagbe rẹ. Kiye si i, emi ti kọ ọ si atẹlẹwọ mi: awọn odi rẹ mbẹ niwaju mi nigbagbogbo. Awọn ọmọ rẹ yára; awọn oluparun rẹ ati awọn ti o fi ọ ṣofò yio ti ọdọ rẹ jade.

Isa 49:15-17 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA dáhùn pé, “Ǹjẹ́ abiyamọ le gbàgbé ọmọ tí ń fún lọ́mú? Ṣé ó le má ṣàánú ọmọ bíbí inú rẹ̀? Bí àwọn wọnyi tilẹ̀ gbàgbé. Èmi kò ní gbàgbé rẹ. Wò ó! Mo ti fi gègé fín orúkọ rẹ sí àtẹ́lẹwọ́ mi, àwọn odi rẹ sì ńbẹ níwájú mi nígbà gbogbo. “Àwọn ọmọ rẹ tí ń pada bọ̀ kíákíá, àwọn olùparun rẹ yóo jáde kúrò ninu rẹ.
Isa 49:15-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ǹjẹ́ abiyamọ ha le gbàgbé ọmọ ọmú rẹ̀ kí ó má sì ṣàánú fún ọmọ rẹ̀ tí ó ti bí? Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun le gbàgbé Èmi kì yóò gbàgbé rẹ! Kíyèsi i, mo ti kọ ọ́ sí àtẹ́lẹwọ́ mi ògiri rẹ wà níwájú mi nígbà gbogbo. Àwọn ọmọ rẹ ti kánjú padà, àti àwọn tí ó sọ ọ́ dahoro ti padà lẹ́yìn rẹ.