Isa 49:1-4
Isa 49:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ gbọ ti emi, ẹnyin erekùṣu; ki ẹ si fi etí silẹ, ẹnyin enia lati ọ̀na jijìn wá; Oluwa ti pè mi lati inu wá; lati inu iya mi li o ti dá orukọ mi. O si ti ṣe ẹnu mi bi idà mimú; ninu ojìji ọwọ́ rẹ̀ li o ti pa mi mọ, o si sọ mi di ọfà didán; ninu apó rẹ̀ li o ti pa mi mọ́; O si wi fun mi pe, Iwọ ni iranṣẹ mi, Israeli, ninu ẹniti a o yìn mi logo. Nigbana ni mo wi pe, Emi ti ṣiṣẹ́ lasan, emi ti lò agbara mi lofo, ati lasan: nitõtọ idajọ mi mbẹ lọdọ Oluwa, ati iṣẹ mi lọdọ Ọlọrun mi.
Isa 49:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ilẹ̀ etí òkun. Ẹ fetí sílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ mi, ẹ̀yin ará ilẹ̀ òkèèrè, láti inú oyún ni OLUWA ti pè mí, láti inú ìyá mi wá ni ó ti dárúkọ mi. Ó ṣe ẹnu mi bí idà mímú, ó fi mí pamọ́ sí ibi òjìji ọwọ́ rẹ̀, ó ṣe mí ní ọfà tí ó mú, ó fi mí pamọ́ sinu apó rẹ̀. Ó sọ fún mi pé, “Iranṣẹ mi ni ọ́, ìwọ Israẹli, àwọn eniyan óo máa yìn mí lógo nítorí rẹ.” Ṣugbọn mo dáhùn pé, “Mo ti ṣiṣẹ́ àṣedànù. Mo ti lo agbára mi ṣòfò, mo ti fi ṣe àṣedànù, sibẹsibẹ ẹ̀tọ́ mi ń bẹ lọ́dọ̀ OLUWA.” Ẹ̀san mi ń bẹ lọ́dọ̀ Ọlọrun mi, yóo san án fún mi.
Isa 49:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin erékùṣù: gbọ́ èyí, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè jíjìnnà réré: kí a tó bí mi OLúWA ti pè mí; láti ìgbà bíbí mi ni ó ti dá orúkọ mi. Ó ṣe ẹnu mi bí idà tí a pọ́n, ní abẹ́ òjìji ọwọ́ rẹ̀ ni ó ti pa mí mọ́: ó ṣe mí ní ọfà tí a ti dán, ó sì fi mí pamọ́ sínú àpò rẹ̀. Ó sọ fún mi pé, “ìránṣẹ́ mi ni ìwọ í ṣe, Israẹli nínú ẹni tí n ó ti fi ògo mi hàn.” Ṣùgbọ́n èmi sọ pé, “Mo ti ṣe wàhálà lórí asán; mo ti lo gbogbo ipá mi lórí asán àti ìmúlẹ̀mófo. Síbẹ̀síbẹ̀ ohun tí ó tọ́ sí mi ṣì wà lọ́wọ́ OLúWA, èrè mi sì ń bẹ pẹ̀lú Ọlọ́run mi.”